Meghan kò ní yọjú síbi ayẹyẹ ìfinijoyè Ọba Charles

Aafin Buckingham ti kede pe Ọmọọba Harry yoo darapọ mọ awọn mọlẹbi Ọba fun ayẹyẹ ifinijoye Ọba Charles ni oṣu to n bọ sugbọn iyawo rẹ ko ni tẹle wa.
Ọpọ awọn eeyan lo ti n bere fun ọpọlọpọ oṣu pe n jẹ o sese ki tọkọtaya naa yọju si bi ayẹyẹ naa sugbọn pẹlu ikede, gbogbo ibeere ni o jẹ didahun.
Ọmọọba Harry yoo darapọ awọn alejo to to ẹgbẹrun meji ni ye ni gbọngan Westminster Abbey lọjọ kẹfa oṣu karun.
Eyi ni igba akọkọ ti fi oju han si idile Ọba lẹyin ti gba iwe rẹ, Spare, jade.
Iwe Ọmọọba Harry lo tu kẹkẹ ọrọ lori bi ede ayede se waye laarin oun ati idile Ọba, to si ni ero oun yatọ si ti awọn mọlẹbi yooku.
Bi Meghan se kọ lati kopa nibi ifinijoye naa ni yoo jẹ ki awọn eeyan gbagbọ pe o da le lori bi rogbodiyan se bẹ silẹ ninu mọlẹbi naa, eyi ti wọn ko ti ri yanju titi di asiko yii.
Iwe Ọmọọba Harry ati sinima kan to gbe jade lori ayelujara salaye bi wọn se tabuku iyawo rẹ, Maghan, to si ni mọlẹbi oun ko pese iranlọwọ kankan.
Ọjọ ayẹyẹ naa lo jẹ ọjọbi ọmọ Harry ati Meghan, iyin Archie, to n gbe pẹlu iya rẹ ni Amẹrika.
Ninu atẹjade ti Harry ati Meghan fi ransẹ sawọn akọroyin
“Duke ti Sussex yoo yọju si bi ayẹyẹ ifinijoye ni Westminister Abbey lọjọ kẹfa oṣu karun.
"Di Duchess ti Sussex yoo duro siluu Amẹrika pẹlu Ọmọọba Archie ati Ọmọọbabinrin Lilibet."
Agbẹnusọ awọn tọkọtaya naa ni ọrọ naa ko ju bẹ lọ
Ikede ọhun tumọ si pe Ọmọọba Harry yoo kopa ninu ayẹyẹ naa.















