Ọ̀rọ̀ tún bẹ́yìn yọ, NUPENG ní iléepo Dangote yẹ àdéhùn, ìyanṣẹ́lódì ṣeéṣe kó bẹ̀rẹ̀ padà

Oríṣun àwòrán, Dangote Group/Nupeng
Lẹyin ọjọ meji pere ti wọn wọgile iyanṣẹlodi ti wọn gunle, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ẹka epo rọbi lorilẹede Naijiria, NUPENG, ti kede wi pe iyanṣẹlodi mii n kan ilẹkun lẹyin ti wọn fẹsun kan ileeṣẹ ifọporọbi Dangote wi pe o kọ eti ikun si adehun tawọn jọ ṣe lọjọ Iṣẹgun to kọja ni olu ileeṣẹ ajọ DSS niluu Abuja.
Ẹgbẹ NUPENG sọ ninu atẹjade kan to fi sita eyi ti aarẹ ẹgbẹ naa, Ọmọba Williams Akporeha ati akọwe agba, Afolabi Olawale buwọlu, pe ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ NUPENG kaakiri orilẹede Naijiria maa gbaradi fun iyanṣẹlodi mii ti yoo bẹrẹ laipẹ.
NUPENG ni awọn fẹnuko nibi ipade tawọn ṣe pẹlu ileeṣẹ ifọporọbi Dangote lọọfiisi ajọ DSS eyi ti minisita mẹta orilẹede Naijiria naa wa nibẹ pe awọn oṣiṣẹ Dangote lẹtọọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ.
Amọ, NUPENG lawọn ṣe akiyesi pe ileeṣẹ Dangote paṣẹ fawọn awakọ tanka epo rẹ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ naa l'Ọjọru ọjọ kẹwaa oṣu Kẹsan an ti i ṣe ọjọ keji tawọn ṣe ipade l'Abuja wi pe ki wọn ṣi sitika NUPENG kuro lara ọkọ wọn.
NUPENG sọ ninu atẹjade naa wi pe lọjọ keji ni wọn tun paṣẹ fawọn awakọ tanka naa pe ki wọn wa ọkọ wọ inu ileeṣẹ ifọporọbi Dangote lati lọ gbe epo.
Amọ, awọn awakọ tanka naa ko raye wọle tori wọn ni wọn o tẹle ofin to de gbigbe epo nile epo ifọporọbi.
NUPENG bu ẹnu ẹtẹ lu igbesẹ ileeṣẹ Dangote naa, wọn ni igbesẹ naa tapa si ofin ẹgbẹ ati ofin orilẹede Naijiria.
Ẹgbẹ NUPENG ko ni ko yẹ ki eeyan kan lagbara lati tapa si adehun tawọn alaṣẹ ijọba buwọlu.
NUPENG tun kepe ijọba apapọ lati dena lilo awọn ẹsọ eleto abo lọna ti ko tọ nigba ti faakaja ba n waye laarin awọn oṣiṣẹ ati ileeṣẹ kan.
Ẹgbẹ NUPENG ko ṣai kepe ẹgbẹ apapọ oṣiṣẹ, NLC, TUC, atawọn lẹgbẹ lẹgbẹ mii lati ṣatilẹyin fun NUPENG lori ọrọ to n wa nlẹ.
NUPENG kilọ pe ti eeyan ba jẹ ọlọrọ, iyẹn ko tumọ si pe o ga ju ofin lọ.

