Kidnappings in Nigeria: Aráàlú ń bèèrè pé ṣe agbébọn ló ń jí èèyàn gbé àbí Boko Haram?

Oríṣun àwòrán, @Reuters
Ikọ ajijagbara ẹsin Islam ni Iwọ Oorun Afrika, Boko Haram sọ pe, oun lo wa nidi bi wọn ṣe ji ogunlọgọ akẹkọọ gbe ni Iwọ oorun Ariwa Naijiria.
Bi wọn ṣe ji awọn akẹkọọ naa gbe nipinlẹ Katsina, ti mu ki ọpọ eyan ma a beere ibeere nipa bi Boko Haram ṣe l'agbara to ni Iwọ oorun Ariwa Naijiria, ati boya awọn ọmọ ogun orilẹ-ede naa le bori wọn.
O ti le ni ọdun mẹwa, ti awọn ọmọ ikọ Boko Haram ti n ṣiṣẹ ni Ila oorun Ariwa Naijiria, paapaa ni ipinlẹ Borno ati awọn to yi i ka.
- Obìnrin olówònààbì ta ọmọ rẹ̀ oṣù mẹ́rin ní N300,000
- Egbìnrìn ọ̀tẹ̀! Àṣírí ilé ìmúni nígbèkùn míràn tú síta ni Katsina
- Ajínigbé tú ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn
- Báwo làwọn agbébọn ṣe rí ASP Ọlọ́pàá méjìlá jígbé?
- Ìdí tí àwọn ìpińlẹ̀ se ń ti ilé ẹ̀kọ́ ní ìhà ìwọ̀ Oòrun-Àríwá Nàìjíríà rèé
Lọdun 2014, Boko Haram ji awọn akẹkọọbinrin gbe nile ẹkọ Chibok, nipinlẹ Borno. Ọpọ awọn akẹkọọ naa ni ko ti i di riri pada.
Bakan naa lọdun 2018, wọn tun ji awọn akẹkọọbinrin gbe nipinlẹ Yobe.

Oríṣun àwòrán, AFP
Amọ ṣa, awọn janduku ni wọn lo n ṣe ikọlu ni Iwọ oorun Ariwa Naijiria bayii, nitori pe ko si ẹni to mọ ẹgbẹ to wa nidii rẹ. Wọn ma n ji maalu ati eeyan gbe.
Eyi si ti mu ki ibẹru wa pe Boko Haram ti n pẹka.
Olootu ajọ kan to n tọpinpin igbesunmọmi, Jamestown Foundation Terrorism Monitor, Jacob Zenn, sọ pe awọn iṣẹlẹ asiko yii jọ iṣẹ awọn agbesunmọmi.
"Nkan ti wọn fi ara balẹ ṣeto ni, pẹlu iranlọwọ Boko Haram ati imọ adari rẹ, Abubakar Shekau."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nkan ti gomina ipinlẹ Katsina tẹnumọ ni pe, awọn ajinigbe lo gbe awọn ọmọ naa.
Ọdun 2012 ni iṣẹ ọwọ Boko Haram lọ soke, to si n ṣe ikọlu titi de orilẹ-ede Niger ati Chad, to mule ti Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe agbegbe kekeeke ni ikọ naa n dari bayii, amọ o si n ṣe ikọlu tako nkan ti Aarẹ Muhammadu Buhari n tẹnumọ pe, awọn ti "sọ ikọ Boko Haram di alailagbara".
Ajafẹtọ ọmọniyan kan ni Naijiria, Nkasi Wode, sọ pe "niṣe ni Boko Haram ati awọn janduku n ṣiṣẹ ni Iwọ oorun Ariwa ati Ila oorun Ariwa Naijiria, lai si idiwọ kankan".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oun lo mu ki awọn eeyan o ma a sọ fun ijọba lati ṣe atunto ilana eto aabo.
Olori ẹsin Musulumi ni Naijiria sọ pe "alaye wo leeyan fẹ ṣe lori bi awọn eeyan yii ṣe n rinrinajo pẹlu ọpọlọpọ ọkọ, lai si ẹni to ri wọn?"
Bayii ni rogbodiyan ṣe n lọ soke si ni Ariwa Naijiria
Ila oorun Ariwa Naijiria ti n foju wina wahala lati ọjọ pipọ, awọn eeyan to ku si tun pọ si ni ọdun yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọla Adedibu ní Ladoja jẹ̀ tó fi wọlé Gómìnà l‘Oyo labẹ ẹgbẹ́ PDP - Obasanjo
- Ẹ̀sìn kò fàjà! Obìnrin Mùsùlùmí ṣe ilé àlúfà ní ọ̀ṣọ́ fún Kérésìmesì
- Àwọn gómìnà nílẹ̀ Yorùbá ti kùnà láti pèsè ààbò tó péye fún aráàlú - Ẹgbẹ́ Majeobaje
- Ọ̀fẹ́ ló bá dé, Boko Haram kọ́ ló jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé, a kò san kọ́bọ̀ fún ìdáǹdè wọn - Masari
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Oladimeji?
- Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nìkan ni ọ̀nà abáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà- Olusegun Obasanjo
- Ìtura ìgbà díẹ̀ ni bọ́dà tí ìjọba ṣí padà, kò lóòre nínú - Onímọ̀ ọrọ̀ ajé
- Wo ìdí tí ààrẹ Buhari kìí fi ṣe ẹ̀dà Jubril láti Sudan
Ni Iwọ oorun Ariwa Naijiria, gbogbo igba ni awọn eeyan n ku ipinlẹ Zamfara, Katsina ati Kaduna, nitori ija oṣelu ati janduku.
Abajade iwadii ti ajọ to n mojuto rogbodiyan l'agbaye fi sita nibẹrẹ ọdun yii fihan pe ija ilẹ to n waye laarin awọn agbẹ to jẹ Hausa ati awọn daran-daran Fulani, lo jẹ ipilẹ rogbodiyan naa.
O tun jẹyọ pe awọn alakatakiti ẹsin n gbeero lati lo anfaani bi eto abo ṣe ri, fi mu ki afojusun wọn wa si imuṣẹ.
Ọna wo ni awọn ọmọ ogun n gba ṣe iṣẹ wọn?
Ija lati oju ofurufu ni ileeṣẹ ologun Naijiria ṣaba n lo, lati ri aye wọ awọn ibudo awọn agbesunmọmi, to wa ninu igbo.
Bakan naa ni ileeṣẹ ologun ma n fi aworan ati fidio sita lori ayelujara Twitter rẹ pe, oun n ṣẹgun ikọ naa.
Awọn ologun ko fi bẹ ẹ ja lori ilẹ mọ, nitori pe awọn to n ku lara wọn ti pọju.

Oríṣun àwòrán, Twitter/DefenceInfoNG
Iṣoro kan to wa nibẹ ni pe araalu ko fi inu tan awọn ọmọ ologun.
Ọgbẹni Wode sọ pe "ọpọlọpọ awọn ilu lo n sọ pe awọn ọmọ ogun ati ọlọpaa kii gbe igbesẹ kankan, nigba ti awọn ba fi to wọn leti pe awọn agbesunmọmi fẹ ẹ ṣe ikọlu nibi kan."
Awọn onimọ nipa eto abo sọ pe, awọn ilu nlanla ni iru nkan bẹ ẹ ti wulo, kii ṣe ni igberiko.












