Ginimbi Genius Kadungure: Ẹ wo àwọn ọkọ̀ bọ̀gìnì tí ọ̀dọ́mọdé olówó kó jọ lẹ́ni ọdún 36

Oríṣun àwòrán, Genius Ginimbi Kadungure/INSTAGRAM
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti suyọ lẹyin iku ọdọmọde olowo ati gbajugbaja oniṣowo, Genius Kadungure alias Ginimbi, to ku ni Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kọkanla, ọdun 2020.
Lara awọn ọrọ to suyọ lori ẹrọ ayelujara nii ṣe pẹlu isalẹ ọrọ rẹ, ti wọn ni ko mọ.
Bi awọn kan ṣe n sọ wi pe ejo lo n pọ owo fun un ni igba aye rẹ, ni awọn miran sọ wi pe isalẹ ọrọ rẹ lẹgbin lọna mii.
- Wo iye obìnrin tó bá Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó kú àti obìnrin to ṣeéṣe kó jogún rẹ̀
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́fà tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe láti kékéré
- Mo fi ilé yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyá mí fún àtìlẹyìn àti àdúrà rẹ̀ - Emmanuella
- Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà lára ọkọ̀ tó ń lo bátìrì tó sẹ̀sẹ̀ dé Nàíjíríà
- Buhari, a rántí ìjọba rẹ̀ fún ìyà, ìṣẹ́ àti ebi tó peléke - Araàlú faraya
Lara awọn to n sọrọ lori ẹrọ ayelujara ni, awọn mọ daju wi pe inu yara ibusun rẹ ni ejo ohun wa, ti o ti n pọ owo fun un.
Kini awọn orẹ Ginimbi sọ lori ejo to n pọ owo fun Ginimbi?
Awọn ọrẹ Ginimbi ti jade lati sọ wi pe, ko si otitọ kankan ninu ọrọ pe ejo lo n pọ owo fun Ginibi ati wi pe, ki wọn fi oloogbe naa silẹ ki o sun ire.

Oríṣun àwòrán, Genius Ginimbi Kadungure/INSTAGRAM
Ronald Muzambe, to jẹ ọkan lara awọn ọrẹ timọtimọ rẹ, sọ pe ahẹsọ ọrọ lasan ni ati wi pe ki lo de ti awọn eniyan ko ṣewadii ọrọ Ginimbi lasiko to wa laye.
''Gbogbo eniyan to wa laye lo ni anfaani fun ọdun mẹrindinlogoji lati ṣe iwadii ọrọ Ginimbi, amọ wọn ko ṣe e''
''Ti ko ba ti si ẹni to wadii ọrọ rẹ kulẹkulẹ nigba ti o wa laye, nitori naa ki wọn jawo lati ma sọ ọrọ rẹ laida lẹyin to papoda.''

Oríṣun àwòrán, Genius Ginimbi Kadungure/INSTAGRAM
Muzambe ni ki wọn fi oku orun silẹ ko sun ni alaafia.
O si rọ awọn eniyan lati lo oju aanu ti wọn ni lati fi kẹdun pẹlu ẹbi ati ara to fi silẹ, ki wọn si ṣelede lẹyin ẹni to doloogbe.
Ẹ wo awọn ọkọ bogini ti Ginimbi Genius Kadungure ni ko to jade laye
Ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ni Ginimbi nigba ti o di ilumọọka kaakiri orilẹede Zimbabwe nigba ti o bẹrẹ idokowo epo rọọbi ati afẹfẹ gaasi liquefied petroleum (LP).

