Akure Death: Ọmọ ọdún mẹ́wàá ṣàlàyé ìdí tó ṣe ti àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdun kan àbọ̀ sínú kàǹga

Oríṣun àwòrán, @NtaAdo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣinkun ofin mu ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹwaa kan ti wọn fẹsun ipaniyan kan lagbegbe Owode, ni ijọba ibilẹ Ariwa Akure.
Wọn fẹsun kan afurasi naa, ti awọn obi rẹ jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Sokoto, pe o ti aburẹ rẹ ọkunrin sinu kanga.
Bo tilẹ jẹ baba kan naa lo bi awọn mejeji, iya ọtọtọ lo bi wọn.
- Kí ló tún ṣe Òṣèré fíìmù Yorùbá míì tó ń gba ẹ̀jẹ̀ àtomi níléèwòsàn?
- Báyìí ni Àrẹ̀mọ Ooni Adeyeye Ogunwusi ṣe wọ ṣọ́ọ̀ṣì fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bá bàbá rẹ̀ ṣe ìdúpẹ́ ìwúyè
- Mo gbóríyìn fún Buhari bó ṣe dóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé ní Kankara
- Ọsẹ́ tí ọkọ̀ aképo tó gbiná lẹ́bàá Otedola Estate l'Eko ṣe rèé
- 'Ìdí tí a ò fi pa àwọn ajínigbé tó gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kankara nìyìí'
- Òṣèré tíátà Yorùbá yìí la orí mọ́lẹ̀ nígbà tó ń ṣe sinimá lọ́wọ́
- Àwọn ìgbésẹ̀ tóo lè fi so NIN rẹ̀ pọ mọ́ síìmù MTN, Glo, Airtel ati 9Mobile rẹ
Iroyin ni lẹyin to ti ọmọ ọdun kan ati oṣu mẹjọ naa sinu kanga tan lo sọ fun baba rẹ pe wọn ti ji ọmọ ọhun gbe.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bolaji Salami ni iṣẹlẹ naa waye lọjọ karundinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR
Salami ṣalaye fun awọn oniroyin pe "o kọkọ sọ fun baba rẹ pe awọn gbọmọ-gbọmọ lo ji aburo rẹ ọhun gbe ko to jẹwọ pe ọmọ naa wa ninu kanga."
- Báwo ni mo ṣe fẹ́ fi ìyàwó àfẹ́sọ́nà mi akáta hàn fáwọn òbí mi?
- Ọmọ Risikat olójú búlúù méjèéjì jẹ̀bùn oríire àti ìfà ńlá
- Ta ni obìnrin tó fẹ́ bá Dino Melaye ṣe ìgbéyàwó lọ́jọ́ kejì Kérésì?
- Lẹ́yìn ò rẹyìn, Wasiu Ayinde sọ̀rọ̀ nípa Ayinde Barrister
- Èdè àìyedè láàrin Seyi Makinde àtàwọn aṣòfin yanjú, àbá ọdún 2021 dòhun
Nigba to n sọrọ lori idi to fi ti aburo rẹ sinu kọnga, ọmọ ile iwe alakọbẹrẹ naa sọ pe ounn ko mọ pe ohun ti oun ṣe yoo yọri si iku ọmọdekunrin naa.
Lẹyin naa lo sọ pe oun ti i sinu kanga lati gbẹsan bi iya rẹ ṣe maa n fi iya jẹ oun.
O ni iyawo baba oun naa maa n fi iya jẹ oun leyin ti ija bẹ silẹ laarin baba ati iya oun, ti baba oun si gbe obinrin naa niyawo.
Bakan naa lo tun sọ pe baba oun fẹran oloogbe naa ju oun lọ, nitori naa ni oun ṣe ti ọmọ naa sinu kanga ṣugbọn oun ko mọ pe yoo mu ẹmi rẹ lọ.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe afurasi ọhun yoo foju bale ẹjọ laipẹ.














