Ebenezer Obey fọnmú, figbe ta, bí ariwo ikú rẹ̀ ṣe tún gbalẹ̀ tan tan tan

Aworan Ebenezer Obey

Oríṣun àwòrán, Instagram/ebenezerobey

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Se ni ariwo tun sọ lori ayelujara nigba ti iroyin kan jade pe gbajugbaja akọrin juju nni, Ebenezer Obey ti jade laye.

Bakan naa ni iroyin ọhun fikun pe agba akọrin naa ti rọ lapa, to si tun rọ lẹsẹ, ko to jade laye.

Bi o tilẹ jẹ pe iroyin naa ba awọn eeyan lojiji, to si n se wọn ni haa-hii, ti ọpọ eeyan si n sedaro akọni olorin naa to lọ.

Amọ ẹni ti ọrọ kan, baba Ebenezer Obey, tun ti jade sita pe oun ko ku, bẹẹ ni oun ko rọ lapa, tabi rọ lẹsẹ gẹgẹ bii iroyin kan ṣe n gbe kiri.

Ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara, Obey pẹlu ọmọ rẹ ọkunrin meji, Larry Obey ati Bisọọbu Folarin Obey, ṣapejuwe iroyin naa gẹgẹ bii ẹlẹjẹ ti ko fẹsẹ mulẹ rara.

"Mo ri fidio to kede iku mi lẹẹkan si, to tun ni ọta mi ti rọlaparọlẹsẹ, ero awọn ọta ni, ko si ni wa si imusẹ"

Ebenezer Obey ni alaafia ni oun wa, to si rọ awọn kọlọransi ẹda lati dẹkun pinpin iroyin ẹlẹjẹ pe oun ti ku kaakiri ilu.

O ṣalaye pe oun ṣẹsẹ lọ si ilu London fun itọju ara oun ni.

"Mo gbera kuro ninu Eko wa si ilu London lonii.

"Mo ri fidio to kede iku mi lẹẹkan si, to tun ni ọta mi ti rọlaparọlẹsẹ,

"Koda wọn tun gbe posi pẹlu ọpọ aworan, gbogbo nnkan ti wọn sọ pata lo jẹ irọ to jina si otitọ.

"Ero awọn ọta ni, ti mo si mọ pe gbogbo ero wọn ko ni wa si imusẹ.

"Ọlọrun mi wa ni ipo agbara. Mo n tun sọ, Ọlọrun mi wa ni ipo agbara. Mo mọ pe gbogbo ipinnu ọta lori aye mi ko ni wa si imusẹ," o fikun.

Obey tẹnumọ pe oun wa laaye, ti ko si nkankan to mu oun."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ó ti ju ìgbà méjìlá lọ, tí wọ́n ti kéde ikú mi – Ebenezer Obey

Eyi ki n ṣe igba akọkọ ti iroyin nipa Iku Ebenezer Obey yoo jade sita lori ayelujara.

Ni ọdun 2025 ninu oṣu kẹrin yii ni agba ọjẹ olorin Juju ọhun ti ṣalaye pe o ti le ni igba mejila ti wọn ti kede iku oun.

Lọdun 2020, Aṣoju ẹgbẹ orin baba Ebenezer Obey, Tunji Odunbaku ba BBC News Yoruba sọrọ nigba ti iroyin n gbe kiri pe gbajugbaja olorin naa ti dagbere faye.

Odunbaku sọ fun BBC pe ko si otitọ ninu iroyin naa ni ọdun 2020.

Alagba Ebenezer Obey sọ pe, " Mi o le gbagbe ọlọkan-o-jọkan ailera ti mo koju laye mi, eyi to mu mi ṣe ọpọ iṣẹ abẹ.

" Mo dupẹ f'Ọlọrun to mu mi bori awọn akoko iṣoro naa. Emi ti wọn ti kede iku mi kọja igba mejila, sibẹ, Ọlọrun da mi si"

"Idi niyi ti mo fi n ṣe aye mi lọ pẹlu ọkan ọpẹ si Ọlọrun, pẹlu gbogbo idojukọ ailera ti mo ni, mo ṣi n lọ si ọna jinjin ati itosi lati kọrin lẹni ọdun mẹtalelọgọrin. Oluwa nikan lo le ṣeyi, mo si fi gbogbo ogo fun un."

Ta ni Ebenezer Obey?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ilu Idogo, nipinlẹ Ogun ni wọn ti bi Oloye Remilekun Olasupo Aremu Fabiyi, lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ọdun 1942.

O kọrin Juju fun ọdun mẹrindinlaadọrin ko too gbọ ohun Oluwa to si di ajihinrere. Baba Miliki lawọn eeyan mọ Obey si ni gbogbo asiko ọdun 1950 sisalẹ.

Ọdun 1964 lo da ẹgbẹ orin rẹ to pe ni International Brothers silẹ.

Awọn orin ọlọkan-o-jọkan to kun fun arojinlẹ ati miliki ni aye mọ Ebenezer Obey mọ.

Eyi lo ṣe jẹ kayeefi fun awọn onifaaji to n fẹran rẹ nigba ti wọn gbọ pe Baba Commander bi wọn tun ṣe maa n pe e ko kọrin aye mọ.

Ni awon akoko ti Obey n kọrin onimiliki naa ni awọn kan n gbe e kiri pe o gbe lukudi mi, iyẹn oriṣi oogun owo kan to maa n mu ikun tobi.

Ebenezer Obey fi kọrin nigba naa pe '' Baabu Lukudi''.

O loun ko mu lukudi kankan, bẹẹ ni oun ko gbe oogun oloro lọ siluu oyinbo bawọn ayẹ ṣe n gbe e kiri nigba naa.

Obey padanu iyawo rẹ, Ajinhinrere Juliana Obey-Fabiyi, lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2011.

Bakan naa ni ọmọ agba ọjẹ olorin yii torukọ rẹ n jẹ Olayinka Olalekan, jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọta ni 2022.

Gẹgẹ bi Oloye Ebenezer Obey Fabiyi funra rẹ ṣe wi, oriṣiiriṣii ailera lo ti koju, ṣugbọn Ọlọrun ninu aanu rẹ da ẹmi rẹ si, lati tun ri ọjọọbi ọdun kẹtalelọgọrin.

Díẹ̀ lára orin tí Olóyè Ebenezer Obey kọ

Lara awọn orin ti Baba Commander kọ nigba to wa ni Sango ode ni:

Aimasiko

Edumare Soro Mi Dayo

Iba Lo Ye Ka se

Ota Mi Dehin Lehin Mi

Oro Oluwa Ede

Board Members

Juju jubilation

Ebenezer Obey in London ati bẹẹ bẹe lọ.