Aráàlú tó ń ṣe ìwọ́de tako àjẹbánu ìjọba sọ iná sílé aṣòfin, èèyàn 21 kú

Ile igbimọ aṣofin Nepal lẹyin ti araalu dana sun tan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Lati ọjọ Aje ni awọn eeyan naa ti bẹrẹ iwọde ọhun ki wọn to yabo ile igbimọ aṣofin naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn araalu ti sọ ina sile igbimọ aṣofin to wa niluu Kathmandu, to jẹ olu ilu orilẹede Nepal.

Iṣẹlẹ yii lo waye lasiko ifẹhonuhan ti awọn eeyan orilẹede naa ṣe tako iwa ajẹbanu ti wọn fi kan awọn olori wọn.

Lati ọjọ Aje ni awọn eeyan naa ti bẹrẹ iwọde ọhun ki wọn to yabo ile igbimọ aṣofin naa.

Yatọ si ile aṣofin yii, araalu tun ya bo Singha Durbar to jẹ ile nla ti ọpọ ọọfisi ijọba ilẹ naa wa.

Niluu Kathmandu, wọn ti gbe papakọ ofurufu Tribhuvan tipa bayii latari iwọde ọhun.

Iroyin ni pupọ ninu awọn adari orilẹede naa lo ti salọ si baraki awọn ọmọ ogun bayii lati lọ fi ori wọn pamọ sibẹ.

Eeyan mọkandinlogun jade laye, olootu ijọba atawọn minisita fi ipo silẹ

Ẹwẹ, olootu ijọba Sharma Oli ti kọwe fi ipo rẹ silẹ bayii lẹyin ifẹhonuhan naa to ti mu ẹmi eeyan mọkandinlogun lọ.

Nigba to n sọrọ lori eredi to ṣe fi ipo naa silẹ, o ni oun ṣe bẹẹ lati la ọna fun atunto ofin ti yoo yanju rogbodiyan to wa nilẹ.

Yatọ si olootu ijọba yii, minisita fun ọrọ omi Pradeep Yadav , minisita fun ọrọ agbẹ, Ram Nath Adhikari, ati minisita fun ọrọ ile gbigbe, Ramesh Lekhak naa ti fi ipi wọn silẹ.

Ki lo ṣokunfa ifẹhonuhan naa?

Ifẹhonuhan ọhun bẹrẹ lori ayelujara lẹyin ti araalu sọ pe o to gẹ si bi awọn oloṣelu atawọn mọlẹbi wọn ṣe n gbadun ti iya si n jẹ araalu.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ bẹrẹ si n sọrọ lori ayelujara lati tako aye fa mi lete ki n tutọ ti awọn ọmọ awọn oloṣelu n gbe pẹlu ami "nepo kid".

Amọ ọrọ ti awọn araalu n sọ lori ayelujara naa ko dun mọ ijọba ninu, eyii to mu ki wọn gbẹsẹle awọn oju opo ikansiraẹni kan lori ayelujara.

Lara awọn oju opo ti wọn gbẹsẹle ni Facebook ti awọn eeyan ti n sọrọ ati YouTube, ṣugbọn ijọba ko mọ pe oun ti jale agbọn pẹlu igbesẹ naa.

Ko pẹ lẹyin eyii ni wọn tu si igboro ti wọn sin n sọ pe asiko ti to fun awọn adari wọn lati fi ipo silẹ ki awọn mii le gbajọba.

Ọlọpaa yin gaasi tajutaju si awọn oluwọde naa lati tu wọn ka amọ gbogbo igbiyanju wọn lo ja si pabo.

Amọ lẹyin ti iku eeyan mọkandinlogun waye ni ijọba gbẹsẹ kuro lori awọn oju opo naa amọ ọrọ ti bọ sori nitori awọn ọdọ ti tu jade.