Oyo Insecurity: Kí lo dé tí ìpànìyàn, ìjínigbé, ìdigunjalè ń peléke síi lábẹ́ Gómìnà Makinde

Aworan Alhaja Sherifat Adisa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sherifat Adisa

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo sọ pe awọn n wa afurasi to ku ti wọn lọwọ si ipaniyan oniṣowo obinrin kan ati awọn ibatan rẹ meji ni Ibarapa.

Olugbenga Fadeyi to fi ọrọ yi to awọn oniroyin leti ninu atẹjade kan,sọ pe ọrọ ipaniyan yi ti to Kọmisana Oyo, Nwachukwu Enwonu leti ati pe iwadii n tẹsiwaju.

Iṣẹlẹ ipaniyan taa n wi yi waye ni agbegbe Idere ni ijọba ibilẹ Ibarapa lọjọ Keji oṣu Kini ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ, arabinrin oniṣowo ti wọn pa yi lo n jẹ Alhaja Serifat Adisa to si jẹ oludari ile epo Subawa ni opopona Igboora/Idere.

Yatọ si Alhaja Adisa, awọn ibatan rẹ meji faragbọta ti awọn oniṣẹ ibi yi tun yin mama awọn ọmọ ọdun mẹsan yi nibọn.

Atẹjade yi tun fidi ọrọ mulẹ pe lẹyin wakati diẹ ti wọn ṣọṣẹ ni awọn olubi yi tun lọ ji dokita kan gbe nile rẹ ni Ibarapa yi kan naa.

''Nipa ijinigbe dokita kan ti orukọ rẹ n jẹ Dokita Akindele ni Tapa lagbegbe ariwa Ibarapa nipinlẹ Oyo lọjọ Keji oṣu Kini ọdun yi, ọrọ yi n jẹ ohun kọ ileeṣẹ ọlọpaa lomi nu''

Lẹnu lọọlọ yi, niṣe ni iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe n peleki si ni Ipinlẹ Oyo.

Bi a ko ba gbagbe awọn agbebọn kan pa eekan ẹgbẹ oṣelu PDP Fatai Aborode nigba to n dari bọ lati oko rẹ.

Ni ọjọ kọkanla oṣu kejila ọdun 2020 ni wọn da lọna lopopona Apodun ni Igangan,gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe wi.

Awọn afurasi mẹrin ni wọn ni wọn ṣiṣẹ yi ti awọn ọlọpaa ṣi yi n wa awọn afurasi naa di ba ti ṣe n sọrọ yi.

Laarin Tapa ati Aiyete ni Fatai Aborode ti dakẹ nigba ti wọn n gbe lọ si ile iwosan to wa ni Igboora.

Ẹwẹ ẹgbẹ alagbata epo aladani ni Naijiria ti kesi Gomina Makinde lati wa wọrọkọ fi ṣada lori iṣekupani ati ijinigbe to n gbogo ni ipinlẹ Oyo.

Ẹgbẹ naa fi ọrọ yi sita ninu atẹjade kan lọjọ Aiku lẹyin iku Alhaja Sherifat tawọn ajinigbe ṣeku pa.