Sunday Igboho Arrest: Reno Omokri ní Buhari ń ràgà bo àwọn ẹ̀yà rẹ̀, tó sì ń lépa àwọn akọni tó ń gbèjà ẹ̀yà tiwọn

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram
Amugbalẹgbẹ tẹlẹ fun aarẹ ana, Reno Omokri ti bu ẹnu atẹ lu bi ijọba se mu ajafẹtọ ọmọniyan nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Igboho ni Cotonou, lorilẹede Benin.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ naa loju opo Facebook rẹ, Omokri ni awọn ọmọ Naijiria yoo korajọpọ lati da ohun alumọni wọn jọ lati gbe ajafẹtọ ilu naa lẹyin.
Omokri ni "bi wọn se mu Sunday Igboho ni Cotonou ko dara rara, akọni to n ja lati daabo bo awọn eeyan rẹ ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Naijiria ti fi pampẹ̀ òfin mú Sunday Igboho?
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
- Àwọn agbébọn ti pa ọlọ́pàá mẹ́tàlá ní Zamfara- Gomina Zamfara
- Ilé ẹjọ Májísírèètì Yaba nípinlẹ Eko ti gba béèlì àwọn olùwọde Yoruba Nations 49 tí wọn wa ní àhámọ
- Ohun márùn ún tó mú ìgbé ayé le fọ́mọ Nàìjíríà lójoojúmọ́
A gbọdọ san gbogbo isẹ rere ti Igboho se pada fun nipa kiko awọn ohun alumọni wa papọ lati gbeja rẹ nile ẹjọ.
Buhari ti kọ lati ri awọn ẹbi rẹ to n ja baalu olowo iyebiye to jẹ ti Naijiria lulẹ, bii adunkooko mọni.

Oríṣun àwòrán, Reno Omokri Facebook
Wọn kọkọ pa irọ pe baalu kankan ko ja, amọ nigba ti ori ko awakọ baalu naa yọ, to si ja irọ wọn, ni wọn ba bọ sita lati kede pe lootọ ni baalu ja.
Amọ se ni Buhari n lepa ẹtahoro awọn ọmọ Naijiria to jẹ akọni ti wọn dide lati pin awọn apani darandaran lọwọ isẹ ibi wọn.
Idi ree ti mo se n duro ti Igboho, kii se pe tori o fẹ pin Naijiria amọ tori pe o dide lati gbeja awọn eeyan rẹ."



















