Àwọn ‘Obidients’ti di egungun ẹja sí APC lọ́rùn – Shehu Sani

Shehu Sani

Oríṣun àwòrán, Facebook/shehu sani

Awọn ọmọlẹyìn Peter Obi ti gbogbo aye mọ si ‘Obidients’ ni ko jẹ kí ọrọ akoso orileede Naijiria buru ju bayii lọ.

Gbajumọ oloṣelu kan nipinlẹ Kaduna, Sẹnetọ Shehu Sani lo sọ bẹẹ ni u atẹjade kan to fi sita loju opo Twitter rẹ.

O ni kani kii ṣe ti gulegule awọn ‘obidients’ wọnyi ni, orilẹede Naijiria I ba ti bọ si abẹ ojọba familete n tutọ.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn ‘obidients’ ti di egungun ẹja si ọna ọfun ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba lorilẹede Naijiria.

Sani to ti n lọgun tantan kaakiri latigba ti eto idibo aarẹ ti waye loṣu keji kan sara si awọn omolẹyin Peter Obi naa fun ipa tí wọn n ni lori eto oṣelu Naijiria lọwọlọwọ.

“Bi eeyan ba yọ ọwọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu Labour Party kuro lagbo oselu Naijiria bayii, alaafia ti gbogbo wa n fẹ yoo jọba, ṣugbọn ijọba familete n tutọ ti a ko fẹ naa yoo yọju.”

Atẹjade ti Shehu Sani fi sita

Oríṣun àwòrán, screenshot

Bi a ko ba gbagbe, Oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi lo ṣe ipo kẹta ninu idibo sipo aarẹ to waye loṣu keji, o si ti gba ile ẹjọ lọ bayii lati wi awijare pe oun lo bori.