Queens that are not from Yoruba land: Lára Oríadé Yorùbá tó ti fi àjèjì ṣe ayaba ní Olubadan, Ooni, Alaafin àti Oluwo àwọn obìnrin tí kìí ṣe ọmọ Yorùbá tó jẹ́ ayaba ní ààfin ilẹ̀ Káàárọ̀ oòjíire

Ni ilẹ Yoruba, pataki ni awọn olori tabi ayaba ninu aafin, nitori awọn ni ejika ti ko jẹ ki asọ o bọ, awọn si ni opo mulero to n di aafin mu fawọn ọba alaye wa.
Owe Yoruba kan ko ni 'Ko si apọnle fun ọba ti ko ni Olori' si lo kin ọrọ yii lẹyin pe awọn olori ninu aafin kii se fifi di gẹrẹu lasan, ipo pataki ni wọn di mu.
Koda, a ti ri awọn ayaba kan nilẹ Yoruba bii Mọremi, tii se ayaba Ọọni tilu ile Ife nigba atijọ, to se atilẹyin fun ọkọ rẹ, to si gba ilẹ Ife lọwọ ogun awọn Igbo.
- Taa ni Firdauz Abdullahi, ọmọbabìnrin Kano tí yóò di olorì tuntun fún Oluwo?
- Oluwo àti Olorì àná, Chanel Chin tahùn síra
- Ẹ dẹ́kun bíba ìjọba lórúkọ jẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì sí lẹ́tà Oluwo
- Ọ̀rọ̀ èmi àti Olorì Chanel Chin kò yé ara wa mọ́ nínú ilé- Oluwo
- Mọ̀ síi nípa àwọn Obìnrin tó wà láyé Ooni Ogunwusi ṣáájú Olòrì Naomi SilekunOla
- Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀
Ọpọ eeyan lo nigbagbọ pe awọn ayaba ni aafin ilẹ Yoruba nilo lati gbọ tabi sọ ede abinibi wa daadaa, ki wọn si tun mọ isẹse ilẹ Oodua bo se yẹ.
Wọn ni imọ nipa asa, ede ati ise ilẹ Yoruba fun awọn olori yii ni yoo seranwọ fun wọn lati ran awọn ọba, to jẹ ọkọ wọn lọwọ, ki wọn lee se aseye ti alakan n se epo lori itẹ.
Sugbọn ta ba wo ilẹ Yoruba kaakiri, a ri pe awọn ayaba kan wa ni awọn aafin nilẹ Yoruba, ti wọn kii se ọmọ bibi ilẹ kaarọ o jiire.
Bi a se ni awọn ayaba ti kii se ọmọ ilẹ Yoruba ti wọn wa ni awọn aafin nilẹ Kaarọ oojire, naa la ni awọn ayaba yii ti wọn ti kọ awọn ọkọ wọn silẹ, ti wọn ko si si ni aafin mọ.
Awọn ilu ti awọn Olori yii si wa ni wọn ti sa ipa tiwọn lati gbe ilu naa ni arugẹ, eyi si lo mu ki BBC Yoruba se akojọpọ awọn olori ti kii se ọmọ Yoruba ti wọn jẹ ayaba laafin awọn ọba wa.
Awọn obinrin ti kii se Yoruba ti wọn jẹ Olorì ni aafin ilẹ Yoruba:
Joyce Lekan-Balogun - Olori ni aafin Olubadan tilẹ Ibadan:

Mama Joyce Balogun jẹ ọmọ bibi ilu Onisha nipinlẹ Anambra, to si jẹ ẹya Igbo ti wọn wa lati apa ila oorun guusu Naijiria.
Oun si ni akọbi lobinrin tabi Bẹ́ẹ́rẹ̀ fun aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Ọmọwe Nnamdi Azikwe.
Amọ ilu Eko ni obinrin naa gbe dagba, to si mọ asa ati ise ilẹ Yoruba.
Mama Balogun lo fẹ Sẹnetọ Lekan Balogun, tii se Olubadan tuntun to sẹsẹ jẹ nilẹ Ibadan, ẹni ti wọn de ade fun ni ọjọ Kọkanla osu Kẹta ọdun 2022.
Asiko yii si lo han si ọpọ eeyan pe ọmọ bibi ilẹ Igbo ni aya Olubadan tuntun, to si ti n se Olori ninu aafin ọkọ rẹ bayii.
Olori Zaynab Otiti Obanor - Olori tẹlẹ ni aafin Ooni tilu Ile Ifẹ:

