Ìdí rèé tí ilé ẹjọ́ ṣe kọ láti gba béèlì afurasí márùn-ún tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì Owo èyí tó gbẹ̀mí èèyàn ogójì

Oríṣun àwòrán, Olumide Owaduge/BBC
Ile ẹjọ giga to n gbọ ẹsun igbesunmọmi awọn afurasi marun un to kọlu ile ijọsin kan niluu Owo, nipinlẹ Ondo lọdun 2022 ti kọ lati gba beeli awọn afurasi naa.
Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ ọdun yii ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ko awọn afurasi naa lọ ile ẹjọ fun ipa ti wọn ko ninu ifẹmiṣofo to waye ninu ijọ St. Francis Catholic Church, to wa ladugbo Owaluwa, niluu Owo.
Awọn marun un ọhun — Idris Abdulmalik Omeiza, Al Qasim Idris, Jamiu Abdulmalik, Abdulhaleem Idris, ati Momoh Otuho Abubakar — n jẹjọ niwaju adajọ Emeka Nwite lori iku ogoji eeyan to waye nibẹ, to fi mọ awọn to le ni ọgọrun to farapa.
Iroyin ni ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Al-Shabaab ni awọn afurasi ọhun.
Lasiko igbẹjọ naa ni adajọ Nwite da ẹbẹ wọn fun beeli nu lori ẹsun ti wọn n jẹjọ rẹ latari bi ẹsun naa ṣe wuwo to.
Adajọ naa ni awọn afurasi ọhun le lọ maa dunkoko mọ awọn ẹlẹri ti yoo jẹri tako wọn latari bi ẹgbẹ agbesunmọmi ti wọn wa ṣe buru to.
Bakan naa ni ile ẹjọ ọhun sọ pe oun ko le fun wọn ni beeli nitori ẹri ti ajọ DSS gbe ka iwaju oun nipa wọn ko kere.
Agbẹjọro ajọ DSS, Ọmọwe Callistus Eze sọ niwaju ile ẹjọ naa pe o ṣeeṣe ki awọn afurasi ọhun na papa bora ti ile ẹjọ ba ṣeṣi fun wọn ni beeli latari bi ẹsun naa ṣe wuwo to.

Oríṣun àwòrán, Channels TV
Adajọ ni agbẹjọro awọn afurasri ko sọrọ tako ọrọ ti agbẹjọro DSS sọ nipa awọn onibara rẹ pe wọn le salọ latari bi ẹsun ti wọn n jẹjọ rẹ ṣe wuwo to.
Ti ẹ ko ba gbegbe, ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ni awọn agbegbọn naa yabo ile ijọsin ọhun niluu Owo ti wọn si gbẹmi eeyan to le ni ogoji.
Gomina ipinlẹ Ondo lọdun naa lọhun, Rotimi 'Aketi' Akeredolu sọ pe niṣe lawọn eeyan naa mọọmọ wa da ilu bibi oun ru ti wọn si wa fẹmi ṣofo nibẹ.
O le ni ọgọrun eeyan to farapa nibi iṣẹlẹ naa.
Lara awọn to farapa nibẹ ni arabinrin Atah Folayemi Magret to pada ẹsẹ rẹ mejeji ati oju kan.
Ẹkunrẹrẹ iroyin nipa ikọlu to waye ni sọọsi Owo eyi ti awọn afurasi naa n jẹjọ le lori
Ọjọ Kẹrin osu Kẹfa ọdun 2022 ni awọn agbebọn kan ya wọ inu sọọsi St Francis nilu Owo lasiko ti ijọsin n lọ lọwọ lọjọ Aiku naa.
Wọn kọlu awọn olujọsin, ti eeyan ogoji si jade laye nigba ti aimọye fara pa yanna yanna.
Iyalẹnu gba a ati nnkan ojiji ni ikọlu yii jẹ, paapaa nitori pe iroyin nipa rogbodiyan kii ṣaba wa lati ilu Owo bi ti awọn ilu mii ni Naijiria.
Lootọ si ni ikọlu ti ma n waye si awọn ile ijọsin ọmọlẹyin Kristi ṣaaju, eyi to jẹ ara ọna ti ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram n lo. Ipakupa to waye ni Owo ṣi n jẹ kayeefi fun ọpọ eeyan.
Ijọba Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari, gbagbọ pe, ikọ agbesunmọmi Islamic State lo wa nidii ikọlu ọhun, amọ awọn ara ilu ko gba bẹẹ, to fi mọ Gomina Rotimi Akeredolu.
Oṣu diẹ lẹyin ikọlu yii ni ijọba ipinlẹ Ondo kede pe ọwọ tẹ awọn afurasi to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa. Ṣugbọn lati igba naa, awọn ara ilu Owo sọ pe awọn ko gbọ ohunkohun nipa wọn mọ.
Ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 bakan naa ni iroyin tẹ BBC lọwọ pe ọwọ ileesẹ ologun ti tẹ awọn agbebọn ti kọlu sọọsi kan ni Owo.
Olori awọn osisẹ alaabo , Ọgagun Lucky Irabor lo sisọ loju isẹlẹ naa lasiko to n ṣe ipade pẹlu awọn akọroyin.
Irabor ni kii se igi awọn ologun nikan lo da igbo se nidi ọrọ naa amọ awọn se aseyọri naa nifọwọkọwọ pẹlu awọn ileesẹ agbofinro yoku.
Gomina Rotimi Akeredolu to n dari ipinlẹ Ondo nigba naa, amọ to ti di oloogbe bayii, paapaa sọ pe lootọ ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn agbebọn to wa kọlu sọọsi Owo.
Akeredolu ni bakan naa ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ baba onile ti awọn agbebọn naa gbe ile rẹ saaju ikọlu naa.
O ni awọn agbofinro ko fi epo bọ iyọ lati se awari awọn agbebọn to sisẹ laabi nilu Owo naa.















