Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ẹ̀ka ìrìnnà òfúrufú bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì, FAAN ní k'áwọn arìnrìnàjò wá ọgbọ́n dá sí ìrìn wọn

Awọn oṣiṣẹ ẹka ofurufu nibi iyaṣẹlodi wọn

Awọn oṣiṣẹ ẹka irinna ofurufu ni Eko di gbogbo ọna to wọ papakọ ofurufu Murtala Mohammed nilu Eko lọjọ Aje gẹgẹ bi ara igbesẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ meji ti wọn n gunle.

Awọn oṣiṣẹ ẹka irinna ofurufu lorilẹede Naijiria bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ meji naa lati fi fa ijọba leti lori awọn ibeere ti wọn gbe siwaju ijọba orilẹede Naijiria.

Lara awọn ohun ti wọn n beere lọwọ ijọba ni sisan ajẹẹlẹ owo oṣu to kere ju fun oṣiṣẹ eyi ti wọn pe ni ‘minimum wage’ ati ṣiṣẹwe le ipinnu wiwo ọfiisi awọn oṣiṣẹ to wa nilu Eko, aisi igbe aye to gbadun fun awọn oṣiṣẹ ẹka naa atawọn ibeere miran

Gbogbo ọna to wọ papakọ ofurufu to wa nilu Eko ni wọn di ti wọn si wa ọkọ wọn di gbogbo ọna naa eyi si fa ọpọ sunkẹrẹfakẹrẹ lagbegbe Ikẹja.

Ẹ tete wa ọgbọn da si irinajo ofurufu yoowu ti ẹ ba fẹ rin - FAAN

Awọn oṣiṣẹ ẹka ofurufu nibi iyaṣẹlodi wọn

Nibayii awọn alaṣẹ ajọ to n ṣe amojuto irinna ofurufu lorilẹede Naijiria, FAAN ẹka ti papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe nilu Abuja ti gba awọn arinrinajo ofurufu lamọran pe ki wọn tete wa ọna miran fun irinajo wọn ti irufẹ irinajo bẹẹ ba pọn dandan.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Aje lori iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ẹka ofurufu to bẹrẹ lọjọ Aje ni wọn ti sọ eyi.

Gẹgẹbi atẹjade naa ṣe sọ, igbesẹ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa le mu idiwọ funigbokegbodo ọkọ ofurufu.