Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa alẹ́ ọjọ́ tó ku ọjọ́ mẹ́wàá kí àwẹ̀ Ramadan parí

Aworan

Alẹ ọjọ Laylatul Qadr jẹ alẹ ọjọ to pọndandan fun awọn Musulumi ni agbaye.

O jẹ alẹ ọjọ ti awọn Musulumi gbagbọ wi pe Allah fi ọpọlọpọ ibukun si fun gbogbo awọn to ba yege fun lati gba ibukun bi Ọlọrun ṣe sọ ninu iwe Suratai Qadri.

Alaye ree lori ohun to yẹ ki awọn Musulumi mọ nigba alẹ yii ati igba to yẹ ki eniyan gbadura fun ni alẹ ọjọ naa.

Onimọ nipa ẹsin Islam ni alẹ ọjọ ibukun ni to si jẹ alẹ ọjọ to ku mẹwaa ki awe Ramadan pari.

Imaamu Juma Masjid ti ileẹkọ Misau High Schoo, Malaam Muhammad Albani Misau ni alẹ ọjọ naa ni ọpọlọpọ aabo ati ibukun lati aarọ titi di alẹ.

‘’Ire alẹ ọjọ naa ju ire ẹgbẹgbẹrun oṣu lọ, ire ọjọ kan naa ju ti ọdun mẹrinlelọgọrin lọ to fi mọ oṣu.’’

O ṣalaye pe Anọbi Muhammadu ni ẹni to ba dide lati gbadura ni alẹ ọjọ Laylatul Qadr, pẹlu igbagbọ ni yoo ri idariji gbogbo ẹṣẹ rẹ gba gẹgẹ bi iwe mimọ ti wi.

Ninu ọrọ tirẹ, Sheik Khalifa Muhammadu Mashhoud to jẹ onimọ nipa ẹṣin Islam ni Naijiria ni Laylatul jẹ oun to ṣọwọn ninu ẹsin Islam.

Kilo yẹ ki Musulumi ṣe ni alẹ ọjọ Laylatul Qadr?

Ohun ti o yẹ ki Musulumi ṣe ni alẹ ọjọ yii ni lati sin Ọlọrun bi o ṣe yẹ ni ojoojumọ nipa adura, kika Quran, iṣoore, ẹbun, Zikr ati adura.

Ni akoko yii, onimọ naa ni Anọbi Muhammadu (PBUH) ṣe bẹẹ gẹgẹ bi ti o si ko gbogbo ẹbi rẹ jọ lati kopa ninu ibukun alẹ naa.

Sheik Khalifa Mashshoud ni iwa rere lo yẹ fun awọn Musulumi ni alẹ naa, ki ṣe ki a ri wọn ki wọn maa sọrọ ẹlomiran lẹyin.

‘’Nitori oun gba awẹ, titi di igba ti o ba mu omi, ohun to wa ni ọkan rẹ ni igba ti yoo ja awẹ rẹ ati igba ti yoo ba Ọlọrun pada. Amọ eniyan ko lee ni ayọ yii afi ti o ba hu iwa rere asiko Ramadan.

Ọgbọn to rọ mọ oru yii...

Ọgbọn nla to wa ninu adura oru ni yii ni lati sin Ọlọrun ni oru lai se imẹlẹ.

Lati ibẹrẹ aawẹ Ramadan to jẹ osu mimọ to ni ibukun ni Prophet ti ni alẹ ti o dara fun eniyan ni.

Onimọ nipa ẹsin Islam ni Kano, Sheikh Aminu Ibrahim Daurawa ni eniyan ko gbọdọ ṣe imẹlẹ nitori o le jẹ alẹ ti eniyan ko kasi ni yoo jẹ alẹ Laylatul Qadr

Awọn ami to wa fun alẹ Ọjọ Laylatul Qadr

Sheikh Daurawa ni ọpọlọpọ ami lo wa fun alẹ yii ti awọn eniyan le mọ.

O ni Anọbi Muhammadu sọ pe ni alẹ yii oju ọjọ ma n yi pada.’’ Ti oju ọjọ ba tutu ni ọjọ naa, ti o ba di asiko Laylatul Qadr, alẹ naa ko ni tutu lọpọ.

To ba jẹ pe oju ọjọ gbona ni ọjọ naa, alẹ ọjọ Laylatul yoo tutu.

Bakan naa ni awọn ami to n tẹlẹ oorun ko ni si nibẹ ni kete ti alẹ naa ba ti kọja ni ọjọ keji.

Bakan naa lo sọ nipa awọn ami miran ti ko fi ẹṣẹ mulẹ nipa alẹ ọjọ Laylatul Qadr.