Nigeria Insecurity: Ohun márùn ún tó ń da ètò àbò láàmú ní Nàìjíríà

Awọn oluwọde

Oríṣun àwòrán, AFP

Idojukọ nla ni ọrọ ipenija abo to mẹhẹ jẹ fun orilẹede Naijiria.

Ko fẹrẹ si ojumọ kan ti iṣẹlẹ ikọlu, rogbodiyan tabi igbenipa kan kii waye lorilẹede Naijiria bayii.

Ọgbẹni Audu Bulama Bukarti to jẹ agba onimọ nipa eto abo lagbegbe olooru Sahara ni Afirika nibudo iwadii ijinlẹ Tony Blair Institute ṣalaye pe, ọwọja abo to mẹhẹ yii n ṣe akoba lọpọlọpọ fun orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Pẹlu ọkọọkan awọn ikọlu wọnyii, ẹmi n ṣofo, awọn eeyan n di alaabọ ara, bẹẹ ni igbagbọ ninu eto iṣejọba tiwantiwa ati ninu orilẹede Naijiria n kuru sii lojojumọ."

Nigba ti Aarẹ Muhammadu Buhari gun aga iṣejọba lọdun 2015, ara ileri to ṣe ni didaabo bo araalu lọwọ awọn agbesunmọmi ati ọdaran gbogbo.

Àkọlé fídíò, Igangan Attacks: Àkójọpọ̀ àbọ̀ BBC Yorùbá rèé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ òfò ẹ̀mí àti dúkìá tó wáyé

Amọṣa o din diẹ ni ọdun meji bayii to ku ki o fi ijọba silẹ lẹyin ọdun mẹfa lai ri ọna abayọ si isoro eto aabo.

Awọn eeyan kan ti woye pe gulegule wahala abo lẹnu lọwọlọwọ yii, lo nii ṣe pẹlu bi iṣẹ ati oṣi ṣe gbilẹ kaakiri orilẹede Naijiria.

Ni bayii, ida mejilelọgbọn abọ awọn ọdọ to wa lorilẹede Naijiria ni ko ni iṣẹ lọwọ.

Eyi ni ipenija marun to n dojukọ abo lorilẹede Naijiria, to si n mu li igbe aye le koko fawọn ọmọ Naijiria lati gbe.

Ija ẹsin Jihad

Aworan Awọn ipinlẹ ti awọn agbebọn alakatakiti ẹsin ti n ṣọṣẹ
Àkọlé àwòrán, Awọn ipinlẹ ti awọn agbebọn alakatakiti ẹsin ti n ṣọṣẹ

Bi o tilẹ jẹ pe lọdun akọkọ ni Aarẹ Buhari ti kede pe oun ti ṣẹgun awọn agbebọn Boko Haram, amọṣa lọwọ yii O ti yi ohun pada pe ijọba oun n ba ijakulẹ pade lori ati dẹkun igbesunmọmi eyi to bẹrẹ lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Ẹgbẹ agbebọn Boko Haram ti n gbooro sii lọ sawọn agbegbe tuntun nipa lilo anfani iṣẹ ati aini to gbode lorilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye, UN ṣe sọ, titi di opin ọdun 2020, nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọdunrun o le aadọta, 350,000 eeyan lawọn agbebọn Boko Haram ti ran lọ sọrun apapandodo ti wọn si ti sọ ẹgbẹlẹgbẹ milisnu miran di atipo.

Oku awọn alagbaro oko tawọn agbebọn Boko Haram du lọdun to kọja

Oríṣun àwòrán, AFP

Ikọlu gbẹmigbẹmi lawọn agbebọn Boko Haram to si n sọ ara rẹ di balogun lawọn agbegbe kan. Bi o ti ṣe n gbowo ori lo n gbowo ilẹ lawọn agbegbe miran. Koda bi a ṣe n kọ iroyin yii, ikọ Boko Haram lo n ṣakoso gbajumọ ọja ẹja agbaye to wa letido Chad bayii.

Laipẹ yii, ikọ kan ti yapa to si fara mọ ikọ agbesumọmi miran Islamic State IS torukọ rẹ n jẹ Islamic State's West Africa Province, ISWAP ti wọn si ti lagbara ju Boko Haram lọ.

Wahala laarin awọn darandaran Fulani ati agbẹ olohun ọgbin.

Oniruuru rogbodiyan lo n waye laarin awọn darandaran fulani atawọn agbẹ lorilẹede Naijiria fun ọpọlọpọ ọdun.

Wahala ati ariyanjiyan lori ilẹ ati omi pẹlu papa ijẹko ti di wahalala nla pẹlu ayipada oju ọjs to n waye bayii eyi to n mu ki awọn darandaran o maa rin wa si apa gusu orilẹede Naijiria pẹlu awọn ẹran wọn.

Ọpọ ẹmi lo ti sọnu sinu ikọlu laarin awọn darandaran fulani ati agbẹ lori iwọnba perete aye ijẹko to wa.

Aworan awọn ipinlẹ ti awọn darandaran ati agbẹ ti n fa wahala
Àkọlé àwòrán, Awọn ipinlẹ ti awọn darandaran ati agbẹ ti n fa wahala

Ipinlẹ Benue ni rogbodiyan laarin darandaran ati awọn agbẹ ti buru julọ.

Laipẹ yii, eeyan meje lo ku nigba tawọn agbebọn kan ṣina ibọn bolẹ nibudo kan tawọn eeyan togun le kuro nile wọn wọ si.

Bakan naa lawọn miran ti fi ẹsun ijinigbepawo kan awọn darandaran Fulani pẹlu.

