Omoyele Sowore: Ẹgbẹ́ aṣòfin Amẹ́ríkà ní ìjọba ń tẹ ẹ̀tọ́ olùdíje ààrẹ́ tẹ́lẹ́ náà lóju

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore
Ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni orilẹede Amẹrika ti kesi ijọba ilẹ wa pe ko tu eekan lẹyin ọrun oludije tẹlẹ fun ipo aarẹ, Omoyele Sowore.
Ẹgbẹ naa ni ijọba ko ni ẹri to daju rara lati ba oludije aarẹ tẹlẹ naa se ẹjọ lori ẹsin idaluru ti wọn fi kan.
Bẹẹ ba gbagbe, Sowore ni ọwọ awọn agbofinro tẹ lọjọ Kẹta osu Kẹjọ ọdun 2019 lori ẹsun o n gbidanwo lati se iwọde kan to pe Revolution Now.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú iṣẹ́ wo ní Funke Akindele rán sí Bukunmi Oluwasina, tó fa ariwo lórí ayélujára?
- "Buhari, o kò ṣe bẹbẹ kankan láì jẹ́ pé o gba Leah Sharibu náà sílẹ̀"
- Wo àwọn nǹkan to tún nílò NIN fún yàtọ̀ fún ìforúkọsílẹ̀ síìmù
- Ilé aṣòfin àgbà yọ gómìnà nípò, ẹni tó fi owó ìlú rán ọmọ lọ sí Amẹ́ríkà
- Amẹ́ríkà yarí pé àwọn agbégbọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 344 gbọ́dọ̀ fojú winá òfin
- Ẹ̀ẹ̀kan láàrin ọjọ́ méjì là ń jẹun ní ìgbèkùn, ìyà jẹ wá - Akẹ́kọ̀ọ́ Kankara ṣàlàyé
- Sé Boko Haram ń pẹ̀ka kiri Nàíjíríà ní ìjínigbé ṣe burú báyìí?
- Ọla Adedibu ní Ladoja jẹ̀ tó fi wọlé Gómìnà l‘Oyo labẹ ẹgbẹ́ PDP - Obasanjo
- Ẹ̀sìn kò fàjà! Obìnrin Mùsùlùmí ṣe ilé àlúfà ní ọ̀ṣọ́ fún Kérésìmesì
- Àwọn gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ti kùnà láti pèsè ààbò tó péye fún aráàlú - Ẹgbẹ́ Majeobaje
Iwọde naa si ni Sowore lo wa lati tako eto isejọba ti ko mọyan lori atawọn iwa aidaa miran ni Naijiria.
Lẹyin naa ni ijọba gbe asaaju ẹgbẹ Revolution Now ọhun lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o gbimọ lati da omi alaafia Naijiria ru to fi mọ lilu jibiti ati tita abuku aarẹ Muhammadu Buhari.

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore
Amọ ẹgbẹ Amofin Amẹrika ni iti ọgẹdẹ ni awọn ẹsun ti wọn fi n kan Sowore ọhun, ko si to ohun to yẹ ki ijọba apapọ yọ ada si.
Wọn ni pipe fun iwọde alaafia kii se ete lati dijẹ gbajọba, bẹẹ si ni ẹjọ ti wọn n ba Sowore se ti tako ẹtọ to ni labẹ ofin lati sọ ohun to ba wu, pipejọ sibi to wu ati ẹtọ si igbẹjọ lai fi falẹ.
Ẹgbẹ naa wa n rọ awọn agbofinro lorilẹede naijiria ati ijọba apapọ lati fi Sowore lọrun silẹ nitori awọn ẹri ti wọn ko jọ ko lẹsẹ nilẹ lati ba se ẹjọ.














