Àwọn dókítà Naijiria kéde ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ márùn ún, wo iye ìgbà tí wọ́n ti daṣẹ́ sílẹ̀ lọ́dún márún ún sẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, @FMCGlobal
Ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun ni Naijiria, NARD, ti kede iyanṣẹlodi lati le jẹ ki ijọba ṣe awọn nnkan ti wọn n beere fun.
Iyanṣẹlodi onikilọ naa ti wọn yoo ṣe fun ọjọ maraun un ni ẹgbẹ NARD sọ pe yoo bẹrẹ lọjọ Ẹti ọjọ kejila oṣu Kẹsan an yii.
Akọwe agba ẹgbẹ naa, ẹka ti ilu Abuja, Agbor Affiong, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti o fi sita lonii Ọjọbọ, ọjọ kọkanla oṣu Kẹsan an.
Nibi ipade ori ayelujara ti igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ NARD ṣe lalẹ Ọjọru mọju Ọjọbọ oni ni wọn ti fẹnu ko lori igbesẹ yii.
Ṣaaju ni aarẹ ẹgbẹ NARD, Osundara Zenith, ti sọ lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii pe ẹgbẹ naa n gbero lati da iṣẹ silẹ lawọn ile iwosan ijọba kaakiri orilẹede Naijiria lati le jẹ ki ijọba wa nnka ṣe aigbaye-gbadun awọn dokita lẹnu iṣẹ ati aisi ina ọba to duro lati fi ṣiṣẹ.
Awọn nnkan mii ti ẹgbẹ awọn dokita fi kede iyanṣẹlodi ni ijawalẹ iwẹ ẹri wọn, owo ajẹmọnu to kere atawọn nnkan mii.
Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn dokita nile iwosan ijọba ẹka ilu Abuja tiẹ ti bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ meje ni ti wọn lati ọjọ Aje ọjọ kẹjọ oṣu Kẹsan an yii.
Wo iye igba tawọn dokita ti daṣẹ silẹ lọdun marun un sẹyin ni Naijiria
Awọn dokita gunle iyanṣẹlodi lọdun 2024
Ìyanṣẹ́lódì tí àwọn dókítà ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ ìyẹn Association of Resident Doctors (NARD) gùnlé lọdún 2024 ṣàkóbá fún àwọn èèyàn tó nílò ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Ọpọ̀ àwọn aláàárẹ̀ ló ń kọminú pé àwọn kò rí dókítà tọ́jú àwọn látàrí ìyanṣẹ́lódì náà.
Àwọn dókítà ní àwọn gùnlé ìyanṣẹ́lódì láti jẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ jí gìrì sí gbígba ìtúsílẹ̀ ọ̀kan lára wọn, dókítà Ganiyat Popoola, tó ti wà ní àkàtà àwọn ajínigbé láti inú oṣù Kejìlá, ọdún 2023.
Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ní ilé ìwòsàn Aminu Kano Hospital ló ti ń wá ìtọ́jú lọ sí àwọn ilé ìwòsàn aládàni.
Ọkùnrin kan tó gbé aláìsàn lọ sílé ìwòsàn náà ní àwọn dókítà kò ṣe ìtọ́jú èèyàn òun, ó ní wọ́n sọ fún òun pé àwọn ń yanṣẹ́ lódì àti pé ìṣllẹ̀ pàjáwìrì nìkan ni àwọn lè mójútó báyìí.
Ẹwẹ, Ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede Naijiria sọ nigba naa pe inu awọn ko dun lori ipinnu awọn ọmọ ẹgbẹ dokita to n gbe ninu ọgba ileewosan ṣe bẹrẹ iaynṣẹlodi ọlọjọ meje.
Ileeṣẹ eto ilera sọ pe ko tọ ọ bi awọn dokita naa ṣe yan iṣẹ lodi lai fi gbogbo akitiyan ijọba lori awọn nnkan ti wọn n fẹ ṣe.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ eto ilera, Ado Bako, fi sita, o ni ijọba ti sẹtan lati ṣamulo ofin "Ko si iṣẹ, ko sowo" fun gbogbo ọjọ ti iyanṣẹlodi naa ba fi waye.
Nnkan ti eyi tumọ si ni pe, ijọba yoo yọ owo gbogbo iye ọjọ ti awọn dokita naa ko fi ṣiṣẹ kuro lara owo oṣu wọn.
Awọn dokita gunle iyanṣẹlodi lọdun 2023
Lọdun 2023, awọn dokita ile iwosan ijọba ti a mọ si 'Resident Doctors' gunle iyanṣlodi.
