Nigeria Borders open: Onímọ̀ ọrọ̀ ajé ní ìlànà tẹ́tẹ́ títa ní ìjọba ń lò fétò ọ̀rọ̀ ajé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọru ni ijọba orilẹ-ede Naijiria kede pe ki awọn ẹnu ibode mẹrin di ṣiṣi pada.
Oṣu Kẹjọ, ọdun 2019 ni awọn ibode naa ti wa ni titi pa, nitori pe ijọba 'fẹ ẹ fi opin si kiko nkan ijagun wọle lọna aitọ, ki opin le ba ipenija to n koju eto aabo, ati lati mu idagbasoke ba ọrọ aje Naijiria.
Inu ọpọlọpọ araalu lo dun si aṣẹ tuntun yii nigba ti ijọba kede lati si ẹnu bode mẹrin pada ni Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari, o ṣẹ ilẹ̀ Yorùbá púpọ̀, ló àyájọ́ ìbí rẹ̀ láti tọrọ àforíjìn - PDP
- Wo ìdí tí ààrẹ Buhari kìí fi ṣe ẹ̀dà Jubril láti Sudan
- Ẹ dín agbára ìjọba àpapọ̀ kù, kẹ ṣì ṣe àgbékalẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ - Tinubu bẹ̀bẹ̀
- Wo eyi to súnmọ́ ọ nínú àwọn ibùdó 203 fún ìforúkọsílẹ̀ fún NIN rẹ
- Adigunjalè méjì ko ìjàmbá ọ̀kadà lẹ́yìn ìṣẹ́ ibi n‘Ibadan, ọ̀kan kú lójijì, aráàlú dáná sun èkejì
- Àwọn ohun kàyéèfì tó le mú kí ọmọbìnrin ní oyún ìju
Ṣugbọn, onimọ kan nipa ọrọ aje, Gbadamosi Olusola, to jẹ Igbakeji Aarẹ Ẹgbẹ awọn onimọ ọrọ aje ati iṣiro ni Naijiria, sọ fun BBC pe, idẹrun ọlọjọ diẹ ni yoo mu wa fun araalu.
Eyi ko ṣẹyin bi coronavirus ṣe ti ṣakoba fun ọrọ aje.
Oore wo ni titi bọda ṣe fun Naijiria?
Ọgbẹni Gbadamosi Olusola ṣalaye pe ko si anfaani kankan ti Naijiria jẹ lara titi awọn ẹnu ibode, nitori pe iṣẹ fayawọ lọ soke si, ti ko si tun si ayipada lori ọrọ eto aabo.
Bakan naa ni Ọgbẹni Gbadamosi tọka si pe, o tun mu ki owo ọja lọ soke pẹlu ìdá tó le ni ọgọrun.
Eyi ti ko ṣẹyin eto aabo to mẹhẹ, to ti mu ki awọn agbẹ fi oko wọn silẹ.
- Ìrẹ̀sì kò gbọdọ̀ wọlé níbáyìí ta ṣí ẹnu bodè padà - Ìjọba àpapọ̀
- Jide Kosoko forin sẹ́nu pé òun ni igi lẹ́yìn ọgbà Mr Latin lórí ipò ààrẹ TAMPAN tó wà
- Ó pé ọdún mẹ́wàá tí Barrister kú; wo ǹkan tó yẹ láti mọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórin, tẹ̀wé-tẹ̀wé, akọ̀wé àti sọ́jà
- Àìmọ̀kan ló mú mi hu ìwà tí mo hù kọjá sẹ́yìn, Jonathan dárí jì mí - Dino Melaye
Njẹ anfaani to wa ninu bi ijọba ṣe ṣi bọda pada?
Ọgbẹni Oludola Gbadamosi ni itura yoo ba araalu, nitori pe owo yoo pọ si nilu.
Awọn oniṣowo ti bi bọda ṣe wa ni titi pa ṣe akoba fun yoo bẹrẹ iṣẹ pada.
Amọ o tun sọ pe ipa ti ko dara ni igbesẹ yii yoo ni lara akitiyan ati owo ti ijọba ti na sori eto ọgbin lasiko ti ẹnu ibode wa ni titi pa.
Nitori pe awọn ileeṣẹ abẹle ko ni le fi iga gbaga pẹlu ọja to n wọle lati ilẹ okeere, lori iye ti wọn n ta a.
O ṣe apejuwe bi owo irẹsi, ati ẹja, ẹran nkan abiyẹ, ṣe lọ soke si i, lasiko ti ijọba ti ẹnu ibode, nitori pe abẹle nikan lo ti n wa.
Ọgbẹni Gbadamosi tun sọ pe, Naijiria ko ni agbara lati pese gbogbo nnkan ti araalu nilo, paapa awọn nkan ti ẹnu n jẹ bi irẹsi ati ẹja.
Nitori naa lo ṣe ṣe pataki fun ijọba lati kọkọ mojuto awọn ipenija to wa nilẹ bi eto aabo, to ti mu ki awọn agbẹ fi oko silẹ, ati ina mọnamọna.
O ni o ṣeni laanu pe, bi igba ti eeyan n ta tẹtẹ ni ilana ọrọ aje ti Naijiria n lo, kii ṣe eto to ṣe e tọka si.
Ti ko ba si ṣe gbogbo nkan to yẹ, yoo tun pada si ẹsẹ aarọ ni.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@nigeria customs
Ohun ti Aarẹ Muhammadu Buhari sọ lọsẹ to kọja ni pe awọn orilẹ-ede to paala pẹlu Naijiria ti ni òye nkan ti igbesẹ titi ẹnu ibode pa da le lori.
