Oyo 2021 Appropriation Bill: Makinde takú mọ́ àwọn aṣòfin lọ̀wọ̀ pé òun kò fẹ́ ìṣúná gbèsè

Gomina Seyi Makinde n gbe aba isuna 2021 kalẹ siwaju awọn asofin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Yoruba ni ohun ti yoo ba dara nigbẹyin, o lee kọkọ wọ nibẹrẹ.

Bẹẹ ni ọrọ ri lori aba eto isuna ipinlẹ Oyo fọdun 2021, eyi to fa ede aiyede laarin gomina Seyi Makinde ati ile asofin ipinlẹ Oyo.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Kẹrindinlọgbọn osu Kọkanla ọdun 2020 ni Makinde gbe aba isuna ọdun to n bọ kalẹ siwaju awsn asofin lati yiiri wo, ki wọn si fontẹ lu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Apapọ owo aba isuna naa ni biliọnu lọna ọrinlerugba o din mẹwa naira (N266bn), tijọba si n reti abọ ile asofin lori rẹ.

Gomina Seyi Makinde sọrọ lẹyin to gbe aba isuna 2021 kalẹ siwaju awọn asofin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Amọ, iwadi BBC Yoruba fihan pe ariwo sọ laarin gomina Makinde ati awọn asofin naa lẹyin ọjọ diẹ lori aba isuna ọhun.

Idi ni pe iwadi BBC fidi rẹ mulẹ pe ile asofin fi awọn akansẹ isẹ kan sinu aba isuna naa, eyi ti owo rẹ to biliọnu mẹwa naira, ti apapọ owo aba isuna naa si fo soke lọ si biliọnu lọna ọrinlerugba o din meje naira (N273bn).

Sugbọn igbimọ ile asofin to wa feto isuna, ninu awijare rẹ ni, ile ti fi aaye silẹ fun ẹka alasẹ lati gba owoya fi gbọ bukata aba isuna ọhun, eyi to mu ki aba isuna naa ga soke.

Gomina Seyi Makinde sọrọ lẹyin to gbe aba isuna 2021 kalẹ siwaju awọn asofin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Ile asofin ni kii se pe awọn de idi fun aba isuna naa, tabi fi owo kun, eyi ti yoo bọ sapo awọn.

Amọ Gomina Makinde la gbọ pe o fi apa janu pe nibo ni oun yoo ti ri alekun biliọnu mẹwa naira lati fi gbọ bukata isuna ọhun lasiko ọda owo to n ba ilẹ wa finra yii.

Gomina Makinde ni oun ko fẹ ki owo isuna ọdun 2021 naa ga soke debi pe yoo nira lati gbọ bukata rẹ, eyi to le mu alekun ba gbese to wa lọrun ipinlẹ Oyo.

Amọ lẹyin o rẹyin, ile asofin ati ẹka alasẹ ipinlẹ Oyo fi ọgbọn agba yanju ede aiyede naa, to si yanju nitubi n nubi.

Àkọlé fídíò, Zlatan: Ọ̀rẹ́ ni mo sìn lọ ‘studio’ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ orin lẹ́yìn tí mo kùnà ìdánwò WAEC

Igun mejeeji si lo pada gba pe ko ni dara ki wọn se agbekalẹ isuna fọdun to n bọ ti yoo nira lati se amusẹ rẹ, tile asofin si yọ owo gbese to ni oun fi sori aba isuna ọhun, eyi to mu ko ga soke.

Lẹyin o rẹyin, ile asofin Oyo fontẹ lu aba isuna ọdun 2021 naa, eyi ti apapọ owo rẹ jẹ biliọnu lọna ọtalerugba naira o le mẹjọ (N268bn).