Igbimọ adari ẹgbẹ awọn dokita ile iwosan agba to jẹ tijọba lorilẹede Naijiria, NARD fun ijọba apapọ Naijiria ni gbedeke ọsẹ meji bayii lati fi wa nnkan ṣe lori adehun to wa laarin awọn ati ijọba.
Lẹyin ti ijọba ko ṣe nnkan ti wọn n fẹ fun wọn ni wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi.
Kini awọn ẹbẹ ati adehun ti awọn dokita ọmọ ẹgbẹ NARD n tọka si lọdun 2023?
Lara awọn ibeere awọn dokita ileewosan agba naa ni afikun ilana owo oṣu awọn oniṣegun oyinbo ti a mọ si CONMESS pẹlu ida igba iye ti wọn n gba bayii.
Bakan naa lawọn dokita naa tun n beere fun yiya ida marundinlogun (15%) gbogbo eto iṣuna apapọ Naijiria sọtọ fun ẹka eto ilera dipo ida mẹfa din diẹ ninu ọgọrun (5.7%) to wa bayii.
Wọn tun n fẹ ki ijọba mojuto bi ohun amayedẹrun lẹka naa ṣe n fojojumọ jo ajorẹyin, pẹlu gbigba awọn oṣiṣẹ ilera si iṣẹ lati dipo ọgọọrọ awọn to ti gbe ẹrun wọn roke okun.
Bakan naa ni wọn tun n fẹ ki ijọba jami lori abadofin kan to wa ni ile aṣojuṣofin bayii eyi to fofin de awọn dokita pe wọn ko gbọdọ fi orilẹede Naijiria silẹ lọ ṣiṣẹ loke okun laijẹ pe wọn ti ṣiṣẹ fun iye gbedeke ọdun kan lorilẹede Naijiria.
NARD tun ke sijọba ko san awọn ajẹẹlẹ owo oṣu ti wọn jẹ wọn lọdun 2014, 2015, ati 2016.
Ẹgbẹ awọn dokita gunle iyanṣẹlodi alailọjọ lọdun 2021
Awọn dokita lorilẹede Naijiria kaakiri gunlẹ iyanṣelodi fun igba kẹrin lọdun 2021 lati bere fun afikun owo oṣu wọn ni ọwọ ijọba.
Awọn dokita to ba BBC sọrọ ni ijọba kuna lati risi eto igbaye gbadun awọn dokita ati ẹkọ to peye fun wọn.
Awọn dokita naa ni aibikita ijọba si ilakọja awọn dokita kaakiri n fa ifaṣẹyin fun eto ilera ni Naijiria.
Wọn ni ijọba kọ lati mu adehun ti wọn ṣe pẹlu wọn ṣe ni nkan bi osu mẹrin ṣẹyin ti wọn da wọ iyanṣelọdi duro nigba naa.
Kaakiri Naijiria, awọn dokita akẹkọmọṣẹ, Resident doctors lo poju ninu awọn dokita to n ṣiṣẹ ni Naijiria.
Ni ọpọ igba ni iyanṣelodi wọn ma n ni ipalara fun awn to nilo dokita, ti gbogbo ileewosan yoo si da paro-paro.
Ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria wa rọ tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria ti iyanṣelodi naa fa ipalara fun wọn.
Amọ wọn ni ijọba gbọdọ mu ileri wọn ṣe lori gbogbo adehun ti wọn ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn dokita kaakiri orilẹede Naijiria.
Awọn dokita lawọn ile iwosan ijọba ni Naijiria da iṣẹ silẹ lọdun 2020
Awọn dọkita to n ṣiṣẹ nile ẹkọṣẹ iṣegun ni Naijiria sọ pe iya n jẹ wọn lo jẹ ki wọn gunle iyanṣẹlodi.
Aarẹ awọn dokita naa ni ẹka ile iwosan ijọba apapọ, FMC, to wa ni Abeokuta, Adekunle Akeem Jimoh sọ fun BBC pe ijọba apapọ ko ṣe awọn ohun to yẹ ni ṣiṣe lo jẹ ki wọn daṣẹ silẹ.
O ni "Bi a ṣe n lọ si ibiṣẹ, ko si awọn ohun ti a nilo lati fi dabo bo ara wa; bi ibomu atawọn nnkan mii to yẹ ki ijọba pese, ijọba kọ lati pese rẹ."
Jimoh ni lati ọdun 2014 ni ẹgbẹ awọn dokita naa ti n bere awọn ẹtọ wọn lọwọ ijọba apapọ ṣugbọn ijọba ko kọbi ara si awọn ibere naa.
Bo tilẹ jẹ pe wọn wa ni idaṣẹṣilẹ, Jimoh sọ pe awọn dokita ọhun ṣi n ṣetọju awọn to ni arun Covid-19.















