"Ọdẹ ìbílẹ̀ ni bàbá, ìyá àti ọkọ mi, Fijilańté tó ṣọ́ Aláàfin Adeyemi àti Owoade ni mí"

Àkọlé fídíò, "Ọdẹ ìbílẹ̀ ni bàbá, ìyá àti ọkọ mi, Fijilańté tó ṣọ́ Aláàfin Adeyemi àti Owoade ni mí"
"Ọdẹ ìbílẹ̀ ni bàbá, ìyá àti ọkọ mi, Fijilańté tó ṣọ́ Aláàfin Adeyemi àti Owoade ni mí"

Awọn eeyan kan ni ko si ohun ti ọkunrin le se, ti obinrin ko le e se.

Nilẹ Yoruba, awọn ọkunrin nikan la mọ mọ isẹ ọdẹ sise amọ iyalẹnu nla lo jẹ pe obinrin kan wa to yan isẹ ọdẹ sise laayo.

Lati kekere si ni obinrin naa, to ti di iya agbalagba bayii ti bẹrẹ isẹ ọdẹ sise.

Ninu irinajo BBC News Yoruba si ọdọ Alaafin Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade, si ni a ti se alabapade mama agba yii, Marian Alarape Iyanuore, to jẹ ọdẹ ibilẹ.

Koda, mama ọdẹ naa, lo maa n wọ Khaki gẹgẹ bii Ologun, ti ẹnu si maa n ya ọpọ eeyan pe se eegun si wa lara iya yii lati sisẹ ọdẹ.

Tun wẹ, Mama naa tun jẹ ọmọ ẹgbẹ fijilante to n lo ilana ibilẹ lati pese aabo to peye, paapaa ni aafin Oyo.

BBC News Yoruba ba Mama Marian Alarape Iyanuore takurọsọ, to si salaye nipa ohun to gbe de idi isẹ naa, awọn ipenija to ti la kọja ati awọn aseyọri rẹ.

Bakan naa, Mama fijilante yii tun sọrọ lori bo se rọrun si lati wa lara awọn ọdẹ ibilẹ to n pese eto aabo fun Alaafin atawọn mọlẹbi rẹ.

Mama Marian Alarape Iyanuore ree to wọ asọ ologun alawọ ewe, o joko, kọ ẹyin si ile kan, o si wa lori aga kan, to si gbe ibọn sakabula lọwọ.
Àkọlé àwòrán, Mama Marian Alarape Iyanuore, ọdẹ ibilẹ ni aafin Oyo

"Mo jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ OPC tẹ́lẹ̀, kí ń tó lọ ṣe ọdẹ Asọ̀lúdẹ̀rọ̀, tí mo wá padà di Fijilańté"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Mama ọdẹ Iyanuore ni lati kekere ni oun ti bẹrẹ si ni yinbọn nitori ọdẹ ibilẹ ni baba oun.

"Mo darapọ mọ isẹ fijilante gẹgẹ bi ọdẹ obinrin amọ inu ẹgbẹ Oodua, OPC ni mo kọkọkọ dara pọ mọ.

Lẹyin ti mo kuro ninu ẹgbẹ OPC tan, ni mo wa dara pọ mọ ẹgbẹ ọdẹ Asọludẹrọ.

Mo beere lọwọ ẹgbẹ ọdẹ naa pe se wọn yoo maa fun wa ni owo osu amọ wọn sọ pe ko si owo osu nitori pe a maa sisẹ sin ilu ni.

Idi ree ti mo se kuro ninu ẹgbẹ ọdẹ Sọludẹrọ, ti mo si dara pọ mọ ẹgbẹ fijilante.

Mo tun wa beere nibẹ pe se ninu ẹgbẹ fijilante, se wọn yoo maa fun wa lowo ni abi a maa tun sin ilu ni, ti a si maa na owo ara wa da sita?

Wọn wa dahun pe a maa sin ilu sugbọn o le jẹ pe owo ti wọn yoo maa fun wa ko ni to nnkan.

Mo ni eyi si daa diẹ, maa maa ba wọn lọ baun, bi mo se pada wọnu ẹgbẹ Fijilante nu u."

