Àwọn ọkùnrin lè máa jẹ́ orúkọ bàbá ìyàwó wọn láti àkókò yìí lọ – Ilé ẹjọ pàṣẹ

Oríṣun àwòrán, OLYMPIA DE MAISMONT/AFP via Getty Images
Ile ẹjọ to ga julọ ni South Africa ti pasẹ pe awọn ọkọ le maa jẹ orukọ baba iyawo wọn lati akoko yii lọ.
Idajọ yii lo yi ofin kan to ti kọkọ sọ pe awọn ọkọ ko le maa jẹ orukọ baba iyawo wọn ṣaaju.
Tọkọ-taya meji lo gbe ẹjọ naa lọ siwaju ile ẹjọ to ga julọ ọhun lori ẹsun pe ofin akọkọ n ṣe idẹyẹ si awọn ọkunrin bi ko ṣe faye gba wọn lati maa jẹ orukọ baba iyawo wọn.
Ileeṣẹ iroyin SABC jabọ pe ṣaaju ni igbẹjọ naa, ni wọn ko ti gba Henry van der Merwe laaye lati maa jẹ orukọ baba iyawo rẹ, Jana Jordaan.
Bẹẹ ni wọn ko faye gba Andreas Nicolas Bornman lati fi orukọ baba iyawo rẹ, Jess Donnelly-Bornman si ara orukọ tirẹ.
Ohun to kan bayii ni ki ile igbimọ aṣofin orilẹede naa ṣe atunṣe si ofin to wa nilẹ ki aṣẹ tuntun naa le di mimuṣẹ.
Awọn tọkọ-taya meji ọhun sọ pe ofin to wa nilẹ tẹlẹ ti pẹ, ko si ba ode oni mu, bẹẹ ni wọn tẹ ẹtọ eeyan loju mọlẹ lati ṣe ohun to ba n fẹ.
Wọn ti kọkọ pe ẹjọ naa nile ẹjọ giga ti wọn si bori nibẹ, amọ wọn tun gbe ẹjọ ọhun lọ ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede naa fun ontẹ.
Ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan, The Free State Society of Advocates, darapọ mọ tọkọ-taya naa ninu igbẹjọ ọhun.
Wọn ni ofin ti ko faye gba ọkunrin lati maa jẹ orukọ baba iyawo rẹ n de awọn ọkunrin lọna lati ṣe ohun ti yoo mu iyawo wọn dun.
Minisita fun ọrọ abẹle, Leon Schreiber ati minisita eto idajọ, Mamoloko Kubayi sọ pe awọn ko lodi si ẹjọ ti tọkọ-taya naa pe gẹgẹ bii ohun ti iwe iroyin IOL sọ.















