Sunday Igboho Arrest: Ìgbà márùn-ún rèé tí ajìjàgbara bọ́ lọ́wọ́ ìkọlù láti mu

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram

Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Igboho lo jẹ asiwaju ajijagbara fun iran Yoruba, to si tun n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba Nation.

Nitori bo se n pe fun iyapa Naijiria yii, ni ijọba se n gbiyanju lati mu si ahamọ, ko si finmu kata ofin nitori ẹsẹ nla ni igbinyanju lati mu iyapa ba orilẹede yii.

Lati igba naa ni Sunday Igboho ti n pariwo pe oniruuru ikọlu lo n waye si ile oun ati lasiko to ba n rin laarin ilu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ni alẹ ọjọ Aje, ọjọ Kọkandinlogun osu Keje ọdun 2021, ni iroyin gbalẹ kan pe ọwọ ijọba ti tẹ Sunday Igboho ni ilu Cotonou, lorilẹede Benin.

K ọwọ sinku ijọba to tẹ ajijagbara naa, akoko marun ree ti ariwo ti gbalẹ kan pe ikọlu waye si Igboho pẹlu ete lati mu si ahamọ ijọba.

Ibudo Guru Maharaji loju ọna marosẹ Ibadan silu Eko:

Igba akọkọ ti ikọlu yoo waye si Sunday Igboho ni akoko to n lọ silu Eko, lati lọ sile Iba Gani Adams.

Opopona Marosẹ Ibadan silu Eko, niwaju ile Guru Maharaji ni awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti da ikọ rẹ duro.

Iroyin to gbalẹ kan nigba naa ni pe awọn DSS naa fẹ gbe Sunday Igboho ni amọ ti awọn onitọun ni ko ri bẹẹ.

Awọn afurasi Sọja

Oríṣun àwòrán, Facebook/Koiki Media

Afurasi Sọja meji wa tọpinpin ile rẹ:

Bakan naa ni iroyin gbode pe awọn afurasi Sọja meji wa tọpinpin ile Sunday Igboho amọ ti awọn ọmọ ẹyin rẹ mu wọn mọlẹ.

Awọn afurasi Sọja naa lo wọ asọ ologun ti wọn si n gun ọkada kọja ni ogunjọ osu kẹta ọdun 2021 ti isẹlẹ naa waye.

Amọ awọn afurasi naa ni awọn n lọ jẹjẹ tawọn ni wọn da awọn duro, ti awọn ko si wa se ohunkohun ninu ile naa.

Lẹyin o rẹyin ni wọn fa awọn afurasi naa le ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lọwọ, ti ileesẹ ologun si fi ikede sita pe awn ko ni pẹlẹngọ lati mu Igboho tawọn ba setan lati se bẹẹ.

Ile Sunday Igboho to jona

Awọn Janduku sọ ina sile Sunday Igboho:

Awọn janduku kan la gbọ pe wọn ya bo ile akọkọ ti Sunday Igboho kọ si agbegbe Soka nilu Ibadan, amọ kii se ile yii lo n gbe.

Aimọye dukia lo jona ninu ile naa, ti wọn si tun ni awọn agbebọn ọhun gbe kẹẹgi epo pẹtiroolu wa lati sun ile naa ni.

A gbọ pe ọpẹlọpẹ awọn ọmọ ẹyin Igboho to jade ti wọn, tawọn janduku ọhun to gbe ọkọ bọọsi ati ayọkẹlẹ wa, si sa lọ.

Awọn agbofinro mu lẹta wa sile Sunday Igboho:

Igba kẹrin ti ariwo yoo sọ pe wọn se ikọlu sile Sunday Igboho ni akoko ti wọn ni awọn osisẹ agbofinro ko ọkọ bọọsi wa lati fun Igboho ni lẹta kan.

Wọn ni ọga agba ọlọpaa nilẹ yii lo fi lẹta naa ransẹ si amọ tawọn ọmọlẹyin Igboho yari lati gba iwe naa.

DSS kọlu ile Sunday Igboho ni aago kan abọ̀ loru:

Ile Sunday Igboho

Nigba to di idaji oru Ọjọbọ, ọ̀jọ̀ Kinni osu Keje ọ̀dun 2021, ni awọn gende agbebọn, ti wọn jẹ osisẹ DSS ya bo ile ajijagbara naa.

Ni ọjọ naa, wọn pa eeyan meji gẹgẹ bi wọn ti kede rẹ, ti wọn si ba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ ninu ile naa amọ wọ ko ri Igboho mu rara.

Bakan naa ni wọn ko eeyan mejila ninu ile naa si ahamọ wọ, ti wọn si tun ko awọn dukia miran lọ si ọọfisi wọn pẹlu.

Lara awọn dukia ọdun ni awọn asọ oogun ibilẹ ti Igboho fi n se isọra, awọn iwe asẹ iwọlu rẹ nilẹ okeere, owo Naira, Euro, Dọla ati pọun, to fi mọ awọn ẹsọ ara ni orisirisi.

Lati akoko naa si ni ijọba ti kede pe awọn n wa Sunday Igboho, ki ọwọ wọn to wa tẹ ni Cotonou, lorilẹede Benin.