Mama Marian Alarape Iyanuore ree to wọ asọ ologun alawọ ewe, o kọ ẹyin si ile kan, to si duro, na ibọn sakabula to wa lọwọ rẹ soke bii pe o fẹ yin ibọn.
Àkọlé àwòrán, Mama Marian Alarape Iyanuore, ọdẹ ibilẹ ni aafin Oyo

"Mo koju ọpọ ipenija nidi isẹ ọdẹ, bi ka lẹ mọlẹ ninu igbo, ẹru kii ba mi tori aya nini ni gbogbo nnkan"

Nigba to n salaye bo se de idi isẹ akọni yii ati awọn ọpọ ipenija to ti foju wina rẹ, Mama ọdẹ Alarape Iyanuore, salaye pe:

"Lati kekere titi de ọlọmọge ni mo ti maa n yinbọn nitori ọdẹ ibilẹ ni baba mi.

O ti pe ọdun mọkanlelogun ti mo ti bẹrẹ isẹ naa, ti mo si koju ọpọ ipenija nitori pe ko si isẹ ti ko ni isoro tiẹ, Ọlọrun nikan lo maa n ko eeyan yọ.

Mo ti foju wina ọpọ ipenija bẹrẹ lati inu ẹgbẹ OPC, a lọ gọ mọ inu igbo, a lẹ mọlẹ, lati igba naa la ti n ba irinajo yii bọ.

Ko si ipenija to le ka mi laya nitori aya nini ni nnkan, ko si si ibi ti wọn le sọ pe ka lọ, ti n ko ni lọ."

Mama Marian Alarape Iyanuore ree to wọ asọ ologun alawọ ewe, gbe apo alawọ ewe kan kọ ejika rẹ, o tun so asọ otutu Súẹ́tà rẹ mọ inu, o fi igo soju, to si duro, o n rẹrin. Ori papa isere kan lo wa eyi ti ọpọ eeyan pọ si.
Àkọlé àwòrán, Mama Marian Alarape Iyanuore, ọdẹ ibilẹ ni aafin Oyo

"Ọdẹ ni Baba, iya ati ọkọ mi, mo ti kọle, mo si ti gbe nnkan rere mii se nidi isẹ ọdẹ"

Bakan naa ni Mama Iyanuore fikun pe ọdẹ ibilẹ tẹlẹ ni ọkọ oun, awọn si jọ n fi ọwọ wẹ ọwọ bii ọdẹ ati ọdẹ ni.

"Bi emi ati ọkọ mi se jọ n ba a lọ ree, ti a fi de ibi ti a de yii.

Awọn mọlẹbi mi fẹran isẹ ti mo n se tori ọdẹ ni baba mi, koda, iya to bi mi, ọdẹ isẹmbaye ni oun naa.

Mo ti gbe awọn nnkan rere se nidi isẹ ọdẹ ibilẹ yii, mo ti kọle ninu rẹ, mo si tun ni alaafia nibẹ.

Awọn ọmọ mi ko se aarẹ, emi naa ko se aarẹ, mọlẹbi mi kankan ko pa mi lẹkun."

Mama Marian Alarape Iyanuore ree to wọ asọ ologun alawọ ewe, o de fila alawọ ewe pẹlu, o gbe apo alawọ ewe kọ ejika rẹ, o kọ ẹyin si ile kan, to si joko lori aga alawọ buluu, o mu ọta ibọn lọwọ
Àkọlé àwòrán, Mama Marian Alarape Iyanuore, ọdẹ ibilẹ ni aafin Oyo

"Mo ba Alaafin Adeyemi sisẹ, mo tun n ba Ọba Owoade sisẹ, eeyan daadaa ni awọn mejeeji"

Mama ọdẹ fijilante, Marian Iyanuore, ninu ọrọ rẹ, wa mẹnuba ajọsepọ to wa laarin rẹ ati Alaafin ana, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta.

"Se ẹ ri Kabiyesi ana, Baba daadaa ni, ki Ọlọrun fi ọrun kẹ wọn.

Baba gbinyanju fun wa tori ti a ko ba fẹ ri owo gba, wọn yoo ni ka ni suuru, ti wọn yoo si fun wa ni owo lọwọ ara wọn.

Bakan naa, Alaafin to wa lori itẹ bayii, Ọba Abimbola Owoade, ọwọ Alaafin ana naa ni awọn naa mu.

Nigba ti a lọ ba wọn pe a ko ri owo gba, baba ni a ri owo, bi baba se n yanju ọrọ wa nu u.

Amọran mi sawọn ọdọ ọmọbinrin ni pe ki wọn dara pọ mọ awa ọdẹ Fijilante.

Ki wọn fi tọkantakọn sisẹ yii gẹgẹ bi a ti n se fun Alaafin.

Ko yẹ ki obinrin maa duro woju ọkunrin nitori ẹni to ba n woju ọkunrin, ebi yoo pa ku."