Oríṣun àwòrán, NUPENG

Oríṣun àwòrán, NUPENG
Kii ṣe dandan fáwọn oṣiṣẹ wa lati darapọ mọ ẹgbẹ - Dangote
Ẹwẹ, ileeṣẹ ifọporọbi Dangote ti sọ pe kii ṣe dandan fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ kan tabi omiran.
Ileeṣẹ Dangote ni ẹni to ba wu lo le darapọ mẹgbẹ oṣiṣẹ, gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ati ofin ẹgbẹ oṣiṣẹ lagbaaye ṣe la a kalẹ.
Ileeṣẹ Dangote sọrọ yii ninu esi rẹ si oniruuru ẹsun ti NUPENG fi kan an lara eyi ti wọn fi sọ pe ọgbọn imunilẹru ni Dangote n da ni ko ṣe fẹ kawọn awakọ tanka rẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ.
Ileeṣẹ naa sọ pe awọn ko di oṣiṣẹ kankan lọna lati darapọ mọ ẹgbẹ to ba wu wọn lati maa ṣe.
Dangote tun ni irọ to jinna si ootọ lọrọ ti NUPENG sọ wi pe ileeṣẹ Dangote fipa mawọn awakọ rẹ lati kọwọ bọ iwe adehun wi pe wọn o ni darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ kankan.
''Ileeṣẹ ifọpọrọbi Dangote ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu oniruuru ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria to fi mọ NUPENG.
Koda, a maa n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣiṣẹ NUPENG pẹlu gbogbo eto ti wọn maa n ṣe to fi mọ owo ti wọn maa n gba lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
A wa n fi asiko yii rọ NUPENG lati ma da asọyepọ to n lọ lọwọ eyi ti ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn osiṣẹ n ṣagbatẹru rẹ ru.
Bakan naa ni a tun rọ NUPENG lati dẹkun fifi atẹjade to le ṣakoba fun eto imupadabọ sipo ọrọ aje Naijiria ti Aarẹ Bola Tinubu n ṣe sita,'' ileeṣẹ Dangote lo sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita.
NUPENG wọgile iyanṣẹlodi wọn lọjọ Iṣẹgun
Lọjọ Iṣẹgun ọjọ ọsẹ yii ni ẹgbẹ NUPENG wọgile iyanṣẹlodi wọn ti wọn bẹrẹ lọjọ Aje.
NUPENG ṣẹwele iyanṣẹlodi naa lẹtin ti adehun waye laarinẹgbẹ baa ati ileeṣẹ ipọnpo Dangote.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita loju opo X wọn, NUPENG kede pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ipọnpo Dangote ti gba pe eyikeyi to ba wu ninu awọn dẹrẹba ọkọ epo ileeṣẹ naa lo le darapọ mọ oṣiṣẹ - igbesẹ yii ko ba awọn alaṣẹ ileeṣẹ ipọnpo Dangote lara mu.
NUPENG nfi ẹsun kan ileeṣẹ ipọnpo Dangote pe o n sọ ara rẹ di balogun eminikan lọga lẹka ipọnpo, sisan owo oṣu ti ko ya ranti f'awon oṣiṣẹ rẹ, ati gigunle awọn iwa ti lodi si ọrọ oṣiṣẹ eleyii ti wọn ni o takọ ofin oṣiṣẹ labẹle ati lagbaye.
Ileeṣẹ Dangote ko tii fesu si awọn ẹsun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pataki ẹka epo rọbi ninu eto ọrọ aje Naijiria
Ẹka ipọnpo ati afẹfẹ gaasi ni igi lẹyin ọgba fun ọrọ aje Naijiria pẹlu idiyele ojilelugba biliọnu dọla ($240b).
Awọn ile ati ileeṣẹ gbogbo lo nilo epo gẹgẹ bi ohun amuṣagbara fun ẹrọ amunawa wọn.
Bakannaa lawọn awakọ pẹlu nilo rẹ lati fi gbe ọkọ wọn ro.
Awọn awakọ ti ṣalaye ẹdun ọkan wọn lori itaporogan ti waye laarin awọn igun mejeeji yii, eyi ti wọn sọ pe o le tun wa ọwọngogo epo ati ẹkunwo ọkọ jakejado Naijiria.
Ẹwẹ, minisita fun eto ilera pẹlu ti sekilọ pe iyanṣẹlodi NUPENG yoo ni ipa to le lara awọn ileewosan kaakiri Naijiria, nitori ida ọgọrin ninu wọn lo jẹ pe ẹrọ amunawa ni wọn n lo.
Adehun ti awọn mejeeji t'ọwọ bọ laa kalẹ pe gbigba awọn oṣiṣẹ sinu ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo bẹrẹ lẹyẹ-o-ṣọka, yoo si waye fun ọsẹ meji.