Ṣugbọn, a ko le sọ eyi to jẹ ninu ọrọ eto aabo ati ọrọ aje, nitori pe ko si ayipada rere kankan nibẹ.
Ìrẹ̀sì kò gbọdọ̀ wọlé níbáyìí ta ṣí ẹnu bodè padà - Ìjọba àpapọ̀
Minisita feto ẹnawo, eto isuna ati aato ilu, Zainab Ahmed ti kede pe ijọba apapọ si gbẹsẹ le awọn eroja kan pe ko ma wọle sorilẹede yii.
Minisita naa sisọ loju ọrọ yii lasiko to n bawọn akọroyin ile ijọba sọrọ lopin ipade igbimọ alasẹ ijọba ilẹ yii.
Ahmed, ẹni to kede pe ijọba ti pasẹ pe ki wọn si awọn ẹnu bode mẹrin kan pada nilẹ wa lọgan, tun salaye nipa awọn ọja ti ko ni le wọle sorilẹede yii lati oke okun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ohun kàyéèfì tó le mú kí ọmọbìnrin ní oyún ìju
- Ìdí tí àwọn ìpińlẹ̀ se ń ti ilé ẹ̀kọ́ ní ìhà ìwọ̀ Oòrun-Àríwá Nàìjíríà rèé
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 yóò dé sí Nàìjíríà nínú oṣù kíní ọdún 2021
- Jide Kosoko forin sẹ́nu pé òun ni igi lẹ́yìn ọgbà Mr Latin lórí ipò ààrẹ TAMPAN tó wà
- Ó pé ọdún mẹ́wàá tí Barrister kú; wo ǹkan tó yẹ láti mọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórin, tẹ̀wé-tẹ̀wé, akọ̀wé àti sọ́jà
- Àìmọ̀kan ló mú mi hu ìwà tí mo hù kọjá sẹ́yìn, Jonathan dárí jì mí - Dino Melaye
Awọn ọja naa ni Irẹsi, awọn ohun abiyẹ ati awọn eroja miran tijọba ti fofin de saaju lasiko to n ti awọn ẹnu bode wa pa.
Ahmed fikun pe loore koore ni awọn asọbode yoo maa paraaro awsn ẹnu bode ilẹ wa lati ri daju pe awọn eroja kotọ naa ko ri ọna wọle sorilẹede yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O tun salaye pe nigba ti yoo ba fi di ọjọ to kẹyin ninu ọdun yii, ijọba apapọ yoo si awọn ẹnu bode yoku to wa ni Naijiria silẹ.
Bakan naa ni ẹgbẹ awọn agbẹ ọlọsin adiẹ ti mu igbe bọnu pe nibayii tijọba ti si awọn ẹnu bode ilẹ wa mẹrin pade, o gbọdọ ri daju pe wọn ko ko awọn ohun abiyẹ wọ orilẹede yii.
Ọga agba fun ẹgbẹ naa, Onallo Akpa lo kede bẹẹ pẹlu afikun pe ijọba ko gbọdọ yẹsẹ kuro lori ileri to se lati se ọna mọ awọn ohun abiyẹ lati oke okun.
Aarẹ Buhari pàsẹ ki wọn si awọn bode Naijiria pada kiakia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti paṣẹ pe ki wọn ṣi awọn ẹnu ibode mẹrin loni wara n ṣesa.
Awon merin naa ni ibode Seme ni ẹkun Guusu Iwọ-Oorun, Illela ni ipinlẹ Sokoto, Maigatgari ni iha Ila Oorun-Ariwa ati Mfun ni ẹkun Guusu-Guusu.
Minisita eto isuna lo fi ikede yii sita lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ikejidinlogun ti ori ayelujara to waye l'Ọjọru ọsẹ.
Atẹjade naa tun wa loju opo Twitter agbẹnusọ aarẹ Buhari, Bashir Ahmad.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bakan naa lo ni ki wọn si awọn to ku ni ọjọ kọkanlelọgbọ̀n osu kejila ọdun yii.
Ṣaaju lọjọ kẹjọ oṣu kejila ọdun yii ni aarẹ Buhari ti safihan ipinu rẹ lati ṣi awọn ẹnu ibode naa.
O ṣalaye pe idi ti wọn fi gbe awọn ibode naa tipa wa lara akitiyan ijọba lati dẹkun kiko awọn nkan ija oloro ati oogun oloro wọ orilẹede Naijiria lọna aitọ.
Aarẹ Buhari sọ eyi nigba to n ṣepade kan pẹlu ẹgbẹ awọn gomina Naijiria ni ile aarẹ ni Abuja.
Titi ti wọn ti awọn ibode ọhun pa ti da ọpọlọpọ ipalara silẹ to si ti fa wahala laarin Naijria atawọn orilẹede agbegbe rẹ ti wọn si n kigbe pe ofin ijọba yii n pa ọrọ aje awọn lara.
Aarẹ ni "nibayii ti awọn orilẹede agbegbe wa ti ri ẹkọ kọ, ijọba ti ṣetan lati ṣi awọn ibode pada".
Ẹwẹ, ko ye ni pato ewo ninu gbogbo idi ti aarẹ Buhari ka ti wọn fi ti awọn ibode ọhun pa ti o wa gbagbọ pe o ti wa si imuṣẹ tori awọn mii n sọ pe erongba ti aabo ko yọri si rere.
O ti le lọdun kan ti awọn ibode orilẹede Naijria ti wa ni titi pa ko to wa di pe ijọba pinu lati ṣi wọn pada loṣu yii.


















