Civilian JTF: Kí ló mú aṣáájú Yorùbá tako ìgbésẹ ológun láti gbà ọdẹ́ ìbílẹ̀ JTF ṣiṣẹ ní Borno?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbaagba ẹgbẹ iṣọkan ilẹ Yoruba ti gbarata lori igbesẹ ileeṣẹ ologun Naijiria lati gba ọmọ ikọ alaabo abẹle Civilian JTF irinwo ni Bornu siṣẹ ologun Naijiria.
Ninu ohun tawọn agba wọnyi sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo, wọn ni ọgbọn irẹjẹ leyi jẹ, to si tubọ fidi ọrọ mulẹ pe, aparo kan ga ju ọkan lọ ninu iṣejọba Naijiria.
Alagba Ayo Adebanjo to jẹ olori ẹgbẹ Afenifẹre ilẹ Yoruba wa lara awọn to ni igbesẹ naa ku diẹ kaato.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alagba Adebanjo ni irẹjẹ gbaa ni iwa yii jẹ ati pe awọn ti n sọrọ tako iru nnkan bayii.
Agba ọjẹ naa ni nitori iru nkan bayi lawọn fi n lọgun pe ''ki atunto iṣejọba ta mọ si Restructuring waye ni Naijiria''
''A ti ni ki wọn ṣe atunto tipẹ lati le mu iru irẹjẹ yii kuro. A ti n sọ pe o yẹ ki a ni ikọ ọlọpaa ati ologun fun ipinlẹ kọọkan.''
Ohun ta ba si ro pe o da fun iha kan Naijiria, iru rẹ yẹ ko da fun awọn to ku, ti Naijiria ko ba ti ṣe atunto yii, ilu ko le rọgbọ."
''Wọn ko fẹ ṣe atutnto yi nitori ohun ni wọn fi n ko gbogbo ọrọ wa lọ si ọdọ wọn, ko tọ ki wọn gba awọn kan si iṣẹ ologun laifi tawọn apa Naijiria mii ṣe.
Bashorun Seinde Awogbofa to jẹ akọwe Afenifere naa da si ọrọ yii.
O ni lootọ ni pe wọn ni ipenija aabo wa ni ariwa Naijiria ṣugbọn ipenija aabo ko yọ apa Naijiria kankan silẹ.
''Gbigba eeyan siṣẹ ologun ni eto tirẹ, ohun to yẹ ni ki ijọba gba gbogbo eeyan lai da apa orilẹede Naijira kan si.'
Alagba Awogbofa ni ohun tawọn n wi yii, awọn aṣoju lati ariwa Naijiria bi Sẹnẹtọ Ali Ndume naa ko dakẹ lori rẹ, paapa bi ijọba ti ṣe fẹ forijin awọn ọmọ ikọ Boko Haram to yiwa pada.
O wa pe fun iranwọ fawọn ologun Naijiria, ki wọn ba le sẹ aṣeye ti alakan n ṣepo lori awọn agbesunmọmi Boko Haram, to n da omi alafiaa Naijiria ru.
Iléeṣẹ́ ológun sọ ikọ̀ ọdẹ́ ìbílẹ̀ JTF di ológun ní Borno, ẹ̀yà yókù ní Nàíjíríà fọnmú

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Awọn ọmọ Naijiria kan ti fariga lori igbesẹ ileesẹ ologun ilẹ wa lati gba awọn ikọ ojulalakan fi n sọri si aarin wọn.
Ọjọbọ ni ileesẹ ologun kese pe oun ti gba irinwo awọn ọmọ ikọ alajumọse to jẹ araalu (Civilian JTF) nipinlẹ Borno si aarin wọn.
Awọn eeyan naa, ti ọpọ wọn jẹ ọdẹ ibilẹ, ni wọn ni yoo maa seranwọ fun ileesẹ ologun lati gbogun ti ikọ Boko Haram to n ba ipinlẹ naa finra ati apapọ ẹkun ariwa Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó ti ṣe àríyá aláṣọ funfun kó tó kú
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
- Ta ni olóògbé Jerry Rawlings, tí wọ́n fún ní àlàjẹ́ 'Junior Jesus'
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l‘Eko
Amọ igbesẹ naa ti n mu ki awọn ẹya to wa ni Naijiria maa fura pe ejo lọwọ ninu lori ọrọ yii, ti eruku ariwo si n sọ lala.
Ẹgbẹ Arewa to duro awọn eeyan to wa lati ariwa Naijiria n tiẹ fara mọ igbesẹ naa ni digbi amọ ikọ Afenifere to wa fun iran Yoruba ti tako igbesẹ naa patapata.

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Bakan naa ni ẹgbẹ Ohaneze Ndigbo to duro fun awọn eeyan ẹkun ila oorun Naijiria ati ẹgbẹ awọn eeyan aarin gbungbun Naijiria, Middle Belt Forum naa koro oju si igbesẹ naa.
Ko tan sibẹ, ẹgbẹ agbarijọpọ awọn eeyan to n gbe ni aarin gbungbun guusu Naijiria, Pan Niger Delta Forum, naa ti fọnmu pe ko yẹ ko ri bẹẹ.
Ninu awijare awọn ẹgbẹ Afenifere ni ọmọ ogun ẹlẹkunjẹun fun ẹkun kan ni ijọba apapọ n ko jọ.
Yinka Odumakin, tii se akọwe apaps fun ẹgbẹ Afenifere salaye pe awọn ẹkun yoku ni Naijiria kii se omugọ, ko si bi ẹya yoku yoo se ni igbẹkẹle ninu ijọba pẹlu iru iwa yii.
