Impeached Kenya Governor: Sonko Mbuvi ní àwọn alájẹbánu tóun dí lọ́wọ́ ló yọ òun nípò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gomina ilu Nairobi, tii se olu ilu Kenya, Mike Sonko Mbuvi ni wọn yọ kuro nipo lẹyin ti ile asofin agba orilẹede naa fi ontẹ lu iyọnipo tile asofin agbegba se.
Awọn asofin agba naa lo ni Sonko jẹbi ẹsun mẹrin ọtọọtọ ti wọn fi kan, paapaa julọ, iwa titapa si ofin, asilo ipo, hihu iwakiwa atawọn iwa ọdaran miran labẹ ofin.
Lara awọn ẹsun tawọn asofin ilu Nairobi fi kan gomina Sonko ni pe o lo owo ilu lati ran ọmọbinrin rẹ lọ silu New York lorilẹede Amerika lọdun 2018.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú iṣẹ́ wo ní Funke Akindele rán sí Bukunmi Oluwasina, tó fa ariwo lórí ayélujára?
- Amẹ́ríkà yarí pé àwọn agbégbọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 344 gbọ́dọ̀ fojú winá òfin
- Ẹ̀ẹ̀kan láàrin ọjọ́ méjì là ń jẹun ní ìgbèkùn, ìyà jẹ wá - Akẹ́kọ̀ọ́ Kankara ṣàlàyé
- Sé Boko Haram ń pẹ̀ka kiri Nàíjíríà ní ìjínigbé ṣe burú báyìí?
- Ọla Adedibu ní Ladoja jẹ̀ tó fi wọlé Gómìnà l‘Oyo labẹ ẹgbẹ́ PDP - Obasanjo
- Ẹ̀sìn kò fàjà! Obìnrin Mùsùlùmí ṣe ilé àlúfà ní ọ̀ṣọ́ fún Kérésìmesì
- Àwọn gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ti kùnà láti pèsè ààbò tó péye fún aráàlú - Ẹgbẹ́ Majeobaje
Bakan naa ni wọn lo tun se owo iranwọ eto ẹkọ fawọn ọmọ mẹkunnu nilu Nairobi basubasu.
Sonko ni ọpọ eeyan mọ bii ẹni to n gbe igbe aye olowo nla nipa wiwọ asọ ati goolu olowo iyebiye amọ gomina tẹlẹ naa ti sẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan.
Sonko ni awọn eeyan to kundun kiko owo ilu jẹ nilu Nairobi ti oun da lọwọ kọ nidi iwa ajẹbanu lo n ba oun ja lati ri ẹyin oun.
Kii se igba akọkọ ree ti ẹnu yoo kun Sonko nitori ẹnu kii sin lara rẹ. Awọn alasẹ ọgba ẹwọn lorilẹede Kenya fi ẹsun kan gomina ti wọn yọ nipo naa pe o sa kuro lọgba ẹwọn logun ọdun sẹyin.
Bẹẹ si ni Sonko gba pe lootọ ni oun sa kuro lọgba ẹwọn lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan lori mohunmaworan.
Osu Kejila ọdun 2019 si ni wọn tun mu sahamọ pe o lọwọ ninu iwa ajẹbanu.
Gomina tẹlẹ naa lo fi ọpọ igo ọti lile Hennessy sinu apo imọtoto fun arun Coronavirus ti wọn n pin fawọn olugbe ilu Nairobi, to si ni ọti lile naa le dena arun Covid-19.
Sonko ni gomina keji to wa lori oye ti wọn yoo yọ nipo lori awọn ẹsun asemase.
Ireti si wa pe awọn eeyan ilu Nairobi yoo seto idibo miran lati yan gomina tuntun laarin osu meji niwọn igba ti Sonko ko ni igbakeji.