Ibudo awọn atipo kan

Oríṣun àwòrán, AFP

Wahala ọhun gan ti sun awọn gomina ipinlẹ lati gbẹsẹ le dida malu jẹko ni ita gbangba, eyi si ti fa edeaiyede pẹlu ijọba apapọ.

Ni ọdun 2019, ijọba apapọ gbe eto atunṣe ilana tuntun fun sinsin ẹran ọsin, ti wọn pe ni 10-year National Livestock Transformation Plan kalẹ lati dẹkun rinrinsokesodo awọn ẹran ọsin ati wahala ti wọn n ko sodi. Awọn onwoye ni aini afọkansin, awọn eeyan to tọ ati owo to yẹ lo n di eto naa lọwọ bayii.

Awọn agbebọn ati ijinigbe

Lara awọn ohun to n dẹru ba ọpọlọpọ awọn idile lorilẹede Naijiria bayii ni gulegule ijinigbe, paapaa jiji awọn akẹkọọ gbe nileewe wọn.

O le ni ẹgbẹrun akẹkọs ti awọn agbebọn ti ls ji gbe nileewe wọn laarin oṣu kejila ọdun 2020 si asiko yii. Pupọ ninu wọn lo jẹ pe lẹyin igba ti awọn obi wọn san ẹgbẹlẹgbẹ owo itusilẹ ni wọn to gba ominira.

Awọn agbebọn naa a maa kọlu awọn ileto kekeke lati ji awọn eeyan gbe ti wọn a si tun dana sun ile wọn.

Aworan bi awọn wahala darandaran ati agbẹ ṣe gbilẹ si lati ipinlẹ si ipinlẹ ni Naijiria

Ọpọlọpọ lo ti sare kuro ni ile wọn nitori wahala awọn agbebọn ajinigbe wọnyi.

Agbegbe iwọ oorun ariwa orilẹ€de Naijiria ni ọṣẹ wọn pọ si julọ. Ni ipinlẹ Zamfara nikan, ẹgbẹrun mẹta eeyan ni wọn ti gbẹmi wọn lati ọdun 2012, ko si tii dẹkun.

Awọn ajijagbara ẹlẹyamẹya

Ẹgbẹ ajijagbara kan wa ti wọn n pe ni Indeginous People of Biafra (IPOB) ti n gbena woju awọn agbofinro lorilẹede Naijiria fun ọpọlọpọ igba. IpoB n fẹ ki ẹya Igbo kuro lara orilẹede Naijiria ki wọn si da duro gẹgẹ bi orilẹede tiwọn.

Aworan awọn ọmọ ajijagbara IPoB

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọdun 2014 ni Nnamdi Kanu da ẹgbẹ naa silẹ. Laipẹ yii ni wọn fi panpẹ ofin mu Kanu lati wa jẹjọ ẹsun igbesunmọmi ati iditẹ ms ijọba. Ijakulẹ nla si ni bi o ṣe bọ sọwọ awọn agbofinro ijọba jẹ fun ẹgbẹ IpoB.

Ohun ti IpoB n ja fun kii ṣe tuntun. Ni ọdun1967 ni awọn adari ijọba ẹkun ila oorun Naijiria nigba naa kede ominira kuro lara orilẹede Naijiria, eyi si ṣokunfa ogun abẹle to mu iku ẹgbẹlẹgbẹ eeyan waye nigba naa.

Aarẹ Buhari ti ṣeleri ati tẹ ẹgbẹ IpoB ri mọlẹ. Loṣu to kọja lo kede loju opo Twitter rẹ "gbogbo awọn to n ṣi iwa hu loni" ni a o ba wi "ni ede ti wọn gbọ"

Awọn alaṣẹ Twitter yọ atẹjade naa danu loju opo wọn, lori ẹsun pe o tapa si ofin rẹ lẹyin tawọn eeyan kan lori ayelujara pariwo tako aarẹ Buhari lori rẹ. Iṣẹlẹ yii lo ṣokunfa bi ijọba Naijiria ṣe gbe ẹsẹ le oju opo Twitter lorilẹede Naijiria.

Awọn agbebọn Niger Delta

Awọm ọdọ agbebọn Niger-Delta to di ihamọra ogun ninu ọkọ oju omi

Oríṣun àwòrán, AFP

Agbegbe aringbungbun gusi orilẹede Naijiria ni epo rọbi sodo si julọ, ipenija abo nibẹ kii sii ṣe tuntun.

Epo rọbi ni orisun iṣuna fun ijọba orilẹede Naijiria bẹl si lawọn agbegbọn ẹkun naa n kigbe pe fun pipin alekun ere ori epo rọbi kan ẹkun naa.

Wọn ni wiwa epo lẹkun naa lo n da wahala ayika ati agbegbe tawọn eeyan agbegbe naa n koju silẹ.

Fun ọpọlọpọ ọdun lawọn ọdọ agbebọn ẹkun Niger Delta fi wa lọrun ijọba apapọ nipa jiji awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ awapo lagbegbe naa gbe ti wọn si n kọlu awọn irinṣẹ iwapo rọbi bii ọpa epo.

Aarẹ orilẹ€de Naijiria tẹlẹ, Umaru Musa Yar'Adua lo gbe igbesẹ idasilẹ eto idariji fawọn agbebọn naa lọdun 2009 eyi to fopin si wahala awọn ọds agbebọn lẹkun Niger Delta.

Amọṣa, lọwọ yii awsn ọdọ agbegbe naa tun ti n lagogo ikilọ pe afaimọ ki awọn ma tun pada soko wahala wọn nibẹ.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams