Alaafin Oyo: Ọmọ Yorùbá sọ fún olorì Anu pé kò yẹ kó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀ ìgbéyàwó rẹ̀ sí gbangba

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen__aanu
Awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni wi tọkan wọn jade nipa igbesẹ olori Aanu, ayaba Alaafin Oyo, to sa kuro ni aafin tọmọtọmọ.
Loju opo BBC News Yoruba, niṣe lawọn kan n bẹnu atẹ lu igbesẹ rẹ, tawọn mii si ni o dara bo ti ṣe sa asala f'ẹmi ara rẹ.
Loju opo Instagram rẹ, ni olori Aanu ti sọrọ sita pe, ti nkankan ba ṣẹlẹ si oun lẹyin toun fi aafin silẹ, Alaafin ni ki awọn eeyan mu.
- Ta ni olóògbé Jerry Rawlings, tó darí Ghana fún ogún ọdún?
- Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l‘Eko
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Ìdàlúrú gbòde, ìjọba kéde ìṣéde torí nǹkan ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó ń pòórá
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
- Sina Jesu ní orúkọ́ mi báyìí, ń kò jẹ́ Shina Rambo mọ́ - Adigunjalè tẹ́lẹ̀ kìlọ̀
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
Ọrọ pe ki awọn eeyan da ẹbi ru Alaafin yii ni arakunrin kan Paul Temitope Ilesanmi fi da lohun pe, ko si nkankan ti yoo ṣelẹ si alayeluwa.
O ni lẹyin igba ti olori Aanu ti jẹ owo Alaafin tan, ko le ṣadede sa kuro.
''Wo Alaafin kii ṣe ọkunrin lasan, to kan le jẹ (owo rẹ), ti wa wa salọ''

Bakan naa ni ẹnikan naa sọ loju opo BBC pe, ko yẹ ki olori maa tu aṣiri ohun to ṣẹlẹ ni kọkọ faraye gbọ.
Benny Fortune Akinyemi wa fi ibeere le fun olori Aanu pe ''Nigba ti nkan n rọsọmu laarin olori ati Alaafin, ta lo gbọ si?

Ṣugbọn o ni awọn eeyan miran to sọ pe, ki awọn eeyan foju aanu wo Aanu nitori o ṣeeṣe ki o ma jẹ oju lasan lo mu kuro ni aafin.
Ninu ọrọ ti wọn, wọn ni olori ko le ṣadede gbe igbesẹ to gbe, bi kii ṣe pe ẹmi rẹ wa ninu ewu lootọ.

Titi di igba ti a fi n ṣe akojọ iroyin yii, aafin Oyo ko ti fesi si gbogbo ohun ti olori Aanu n sọ.
Ninu awọn olori to kuro laafin laipẹ yii ni olori Aanu wa.
















