Kìí ṣe pé mo yí orin padà sí ti Ọlọ́run, ìyàtọ́ orin mi ti tẹ́lẹ̀ sí ìpè "Evangelist" ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà rèé - Ebenezer Obey
"Nigba ti iya mi o fẹ ki n maa lu ilu to ni oun fẹ ki n jẹ dokita tabi Agbẹjọro, o fi ede ilu wa sọ ọ pe awọn alagbe lo n lu ilu".
Gbajugbaja olorin juju tẹlẹ to di ilumọọka kaakiri agbaye, Ebenezer Obey Fabiyi ba BBC Yoruba sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo yii nipa bi o ṣe bẹrẹ orin kikọ.
O tun mẹnu ba irufẹ orin to maa n kọ latilẹ to si ṣalaye lori bi awọn eeyan ṣe ro pe o ti yi orin rẹ pada nibayii to ti di Ajihinrere ninu ẹsin Kristẹni.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Olorin naa sọ bi o ṣe di olokiki lati oju agbo lasiko to n kọ orin kan lọwọ.
Bakan naa o ni oun mọ pe orin ni Ọlọrun ran oun wa sile aye lati wa kọ.
"Kii ṣe è mo yi orin pada si ti Ọlọrun... Awọn orin ti mo ti n kọ naa lati ibẹrẹ, awọn orin ọrọ adura, orin to mu ọgbọn ati laakaye dani naa ni mo n kọ tẹlẹ.
"Iyatọ wa ninu keeyan yi orin pada ati keeyan ni ipe"

Ebenezer Obey ṣalaye pe asiko ti ipè de fun oun tumọ si wipe o di atunbi ninu Jesu Kristi to si bẹrẹ si ni sin Ọlọrun daadaa.
"Ọlọrun pe mi lati jẹ Ajihinrere, nigba to tun pe mi tan a n ṣiṣẹ ipe yẹn lati maa jihinrere Jesu Kristi a si tun pa orin naa pọ mọ ọrọ Ọlọrun taa si n ṣe e titi di asiko yii".
O ni ohun ti Ọlọrun yan oun mọ gan ni orin kikọ ti oun si rii dajudaju.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lara awọn orin ti Obey fi gbajumọ niwọnyi:
Aimasiko
Edumare Soro Mi Dayo
Iba Lo Ye Kase
Ota Mi Dehin Lehin Mi
Oro Oluwa Ede
Board Members
Juju jubilation
Ebenezer Obey in London

Oríṣun àwòrán, OTHERS