Oríṣun àwòrán, Ooni Adimula
Lara awọn ayaba ti kii se ọmọ ilẹ Yoruba ti wọn fẹ oriade, ti wọn si gbe ni aafin nilẹ Kaarọ oojire, ni Olori Zaynab Otiti Obanor.
Ayaba ati Yeyelua si lo jẹ tẹlẹ ni aafin Ooni Adimula tilu Ile Ifẹ, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi.
Ni kete ti Kabiyesi naa jẹ Ooni, ni wọn fẹ Olori Zaynab wọle si aafin bi o tilẹ jẹ pe ajọsepọ lọkọ laya naa ko pẹ rara, to fi fori sanpọn.
Ọmọọba ni Olori Zaynab ilu Benin, tii se olu ilu ipinlẹ́ Edo, to si fẹ Ọọni Ogunwusi lọdun 2015.
Amọ lọdun 2017 ni wọn tuka bii tọkọ tiyawo, ti oriade naa si fẹ ayaba tuntun, Olori Naomi Silekunola Moronke Ogunwusi si aafin rẹ.
Olori Chioma Adeyemi - Olori Alaafin tilu Oyo:

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo
Ni osu kẹta ọdun 2021 ni iroyin gbalẹ kan pe Alaafin tilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti ba wọn se ana nilẹ Igbo.
Orukọ Olori naa si ni Chioma.
Chioma si lo wa lara awọn olori jojolo ẹlẹjẹ tutu ti wọn jẹ Ẹ̀lẹ̀ Daddy, tó n mu ki eegun ara ọba alaye naa le koko si.
Olori Chanel Chin - Ayaba tẹlẹ fun Oluwo tilu Iwo

Lara awọn obinrin ti kii se ọmọ Yoruba to fẹ ọba alaye nilẹ Kaarọ Oojire ni Olori Chanel Chin.
Oun si ni Olori tẹlẹ fun ọba Oluwo tilu Iwo, Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kiini.
Ọmọ bibi orilẹede Jamaica ni Chanel Chin, ti oun ati Oluwo si bi ọmọ kan fun ara wọn, ti wọn pe orukọ rẹ ni Oduduwa.
Bakan naa ni Chanel jẹ ọmọ bibi inu gbajumọ akọrin takansufe orin Reggae, Ludlow Chin, ti ọpọ eeyan tun n pe ni Bobo Zaro.
Lasiko ti Chanel jẹ Olori ni aafin Iwo, o maa n de ade sori bii ọkọ rẹ, ti Oluwo si ni oun ni ọba fun awọn obinrin lo jẹ ko maa de ade.
Amọ nigba ti ija de laarin lọkọlaya naa, ni orin di owe, ti wọn si n ka oniruuru ẹsun si ara wọn lọrun nipa asise koowa wọn.
Firdauz Abdullahi - Olori tuntun ti Oluwo fẹ fi se aya:
Lẹyin ọdun diẹ ti aarin Oluwo ati olori rẹ, Chanel Chin daru, oriade naa tun ti n gbe igbesẹ lati tun yigi se plu obinrin miran.
Orukọ olori tuntun naa ni Firdauz Abdullahi.
Gẹgẹ bi Olori Chanel Chin, Firdauz Abdullahi kii se ọmọ bibi ilẹ Yoruba amọ o jẹ ọmọ bibi ilu Kano to wa ni apa Oke ọya.
Idile ọba Ado Bayero ni Firdauz ti wa, ti igbeyawo oun ati Oluwo yoo si waye lọjọ Satide, ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹta ọdun 2022.
Lọwọ bayii, Oluwo ko tii si asọ loju eeun nipa bi Firdauz se ri nitori ko tii fi aworan rẹ sita fun araye ri.
Ti Firdauz ba si di ayaba tan, isẹ takuntakun lo n duro de gẹgẹ bi olori fawọn nilu Iwo.`


















