Ó ṣeéṣe kí a máa ti afárá Third Mainland ní òpin ọ̀sẹ̀ fún àtúnṣe – Fashola

Oríṣun àwòrán, @OnwardNG
Minisita fun oͅroͅ isͅeͅ ati ile gbigbe, Babatunde Fashola ti soͅ pe o ṣeeṣe ki woͅn ti afara Third Mainland ni ipinleͅ Eko ni opin oͅseͅ fun atunse.
Fashola lo soͅ oͅroͅ yii lasiko to n fi oͅroͅ jomitoro oͅroͅ pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels.
O ni ijoͅba ti buwoͅlu bilioͅnu meͅfa o le fun atunse afara ọhun, eyii to to iwoͅn kilomita moͅkanla.
Fashola to fi igba kan jeͅ gomina ipinleͅ Eko ri ni atunṣe naa yoo mu ayipada de ba awoͅn ibi to ti n bajeͅ lori afara naa.
‘’A o gbiyanju lati sa ipa wa lati maṣe jeͅ ki atunṣe afara Third Mainland naa fa inira fun awoͅn ara ilu nitori igbe woͅn naa ni a gboͅ pe ki a ṣe atunṣe afara naa ni a ṣe gbe igbeseͅ beͅeͅ.’’
‘’Ti a ba feͅ ti afara naa, ko ni jeͅ fun oͅjoͅ gboͅoͅroͅ, o ṣeeṣe ko jeͅ opin oͅseͅ nikan."
"Amoͅ mi o ni si ni ipo nigba naa, nitori naa eͅni to ba wa nibeͅ ni yoo maa ba iṣẹ ọhun lọ.’’
Bakan naa lo fikun pe kii se pe afara naa ti bajeͅ patapata, o ni o sͅi wa ni ipo to dara, ti awoͅn yoo si sa ipa woͅn lati se ni kiakia.
Bíborí tí Obi borí ní ìpínlẹ̀ Eko bá wa lójijì, ṣùgbọ́n... – Raji Fashola

Oríṣun àwòrán, other
Minisita fun akanṣe iṣẹ ati idagbasoke ile gbigbe ni Naijiria, Amofin agba Babatunde Raji Fashọla ti boju wẹyin wo eto idibo apapọ to kọju lati jẹwọ wipe ọpọlọpọ iyalẹnu lo waye nibẹ paapaa fun ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣe ijọba ni Naijiria.
Lara awọn iyalẹnu to tọka si ni bi oludije fun ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ṣe bori Tinubu ni ipinlẹ Eko.
Igbagbọ ọpọ ṣaaju idibo aarẹ ni pe Tinubu ni baba isalẹ nipinlẹ Eko, amọ nigba ti esi ibo yoo jade, ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹdẹgbẹta ati meji o le ọtalerinwo o din mẹfa (582, 454) ibo ni Obi ni ti Tinubu si ni ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹdẹgbẹta o din mẹjọ ati ẹgbẹta o le mẹfa (572, 606) ibo.
Bi o tilẹ jẹ wi pe Tinubu lo pada bori ibo aarẹ ni Naijiria, Amofin Fashọla sọ pe ohun to ṣẹlẹ l’Eko lasiko idibo naa ba awọn lojiji.
Fashola to kopa lori eto ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan ni Naijiria, Channels Television lalẹ ọjọ Aiku ṣalaye pe lootọ lawọn ṣe eto ibo ayẹwo ṣaaju idibo apapọ naa lati lee ni afojusun bi nnkan yoo ṣe ri lasiko idibo naa.
O ni ẹgbẹ oṣelu APC mọ awọn ipinlẹ ti o ti lagbara nibẹ to si tẹmpẹlẹ iṣẹ mọ.
Amọṣa, gomina ipinlẹ Eko nigbakan ri naa ṣalaye pe awọn agbegbe kan wa ti esi to jade nibẹ ba awọn lojiji.
“Lawọn ipinlẹ kan, iyalẹnu ṣẹlẹ lawọn ibi kan bii Eko nitori pe awọn alatako ko awọn oludibo wọn sita lọpọ yanturu.
Nigba ti wọn bi i boya ẹgbẹ oṣelu LP ba wọn lojiji pẹlu bo ṣe bori nibẹ, Fashọla sọ pe "lootọ, lainijiyan ni o ba wa lojiji. Wọn ko awọn oludibo wọn sita, awa naa si ko awọn oludibo tiwa sita nigba ti idibo sipo gomina waye.”












