Alaafin Oyo: Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Sleekgist.com
Yoruba ni karin-kapọ, yiyẹ ni i yẹni, bẹẹ gan ni nkan ri ni aafin ilu Ọyọ, pẹlu bi olori tuntun mii ṣe wọ aafin.
Iroyin taa gbọ ni pe Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi II tun ti fẹ olori mii. Koda, ilẹ Igbo ni Kabiesi ti lọ mu ayaba tuntun.
Ayaba tuntun naa, Chioma Adeyemi, lo kọwọrin pẹlu Kabiesi ni gbangba fun igba akọkọ, lasiko ti Alaafin fi gbajugbaja oniṣowo kan, Tomori Williams jẹ oye Aarẹ Onikoyi ilẹ Yoruba, ni ọsẹ to kọja.
Gẹgẹ bi iṣe Kabiesi, oun ati awọn olori rẹ ni wọn jọ rin wọ inu gbọngan ayẹyẹ ifinijoye naa.
Aṣọ leesi funfun, gele funfun ati awọn ẹṣọ ara ni awọn olori naa wọ.
Ayaba tuntun naa si wa lara wọn.
Koda, aaye ti aayọ Ọba maa n duro si ni Chioma jokoo si ni ode naa, ọwọ osi Kabiesi lo duro si.
- Torí Kashy Godson ni abúrò mi Barry Jhay ṣe lọ sí Ghana, kí lódé tó fi máa pa á? - Ronke Balogun
- Mo ti kúrò ní ààfin Oyo, kí ìròyìn tó ò jáde pé èmi àti Wasiu Ayinde n fẹ́ ara wa - Olori Badirat
- Mo ti gbà báyìí pé ohun gbogbo tó n dán kọ́ ni wúrà - Olori Badirat Adeyemi
- Eyí ni àwọn arẹwà 'ẹ̀lẹ̀ Daddy', àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
- Ẹni bá rí i kó sọ o, Ìjọba ń wá ẹni dún 45 tó fipá bá ọmọ ọdún méje lòpọ̀
O ṣe e ṣe ki ọpọ eeyan to wa nibi ayẹyẹ naa o ma tete mọ pe ayaba tuntun n bẹ laarin awọn yooku, titi di igba ti agba olorin Fuji, Wasiu Ayinde bẹrẹ si ni i ki wọn.
Eyi waye lasiko ti Kabiesi ati awọn olori rẹ, ti gbogbo wọn jẹ apọnbeporẹ, arẹwa obinrin lọ si oju agbo lati jo.
Lẹyin ti KWAM 1 ti fi orin oriṣiriṣi ki Alaafin, lo bẹrẹ si ni ki awọn olori rẹ naa.
O bẹrẹ lati ọdọ olori agba patapata, Olori Abibatu, titi to fi de ori orukọ kan, Chioma.
Olori Chioma lo ki gbẹhin, eyi to ṣe e ṣe ki o mu ki ọpọ eeyan o ma a wo pe ṣe Kabiesi tun ti fẹ olori tuntun ni.
Eyi gan-an lo mu ki BBC Yoruba bẹrẹ iwadii pe ṣe lootọ ni Alaafin ilu Ọyọ ti ni ayaba tuntun?
Iwadii wa lo fi han pe lootọ ni ayaba tuntun ti wa ni aafin Ọyọ. Chioma si ni orukọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, livetimesng.com
A fi idi eyi mulẹ ninu fidio kan to wa ni ori ayelujara Youtube, loju opo Islanderstv nibi ti Wasiu Ayinde ti n ki awọn ayaba naa.
Bakan naa la ṣe akiyesi rẹ pe ọkan lara awọn ayaba to jade jó pẹlu Kabiesi rọra duro si ẹgbẹ kan lọdọ Kabiesi.
Eyi to ṣeṣe ko tumọ si pe ara rẹ ko ti i mọle daadaa pẹlu awọn ayaba to ku.
- Olorì Anu Adeyemi ń ṣe ọjọ ìbí, ẹ gbọ́ ǹkan tò sọ sí Kábíyésì
- Olorì Aláàfín tẹ́lẹ̀, Anuoluwapo Adeyemi gba àmì ẹ̀yẹ lórí ipa tó kó nínú oge ṣíṣe
- Wo àwọn Adelé-Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Kí ló pa Bobrisky àti Olorì Aláàfin Oyo pọ̀?
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
Iroyin sọ pe ọdun to kọja ni Kabiesi fẹ Chioma, to jẹ ọmọ ẹya Igbo.
Ohun si ni olori Alaafin akọkọ lati ẹya Igbo.
Ao tii le sọ boya Olori Chioma ti wa ninu irinajo oṣu mẹsan-an, lati mọ boya ka maa reti ibeji lanti lanti mii laipẹ gẹ́gẹ́ bi wọn ṣe maa n ti ara Kabiyesi jade.
Tẹ o ba gbagbe, olori Alaafin meji, Badirat Ajọkẹ ati Aanuoluwapọ, lo kuro ni aafin.
Awuyewuye kọkọ jade pe ọrọ ifẹ ikọkọ wa laarin Badirat ati Wasiu Ayinde, lo mu ki wọn o le e kuro ni aafin.
- Wàwúù!!! Lẹ́yìn ọmọ márun-ùn, wo bí ìyàwó àgbẹ̀ se tún bí ìbaàrùn-ún ní Ogbomoso láì ṣe iṣẹ́ abẹ
- A ò lè kọ ẹbí olóògbé Kashy bí wọn ṣe máa hùwà torí ọmọ wọn papòda àmọ mo mọ̀ pé Barry Jhay... - Ẹbí Sikiru Ayinde Barrister
- Bí ilé ẹjọ́ bá pàṣẹ kí Krìstẹ́nì àti Mùsùlùmí máa pe Ọlọ́run ní Allah, kí lẹ ó ṣe?
- Mọ̀ síi nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríru tó mú ẹ̀mí 16,000 èèyàn lọ tó sì ba dukia $206b jẹ́
- Wọ́n jí mi gbé, só mí mọ́lẹ̀ bí ẹ̀ran, fipábámilòpọ̀ láti di aya wọn torí mo jẹ́ Krìstẹ́nì - Ọmọbìnrin ọdún méjìlà
Ṣugbọn Badirat sọ lẹyin oṣu diẹ pe oun finnu-findọ kuro ni aafin ni.
Oṣu diẹ lẹyin ti Badirat kuro, ni iroyin tun jade pe Aanu naa ti sa kuro ni aafin.
Ọjọ diẹ lẹyin ti iroyin naa jade ni Aanu kọ sori ayelujara pe Kabiesi n lepa ẹmi oun lati pa.
A ko tii ni akọsilẹ kankan nipa Olori Chioma, bẹẹ ni aafin ko si fi ikede sita tabi ba oniroyin sọrọ lori rẹ.


















