‘Scope’ ni Abiola Ajimobi fi mú mi mọ́lẹ̀ nígbà tó fẹ́ fẹ mi, Ó ní agbọ́pá àlùfáà Kátólíkì lòun – Florence Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi/instagram
Iyawo Oloogbe Abiọla Ajimọbi to jẹ gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ, Arabinrin Florence Ajimọbi ni lara awọn ọrọ ofege ti Oloye Abiọla Ajimọbi fi fẹ oun ni piparọ fun oun pekristẹni loun, atipe agbọpa alufaa ni ijọ Katoliki loun pẹlu.
Arabinrin Florence Ajimọbi sọ eyi lasiko to fi n fọnrere awọn ohun adidun to waye laarin oun ati ọkọ rẹ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi lori eto kan lori ileeṣẹ redio Flash FM ni ilu Ibadan lọjọ Satide.
O ni ko si aniani pe aye Abiọla Ajimọbi yọ silẹ ninu aye oun lẹyin iku rẹ, ṣugbọn oun ri ọpẹ da fun aduroti Ọlọrun.
Gomina Abiọla Ajimọbi jade laye lọdun 2020 lẹyin to ko aisan koro.
“Aisan COVID-19 to mu u lọ doro nitori pe awa mejeeji gan lo ko arun ọhun nigba naa. O jẹ iriri kan ti mi o ki n fẹ maa ranti.
Oloye Florence Ajimọbi ni ara ọgbọn ẹwẹ ti ọkọ oun fi mu oun mọlẹ lati fẹ ni piparọ pe kristẹni loun nitori pe o mọ pe ọmọ ijọ aguda ni oun nigba naa.
Ẹ mọ awọn ọkunrin. O sọ fun mi pe agbọpa alufaa loun ni ijọ St Patricks’- ọrọ ofege miran tun leyi- nitori pe o mọ pe kristẹni ni mi, musulumi loun.

Oríṣun àwòrán, abiolaajimobi/instagram
“Lọdun yii kan naa ni a ṣe igbeyawo. A fẹra sọna fun bi oṣu meje. Ifẹ aiṣẹtan ni mo ni sii, ti mo si tun ṣi ni sii.”
O ni igba ti awọn n pada sile lọjọ igbeyawo ni ọkọ oun to sọ fun oun musulumi loun o, inu oun yoo si dun lati tẹsiwaju pẹlu ẹsin oun.
Iyaafin Ajimọbi ni ọkọ oun kii ṣe alagabagebe ẹda bikoṣe olootọ eeyan ti kii fi igba kan bọkan ninu rara.
O ni o fun oun loreẹfẹ ati ṣe ẹsin oun, bẹẹni ko si igba kankan ti awẹ ramadan ba waye ti oun pẹlu kii finufindọ gba, koda lẹyin iku rẹ.
Ta ni Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ati Florence Ajimọbi?

Oríṣun àwòrán, abiolaajimobi/instagram
Gbajumọ oṣelu ati oniṣẹ adani ni Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.
O kọkọ jẹ sẹnetọ ni dun 2003 ki o to wa di gomina ipinlẹ Ọyọ ni ọdun 2011. Oun si ni oloṣelu akọkọ ti yoo lo saa meji nipo gẹgẹbi gomina nipinlẹ Ọyọ.
Amọ, lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2020, iṣẹlẹ nla ṣẹlẹ, iku wọle mu Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi lọ.
Odu ti kii se aimọ fun oloko ni Oloye Florence Ajimobi nitori oun ni aya gomina ana nipinlẹ Oyo to ti di oloogbe, Abiola Ajimobi.
Oun si ni obinrin akọkọ nipinlẹ Oyo lasiko ti ọkọ rẹ jẹ gomina fun saa meji nipinlẹ Oyo laarin ọdun 2011 si 2019.












