Mọ̀ nípa Buruli ulcer, àrùn tó ń jẹ ẹran ara èèyàn tó ti pa èèyàn mẹ́fà ní Adamawa

Oríṣun àwòrán, Muhammad Ibrahim Malabu
Awọn oṣiṣẹ eto ilera nipinlẹ Yobe ti fidi rẹ mulẹ pe kokoro kan to n jẹ ẹran ara eeyan ti n kọlu awọn eeyan nipinlẹ naa, eyii ti wọn n pe orukọ rẹ ni 'Buruli ulcer.'
Kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ ọhun, Felix Tangwami, lo fidi iroyin ọhun mulẹ fun BBC ninu ifẹrọwerọ kan.
O ni "Ọdun to kọja ni a kọkọ gburo kokoro naa, o si ti pa eeyan mẹfa, kii ṣe eeyan mẹjọ bi awọn iroyin kan ṣe sọ.
"Àrùn náà ń tàn kalẹ torí àwọn tó mú rò pé wọn máa kú, tí wọ́n bá lọ sílé ìwòsàn"
Felix Tangwami tẹsiwaju pé "Nigba ti arun naa kọkọ bẹrẹ, awọn eeyan ro pe kokoro to bu wọn jẹ ninu oko lo n daamu wọn.
Amọ iwadii wa fi han pe ko ri bẹẹ nitori awọn ọmọde ti ko lọ sinu oko gan ni arun ọhun."
Ẹwẹ, kọmiṣọna naa fi kun pe awọn eeyan to n gbe ni ẹba ipinlẹ Adamawa wa lara awọn to jẹ ki arun naa tunbọ tan kalẹ si.
O ni "Ti wọn ba ti ko arun naa, niṣe ni wọn maa n lọ si ṣọọbu awọn to n ta oogun lati tọju rẹ, kaka ki wọn gba ile iwosan lọ.
"Wọn kii gba lati lọ sile iwosan latari pe wọn ro pe arun jẹjẹrẹ ni, ati pe wọn gbagbọ pe ti wọn ba lọ sile iwosan, iku lo maa ja si."
O fi kun pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun to ṣokunfa kokoro naa ati pe iṣẹ ti n lọ lọwọ lati rẹyin rẹ.
"Gbogbo igba ti wọn ba n tọju mi ni awọ ara mi maa n ja kuro"
Ẹnikan to ti ko arun naa, Mati Adamu to n gbe ni abule Malabu ni ijọba ibilẹ Fufore nipinlẹ Adamawa sọ pe lati ọdun meji sẹyin loun ti n ba arun naa finra, wọn ko si tii mọ ibi to ti wa titi di akoko yii.
Ọkunrin naa ṣalaye pe "Asiko ti mo n ṣiṣe ninu oko ni mo ko arun naa, lojiji ni mo ṣakiyesi pe o daabi pe ina n mi ni nu ẹsẹ mi.
"Nigba ti mo dele ni nnkan bii aago marun un irọlẹ, ẹsẹ mi ti wu, o si ti n dunmi, lalẹ ọjọ naa ni mo pe ẹnikan to n ta oogun lati wa tọju mi.
"Odidi oṣu mẹta ni mo lo nile ti mo n gba itọju ibilẹ ati itọju oogun oyinbo, lẹyin ọdun meji, mo ṣi n gbe pẹlu arun yii."
Adamu ṣalaye fun BBC pe ibatan oun meji ti wọn jọ n gbe nile kan naa lo ti ko arun naa bayii.

Oríṣun àwòrán, Muhammad Ibrahim Malabu
Arun wo ni Buruli ulcer?
Dokita Aliyu Salihu lati ile iwosan Usmanu Danfodiyo University Teaching Hospital, ipinlẹ Sokoto ṣalaye ohun to mọ nipa arun naa.
O ni arun naa jẹ eyii to maa n ba awọ ara ati iṣan inu ara ja, o si maa n jẹ ẹran ẹsẹ tabi apa eeyan.
O fi kun pe kokoro kan ti wọn n pe 'Mycobacterium' lo n ṣokunfa rẹ.
Dokita naa sọ siwaju si pe arun naa le tan lari ara ẹnikan si ẹlomiran.
Awọn ọna ti arun naa fi n tan kalẹ
- Lati inu omi to ni kokoro tabi omi adagun
- O maa n pọ lawọn agbegbe ti omi ba pọ si tabi ti ojo ti n rọ lemọlemọ
- Kokoro naa maa n wọ agọ ara lati oju egbo tabi ọgbẹ lara eeyan
- Awọn kokoro to n gbe ninu omi le fun eeyan ni arun ọhun ti wọn ba ge eeyan jẹ
Itọju arun naa
Dokita ọhun ṣalaye pe lara apẹrẹ arun naa ni ki ara eeyan wu bi pe kokoro bu ẹni naa jẹ.
Lẹyin naa ni oju ọgbẹ ọhun yoo maa dun eeyan ti ara ẹni bẹẹ yoo si maa gbona.
Lara awọn oogu n ti wọn fi n tọju rẹ ni oogun apakokoro ara 'antibiotics.'