O ni "sebi awọn eeyan ẹkun ariwa yii lo tako agbekalẹ ikọ alaabo Amotekun fun kun iw oorun guusu losu diẹ sẹyin, ki lo wa de ti wọn fi se iks ologun fun ẹkun wsn.
Bakan naa ni ẹgbẹ Pandef, Ohaneze Ndigbo ati Middle Belt Forum fọnmu lori igbesẹ ologun naa, ti wọn si ni o ti foju han gbangba bayii pe ẹka ologun Naijiria ti doju de.
Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l'Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti rọ eyikeyi araalu to ba ni iriri pe ọlọpaa ṣe aṣemaṣe si wọn lati tara fi ẹjọ ọlọpaa bẹẹ sun, ki wọn ba le foju rẹ jofin.
Alukoro ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejobi lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC.
O ni igbesẹ yii wa ni ibamu pẹlu ifarajin ileeṣẹ ọlọpaa lati ri pe awọn oṣiṣẹ rẹ ko tẹ oju ẹtọ araalu loju mọlẹ bi tatẹyin wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Èsì ìjọba UK rèé lórí ìwé ẹ̀sùn ọmọ Nàìjíríà lórí ìkọlù ìjọba sáwọn olùwọ̀de ENDSARS
- Wo bó ṣe le bèèrè láti ṣàtìpó ní Canada bí DJ Switch
- Ìdàlúrú gbòde, ìjọba kéde ìṣéde torí nǹkan ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó ń pòórá
- Òkò gbọnin lórí ìjọba àpápọ̀ tórí pé ó pe àwọn olùwọ́de EndSARS ní agbésùnmọ̀mí
- Ẹ gbà mí o! Ìjọba Buhari ní kí Ológun pa mí láàrin ọjọ́ kan péré - Omoyele Sowore
- Bí nǹkan bá ṣe mí àtàwọn ọmọ mi, Aláàfin ni kẹ mú o - Olorì Anu figbe ta
- Ọ̀pọ̀ òkú fọ́nkálẹ̀ nílé ìwòsàn ìjọba ní Ore, ìpayà àjàkálẹ̀ àrùn gbàlú kan
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
Adejobi wa ṣalaye ni meni meji nipa igbesẹ ti ara ilu le gbe lati fẹjọ oṣiṣẹ ọlọpaa to ba tasẹ agẹrẹ si ofin sun wọn fun iwadii to yẹ..
Wo igbesẹ to gbe lati fi ẹjọ ọlọpaa sun:
Kọ iwe ẹhonu rẹ si ọọfisi Kọmisana Eko:
Olumuyiwa ni aaye wa fara ilu lati kọ iwe wọn si ọọfisi Kọmisana ọlọpaa fun ipinlẹ Eko, to wa ni opopona Muiz Banire ,GRA Ikeja.
O ni ninu iwe yii, wọn gbọdọ pe akiyesi alukoro ileesẹ ọlọpaa si ọrọ naa, ko ba le ri idahun to yẹ.
Alukoro ọlọpaa Eko tun sọ pe, bi wọn ba ri aaye ki wọn fi ọwọ ara wọn wa fi iwe yii sọwọ, ki wọn si ri pe wọn ni ẹda rẹ lọwọ fun amojuto to ba ya.
Anfaani wa lati pe sori ago:
Ilana ikeji ti Alukoro ọlọpaa ṣalaye ni pe, araalu le gba lati fẹjọ ọlọpaa to ba ṣaṣemaṣe sun, ni pipe ileesẹ ọlọpaa lori aago.
O ni anfaani yii ko wulẹ mu wahala pupọ wa ju pe, ki wọn mọ nọmba to yẹ ni pipe lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adejobi ni ẹka ọlọpaa to n gbọ ẹsun lati ọdọ araalu ti wọn n pe ni Public Complaints Bureau, ni o wa nidi ẹka to n gba ipe araalu yii lori ago.
Nọmba awọn ẹka yi to ka sita ni: 09010003792 tabi 09010512350
Fi aworan tabi fidio asemase ọlọpaa si oju opo ayelujara:
Adejobi ni ko si aburu nibi ki eeyan ya aworan tabi fọnran fidio, gẹgẹ bi ẹri lati fi han ileesẹ ọlọpaa nipa oṣiṣẹ rẹ to ba hu iwa ti ko da.
O sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn akọṣẹmọṣẹ ti yoo yẹ iru ẹri bẹ wo finifini.
Amọ o ni pẹlu bi awọn eeyan ti ṣe n fi iroyin ofege lorisirisi sita, eyi ti ko ba daa ju ni ki wọn wa si ẹka ọlọpaa lati fẹjọ sun.
Igba ọtun ti de nipa kikoju iwakiwa laarin awọn ọlọpaa:
Adejobi sọ pe awọn ṣeṣẹ le ọlọpaa mẹwa kuro lẹnu iṣẹ lori iwa ko tọ lẹnu iṣẹ ni nilu Eko.
Igbesẹ yii gẹgẹ bo ti ṣe wi, wa lara ọna ati ṣatunto iṣẹ ọlọpaa ni ibamu pẹlu ilana ode oni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Awọn ti ọrọ yii kan jẹ awọn tara ilu fẹsun kan lati ọdun 2019 si 2020, ninu wọn, awọn eeyan meje kan wa ta le lẹnu iṣẹ, ti a si tun ni ki wọn lọ jẹjọ aṣemaṣe''
O ni atunto naa yoo jẹ eleyi ti yoo maa waye lati igba degba.















