Oluwo, ó yẹ kí o bọ̀wọ̀ fún ara rẹ - Olorì àná, Chanel Chin

Oríṣun àwòrán, Queen Cha/instagram
Kii ṣe tuntun mọ pe kabiyesi Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Rasheed Akanbi ati olori rẹ, Chanel Chin ti kọ ara wọn silẹ. Bi o tilẹ jẹ pe kabiyesi funrarẹ lo kede iyapa laarin wọn, olori Chanel ko fọhun lori ọrọ ana ayafi bayii lori oju opo Instagram rẹ.
Ninu ọrọ to fi sita loju opo naa, Olori ana, Chanel Chin ṣalaye pe lati igba ti Oluwo ti n fọnrere ọrọ naa lori ayelujara, oun mọọmọ dakẹ ni. o fẹsun kan kabiyesi pe oniruuru ọrọ ibanilorukọ jẹ ni kabiyesi ti sọ nipa oun ṣugbọn ọbẹ kii mi nikun agba loun fi ṣe.
- Ọpọ́n Nàìjíríà ti sún kọjá ríronú APC, àwa ti ń wá olùdíje fún ọdún 2023 - PDP
- Mo funra sí 'Swimming Pool' tí ọkọ àti àwọn ọmọ mi rì sí - Olubunmi Diya
- Ìdí tí mo fi gún olólùfẹ́ mi tẹ́lẹ̀ pa - Jacinta Igboke
- Ìjọba korò ojú sí bí Islamic State ṣe bẹ́ àwọn Kristiẹni mẹ́wàá lórí ní Bornu
- Idí ti a ko ṣe tú El-Zakzeky silẹ láhàmọ́- Malami
- Ìjọba Kano fi páńpẹ́ òfin mú Ọba àwọn Oṣó lórí ẹ̀sùn jìbìtì
O ni ọ̀wọ̀ ti oun ni fun itẹ Oluwo ni ko jẹ ki oun sọrọ si gbogbo oun ti Kabiyesi Oluwo to jẹ ọkọ oun ana n fi sita.
"Amọṣa, bi kabiyesi ko ba bọwọ fun ara rẹ tabi ori itẹ to joko si ...ta ni yoo bọwọ fun un"
O ni igba akọkọ kọ niyii ti Oluwo yoo maa ba awọn eeyan lorukọ jẹ tabi hun irọ jọ nipa eniyan.
Amọṣa kabiyesi naa ti fesi, oluwo ni bo ba wu olori ana lati duro si Orilẹede naijiria, dede ara rẹ ni o, ṣugbọn gbogbo ẹtọ to yẹ fun irinajo rẹ pada si Canada tii ṣe orilẹede rẹ loun ti ṣe.









