Òkú ẹni ọdún 86 pòórá ní “mortuary” bí mọ̀lẹ́bí ṣe wá gbèé fún ìsìnkú, wàhálà bẹ́ sílẹ̀!

Mọṣuari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Awọn mọlẹbi oku ti lọ yẹ ẹ wo ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, ti wọn si rii pe digbi ni oku si wa ninu yinyin amọ ...”

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi panpẹ ofin mu oṣiṣẹ ile igbokupamọ si meji kan latari bi oku ẹni dun mẹrindinlaadọrun kan, Joel Omiran ṣe dede poora ni ile iwosan Sacred Heart to wa lagbegbe Lantoro niluu Abeokuta.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ naa jẹ akọwe owo, ekeji si jẹ ẹni to n tun pa omi ṣe, awọn mejeji yii ni ọlọpaa ti gbe janto lọ si agọ wọn.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ ọ oloogbe naa ku ni oṣu kan sẹyin nileewosan kan lẹyin ti wọn gbe e digba digba lọ sibẹ fun itọju.

Lẹyin eyi ni wọn gbe e lọ si ile igbokupamọ si ti iṣẹlẹ laabi ti pada ṣẹlẹ yii ṣaaju ọjọ isinku.

Bawo ni oku naa ṣe poora?

Mọṣuari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi awọn iroyin kan ṣe sọ, awọn ọmọ oloku ti lọ wo oku ọhun ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ti wọn si rii pe digbi ni oloogbe ṣi wa ninu yinyin.

Ẹni to ṣalaye fun awọn oniroyin abẹle naa sọ pe awọn ọmọ oloku pada fi to awọn ileewosan naa leti pe awọn n bọ wa gbe oku fun eto isinku.

Wahala ba bẹ silẹ ni ọjọ ti wọn de lẹyin ti wọn ti san gbogbo owo to yẹ ki wọn san tan to ku ki wọn lọ gbe oku lo ba di pe wọn o ri i nibẹ.

“Gbogbo akitiyan lati rii pe wọn ri oku gba kuro nibẹ lọjọ naa ja si pabo”.

Ki ni Ọlọpaa sọ?

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbola Oyeyemi to fi aridaju iṣẹlẹ naa hande sọ fun awọn oniroyin pe:

“Lootọ ni a gbọ nipa iṣẹlẹ pe oku ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlaadọrun, Joel Omiran dede poora ni ileewosan Sacred Heart ni Abeokuta.

“A ti bẹrẹ iwadii, ẹka ọtẹlẹmuyẹ wa to wa ni agbegbe Eleweran si ti gun le iṣẹ lori ẹsun naa”.

Oyeyemi ni awọn ti mu afurasi mẹrin eeyan meji to jẹ oṣiṣẹ mọṣuari, ayẹwe owo wo kan ati ẹni to n tun ọpa omi ṣe (Plumber).

“Ileeṣẹ ọlọpaa mu “plumber” naa si atimọle tori pe a gbọ wipe ọjọ diẹ ṣaaju iṣẹlẹ naa, o ba awọn oṣiṣẹ mọṣuari ọhun ja ilẹkun ibẹ nigba ti kọkọrọ sọnu. A fi panpẹ mu u l’Ọjọbọ”.