Insecurity in Oyo: Mogaji Moshood ní àwọn alága ìbílẹ̀ ń fẹ́ kí Makinde ró wọn lágbára láti kojú ètò ààbò

Oríṣun àwòrán, Vanguard
Ọkan lara awọn Mọgaji ilu Ibadan, Mọgaji Moshood ti sọ fún BBC Yoruba pe Gomina Seyi Makinde ko ṣe amulo imọran tawọn Mọgaji fun un, lori ọna lati wa ojutuu si eto abo to mẹhẹ nipinlẹ Oyo.
Mọgaji Moshood ṣalaye pe Makinde fun ra rẹ lo ṣe ipade pọ pẹlu awọn Mọgaji.
"Ninu ipade ti a jọ ṣe pọ ni Makinde ti sọ fun wa, lati ko ipa ninu wiwa ojutuu sí ọrọ eto abo nitori awa ni a sun mọ awọn araalu julọ.
Emi gẹgẹ bi ọkan lara awọn Mọgaji ṣepade pọ pẹlu alaga ìjọba ibilẹ meji sí mẹta lori ọrọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Adájọ́ fi ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tí DSS kó nílé Sunday Igboho sí ọjọ́ ọdún Iléyá
- Agbébọn já bàálù ológun bọ́, orí kó Abayomi Dairo, awakọ̀ bàálù náà yọ
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọ Winners' Chapel dá pásítọ̀ 41 dúró tórí ọ̀rọ̀ owó?
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ pa ẹ̀ṣẹ̀ Mùsùlùmí rẹ́
- "Seyi Makinde, yé dá ìjọba ṣe, wá nǹkan ṣe lórí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ́"
- Ojú àwọn arìnrìnàjò rí màbo lójú ọ̀nà Márosẹ̀ Ibadan sí Eko torí ọdún Ileya
- Wo ǹkan mẹ́ẹ̀dògún tó yẹ kí o mọ̀ nípa olówó ayé Obi Cubana
- Adójútini ni Bíṣọ́bù Kukah lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa Buhari l'Ámẹ́ríkà - iléeṣẹ́ Áàrẹ
Awọn alaga ti a jọ sọrọ pọ ni ki gomina fawọn laṣẹ, ki awọn le lagbara lati ṣe ohun tí awọn ba fẹ ṣe lori ọrọ abo.
Bakan naa ni awa Mọgaji tun gba Makinde ni imọran wí pe, ki ijọba ro awọn to n da ilu ru lagbara, ki wọn le maa ri nkan ṣe.
A jọ fẹnuko nibi ipade naa pẹlu aṣoju gomina pe, ki a ṣe ipade pọ pẹlu awọn to n ṣe jagidijagan ki a le sọ fun wọn ohun ti ijọba fẹ ṣe fun wọn.
Ohun to ṣẹlẹ pẹlu awọn to da rogbodiyan silẹ ni pe awa ni a ri wọn gẹgẹ ara wa, awọn ko ri wa bẹẹ.
Ṣugbọn awa Mọgaji ko le lọ da ṣe ipade pẹlu awọn eeyan yii lai jẹ pe ijọba ti fún wa ni ohun kan lati fun wọn.
Bẹẹ gẹgẹ ni mo ṣalaye fun gomina, ti wọn si sọ fun mi pe awọn yoo wa nkan ṣe sii.
Ara awọn imọran ti a fún Makinde niyii, ṣugbọn ijọba rẹ ko mu ọkankan lo nibẹ." Mọgaji Moshood lo ṣalaye bẹẹ.
Mọgaji Moshood tun fikun ọrọ rẹ pe, atẹjade ti igbimọ awọn Baalẹ at'awọn Mọgaji fi sita lori eto abo to mẹhẹ,wa lati mu ki gbogbo rẹ le dara naa ni.
Mọgaji Moshood ni awọn ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Makinde lori ọna ati wa ojutuu si eto abo to mẹhẹ.
"Ti gomina ba ranṣẹ pe wa, a o da a lohun nitori a ko le da a da ọrọ to wa nilẹ yii.
Ṣugbọn awa o lagbara kankan lati ṣe ohun kan, ijọba lo lagbara, agbara si ni eeyan maa fi n ṣe nkan," Mọgaji Moshood lo sọ bẹẹ.

"Seyi Makinde, yé dá ìjọba ṣe, wá nǹkan ṣe lórí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ́"

Oríṣun àwòrán, oyo state government
Awọn igbimọ oriade nilẹ Ibadan ti bu ẹnu atẹ lu gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lori ọwọ yẹpẹrẹ, ti wọn lo fi n mu eto aabo nipinlẹ Oyo.
Atẹjade kan ti awọn ọba alaye naa fisita lẹyin ipade wọn tun sisọ loju rẹ pe awọn ọba yii tun koro oju si bi gomina se takete sawọn igbimọ ọba alaye, lati maa da isejọba se.
Ninu awọn ọmọ igbimọ lọba lọba naa, la ti ri awọn olori to di akoso awọn agbegbe kọọkan mu nilu Ibadan, to fi mọ awọn Mọgaji agboole kọọkan ati igbimọ Olubadan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọkọ Lizzy Anjorin fí ẹ̀bùn ọkọ̀ N20m fi ta lọ́rẹ
- Buhari kò jẹ́ kí Yoruba àtàwọn ẹ̀yà míràn gbérí ní Naijiria - Ẹgbẹ́ Yoruba VOR
- "Mo fi nǹkan ọkùnrin mi sínú àgádádogo fún ọ̀sẹ̀ méjì fún ìbálòpọ̀, wàhálà bá de"
- Àwọn egungun ẹ̀yìn mi lágbo tíátà ní Adebimpe Oyebade fi ọ̀nà ẹ̀bùrú gbà mọ́ mi lọ́wọ́ - Yomi Fabiyi
- Wo àwòrán bí ìrìnàjò Hajj ṣe n lọ ní Mecca lásìkò Covid-19
- Mo tún ibojì Funmi Martins ṣe torí ojú ń tì mí nípa ipò ìtìjú tó wà - Ashabi Olorisha
Awọn ọba alaye naa lo salaye pe gbogbo aayan awọn lati fọrọ werọ pẹlu gomina Makinde lori ipo ti nnkan de duro nilẹ Ibadan, ni ko so eso rere.
Koda, wọn ni awọn tun ti parọwa si Alajia ti Ajia, Ọba Nureni Yusuf pe ko gba gomina nimọran pe ko tun iwa rẹ se.
Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ fun iwe iroyin Punch, Ọba Lekan Balogun tii se Otun Olubadan tilẹ Ibadan, salaye pe lootọ ni gomina jinna sawọn oriade nipinlẹ Oyo.
Ọba Balogun ni igbimọ awọn Ọba alaye naa ko ni ohunkohun ninu lati tako gomina Makinde, ju pe ko ko fi opin si eto aabo to mẹhẹ nilẹ Ibadan lọ.
"Ijọba nikan ko le fopin si eto aabo to mẹhẹ, awọn ọba alaye to sunmọ awọn araalu julọ ni ojuse pataki lati se lati ri daju pe aifararọ aabo di ọrọ itan.
Idi ree ta fi n beere fun ajọsepọ lati ọdọ ijọba, ki wọn le maa ba maa sisẹ tako ara wọn.


















