Kaduna, Zamfara àti àwọn ìpínlẹ̀ tó ti ilé ìwé nítorií wahala Boko Haram àti ìdí míràn.

Làásìgbò Boko Haram àti ọwọ́jà ẹlẹẹ̀kèjì àrùn coronavirus ti n fí ojú àwọn ènìyàn ri màbo ni ìhà àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́wọ́lọ́wọ́.
Kìí ṣe ǹkan tuntun pé ọ̀pọ ilé-ẹ̀kọ́ ni ìhà àríwá Nàìjíríà ló ti kéde pé àwọn ti gbé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀kọ́ tì, nítorí yálà ètò ààbò tó mẹ́hẹ tàbí nítóri àrùn Coronavirus to tun pada dé.
Onímọ̀ nípà ètò ẹ̀kọ́ Isa Sani tó n gbé ìlú Kano sàlàyé fún BBC pé ǹkan tó ṣẹlẹ̀ ni ìpińlẹ̀ Katsina, nibi ti ọmọ tó lé ni irinwo ti dàwátì, lẹ́yìn ti awọn agbébọ̀n yabo ilé ìwé GSSS ni ìlú Kankara jẹ ọ̀kan pàtàkì lára ìdí ti ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ fi ti ilẹ̀kùn wọ́n.
Ṣùgbọ́n kíni àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ń sọ?
Ìpínlẹ̀ Katsina
Gómìnà Aminu Bello Masari ti kéde pé ki wọ́n ti ilé ẹẹ̀ka lọ́jọ́ Àìkú, ọja kan lẹ́yìn ti àwọn awọ́n agbébọ̀n kọlu ilé ẹ̀kọ́ Govenment Science school ni ìlú Kankara.
Gẹ́gẹ́ bi gómìnà ṣe sọ nítori ọ̀rọ̀ ètò àbò tó ti polukurumusu ni agbègbè náà àti pé ìgbìyànjú n lọ lọ́wọ́ láti dóòlà àwọn ọmọ ti wọ́n ji gbé.
Ìpínlẹ̀ Zamfara
Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun, ìjọba ìpińlẹ̀ Zamfara náà kéde pé ki wọ́n ti àwọn ilé iwé mẹ́wàá kan to sún mọ́ ààlà ìpínlẹ̀ Katsina, nítori ǹkan tó ṣẹlẹ̀.
Agbẹnusọ fún gómìnà Zailani Bappah to bá BBC sọ̀rọ̀ sàlàyé pé gómìnà gbé ìgbésẹ̀ yìí nítorí ọ̀rọ̀ ààbò tó dẹnukọla ni pàápàá jùlọ ni ìpínll tọ múlé tì wọ́n.

Ìpínlẹ̀ Kaduna
Ní àgbègbè yìí ẹ̀wẹ̀, ìdí ti wọ́n fi gbé ilé-ẹ̀kọ́ ti ni nítorí ààrun coronavirus tó tún padà dé. Gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde tó fi síta, wọ́n gbé àwọn ilé ìwé tí, yálà ti aládani tàbi ti ìjọba ni láti dènà ààrun coronavirus tó tún n fẹ́ bọ̀, ti àwọn tó ni ààrùn náà sì tún ti n pọ̀ sii ni Nàìjíríà.
Ìpínlẹ̀ Kaduna wà lára àwọn ìpínlẹ̀ ti ààrun Covid-19 tún ti n peléke sii lọ́wọ́lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bi àtẹjáde ojoojúmọ́ àjọ NCDC, èyí sì ló mú kí gọmìnà El-Rufai pinu láti tilẹ̀kùn ilé-ẹ̀kọ́.
Ìpínlẹ̀ Kano
Ní ìpińlẹ̀ Kano tó ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ jùlọ ni agbègbè náà, ọjọ́ Isẹgun ni wọ́n pa á láṣẹ láti ti ilé ẹ̀kọ́.
Bótilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba kò sọ ìdí pàtó to fi tilẹ̀kùn, nínú àtẹjáde ti kọmísọ́nà ètò ẹkọ́ Muhammed Sanusi fi síta, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé isẹ́ náà to ba BBC sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé nítori ọ̀rọ̀ ààbò ni wọ́n ṣe tilẹ̀kùn ilé ìwé, pàápàá jùlọ oun ati Katsina jọ pààlà pọ̀.

Ìpínlẹ̀ Jigawa
Ìpínlẹ̀ yìí nítirẹ̀ ni nítori ọ̀rọ̀ corornavirus ni òun ṣe gbe ilẹ̀kun ilé-ẹ̀kọ́ tì, bótilẹ̀ jẹ́ pé ààlà àwọn àti ìpínlẹ̀ Katsina náà súnmọ ara wọ́n.
Rabiu Adamu to jé akọwé ile isẹ to n ri si ètò ẹ̀kọ́ nínú àtẹjáde rẹ̀ to fọwọ́si ṣàlàyé pé ènìyàn mẹrinla lo ni ààrun covid-19 lọ́jọ́ kan soso nípinlẹ̀ náà, nítori náà wọ́n kéde pé ki àwọn obi lọ mu ọmọ wọ́n láwọn ilé ìwé ti ọmọ ń gbe lọ́jọ́rú ki àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó n lọbọ̀ náà si dúro sílé.
Ìpínlẹ̀ Sokoto

Ní ti Sokoto, ètò ẹ̀kọ́ sì n lọ, kò sí ọ̀rọ̀ lórí bóya wọ́n yóò ti ilé ẹ̀kọ́ tàbi wọn o ni tì í.
Ọ̀kan nínú àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ gómìnà tó bá BBC sọ̀rọ̀ sàlàyé pé àwọn òun gan wà nílé ìwé lọ́wọ́ ko si sí èròngbá láti ti ilé ìwé bí àwọn ìpínlẹ̀ ti wọ́n múle ti ṣe n ṣe.
Ìpínlẹ̀ Kebbi
Bí àwọn Sokoto ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ náà ni Kebbi, gẹ́gẹ́ bi ọkan lára àwọn oṣìṣẹ́ ìjọba to ba BBC sọ̀rọ̀ ṣe sọ níbẹ̀ pé, kò sí ìpínu kankan láti ti ilé ìwé nítori pe àwọn ìpínlẹ̀ tó kù ń ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó ní ààbò tó dájú wà ni ìpińlẹ̀ Kebbi ko sì sí ìdí kan ti àwọn yóò fi ti ilé ìwé pa lásìkò yìí.












