Orisabunmi Olasanya: Pásítọ̀ àti Alfa ń wá ṣe òògùn lọ́dọ̀ bàbá mi, ìṣẹ̀ṣe ni kìí ṣe àmúlùmálà

Àkọlé fídíò, Orisabunmi Olasanya: Pásítọ̀ àti Alfa ń wá ṣe òògùn lọ́dọ̀ bàbá mi

Ninu ẹsin mẹta to wa nilẹ Naijiria, eyiun ẹsin isẹse, Kristiẹni ati Islam, isẹse nikan lo jẹ abalaye nilẹ oruba.

Amọ ọpọ eeyan ni kii fẹ safihan ẹsin naa ni gbangba, ti wọn si ri bii ẹsin ti ko laju ati ẹsin atijọ.

O si jẹ iyalẹnu nla lati ri ọmọge to n se ẹsin yii lai fi pamọ, to n so owo ẹyọ mọ ọwọ ati ẹsẹ lati fihan pe Onifa ni oun.

Orisabunmi Olasanya ni orukọ ọmọge ọhun, to si kawe gboye imọ ijinlẹ akọkọ ni fasiti.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Orisabunmi salaye ọpọ ipenija to n koju lati ọdọ awọn ọkunrin tori pe o jẹ ẹlẹsin ibilẹ.

Bakan naa, o tun sọ bawọn ẹlẹsin igbalode meji to ku se n fi ẹsin naa se amulumala nitori pe wọ̀\n maa n tọ baba oun wa, tii se babalawo lati se oogun.

Orisabunmi tun fikun pe oun ti lọ si sọọsi ri, ti oun si ti se akọrin ri ninu sọọsi amọ oun pada sidi ẹsin ibilẹ nitori pe ẹsin isẹse nikan lo pe.