Oríṣun àwòrán, Genius Ginimbi Kadungure/INSTAGRAM
Igba naa lo ti si bẹrẹ si ni ṣe ayẹyẹ diẹdiẹ, ko to wa di gbajugbaja lawujọ.
Laarin awọn ọdun wọnyii ni Ginimbi ra awọn ọkọ bogini nla nla, ti yoo si fi si oju opo rẹ lori ayelujara ti ọkọ tuntun ba de.
Ki o to ku, o ṣẹṣẹ ra ọkọ Lamborghini Aventador, to ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ohun amuṣere tuntun.
Bi o tilẹ jẹpe ileeṣe BBC ko le e fi idi iroyin naa mulẹ, amọ Ileeṣẹ iroyin Times Live fi awọn ọkọ to ni silẹ ko to ku lede bayii;
- Rolls-Royce Ghost (2016 model)
- Rolls-Royce Ghost (2020 model)
- Rolls-Royce Wraith (eleyii to wa ninu rẹ nigba ti ijamba ọkọ ṣẹlẹ)
- Bentley Continental GT (2014 model)
- Bentley Continental GT W12 (2020 model)
- Bentley Bentayga
- Bentley Mulsanne
- Lamborghini Aventador S Coupe
- Ferrari 488 Spider
- Mercedes G Wagon Brabus (2016 model)
- Mercedes G Wagon G63 (2020 model)
- Range Rover Vogue Autobiography (2019 model)
- Range Rover Sport SVR (2019 model)
- Range Rover Sport Lumma (2017 model)
- Range Rover Sport (2018 model)
- Range Rover Velar (2018 model)
- Mercedes-Benz S Class (2014 model)
- Mercedes-Benz S Class (2019 model)
Awọn ọkọ bogini ti wọn ṣe akọsilẹ rẹ wọnyii ko mọ ọkọ bọgini BMW loriṣiriṣi, to di mọ Jaguar ati Lexus.
Wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó ti ṣe àríyá aláṣọ funfun kó tó kú
Ginimbi Genius Kandungure ni ọpọ eeyan mọ si ọdọmọde olowo to maa n se ọpọ ayẹyẹ olowo nla loore koore, ko to dagbere faye.
Ni ọdun 2010, Ginimbi se apejẹ alagbara kan fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, to si ni dandan ni kawọn alejo ti oun pe wọ asọ funfun wa sibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Ginimbi Genius Kadungure
Ilu Harare, ni orilẹede Zimbabwe si lo ti se ayẹyẹ ọhun, lati igba naa si ni o ti di eewọ fun ẹnikẹni lati wọ asọ to yatọ si asọ funfun lọ sibi ayẹyẹ ti Ginimbi ba se.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mọ́kànlá ká nítórí pé ìyàwó fí ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀
- Ta ni olóògbé Jerry Rawlings, tí wọ́n fún ní àlàjẹ́ 'Junior Jesus'
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l‘Eko
Ni ọdun meji lẹyin eyi, eyiun lọdun 2012, Ginimbi tun se ayẹyẹ ọjọ ibi olowo nla miran, amọ orilẹede Boswana lo lọ nigba naa.
Ko tan sibẹ o, lọdun 2013, Ginimbi tun se ayẹyẹ ọlọjọ mẹta ninu ile rẹ to kọ si abule rẹ , Domboshava, eyi to fi n wẹ ile awodamiẹnu to kọ si agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Ginimbi Genius Kadungure
Bakan naa lọjọ kẹwaa osu kẹwaa ọdun taa wa yi, ọdun 2020, ọdọmọde olokoowo naa tun sami ọjọ ibi rẹ, to si tun fi iwe ipe sita lati pe ọpọ alejo ni janti rẹrẹ.
Nibẹ lo tun ti kede pe apejẹ alasọ funfun ni ayẹyẹ ọjọ ibi oun naa, ẹnikẹni ko si gbọdọ wọ asọ miran wa sibi inawo oun yatọ si asọ funfun.
Ayẹyẹ naa, to pe osu kan ati ọjọ mẹta gbako lonii, lo jẹ ohun ti ọpọ eeyan si n sọrọ lori rẹ nipa bo se larinrin to, amọ ọlọjọ ibi naa, Ginimbi ti jade laye.
O wa se ni laanu pe iku ijamba ọkọ lo da ẹmi ọdọmọde olowo, to nifẹ asọ funfun naa legbodo lati ipasẹ ijamba ọkọ kan to se agbako rẹ ninu ọsẹ yii.
Ọ̀dọ́mọdé olówó, ẹni ọdún 36 sọ̀rọ̀ sílẹ̀ pé aṣọ funfun ni káwọn èèyàn wọ̀ wá síbi òkú òun

Oríṣun àwòrán, Ginimbi Genius Kadungure
Ọlọla to gbajumọ lorilẹede Zimbabwe, Ginimbi Genius Kadungure ti sọ fun awọn ebi rẹ, bo ṣe fẹ ki wọn ṣin oku rẹ ki o to papoda.
Awọn mọlẹbi rẹ lo fi lede pe, ki o to papoda ni o ti fi ọrọ ikẹyin silẹ lori bi o ṣe fẹ ki wọn sin oku rẹ.
Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kọkanla, ọdun 2020 ni Ginimbi Genius Kadungure papoda ninu ijamba ọkọ to waye ninu ọkọ bọgini rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Okú àwọn tó kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́nà Benin ní ọlọ́pàá ń rù wá sílé ìwòsàn Ore
- Ta ni olóògbé Jerry Rawlings, tó darí Ghana fún ogún ọdún?
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Sé ọlọ́pàá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ tàbí fìyà jẹ ọ́ láìtọ́, wo bó ṣe fi ẹjọ́ rẹ̀ ṣùn l‘Eko
- Èsì ìjọba UK rèé lórí ìwé ẹ̀sùn ọmọ Nàìjíríà lórí ìkọlù ìjọba sáwọn olùwọ̀de ENDSARS
- Wo bó ṣe le bèèrè láti ṣàtìpó ní Canada bí DJ Switch
- Ẹ gbà mí o! Ìjọba Buhari ní kí Ológun pa mí láàrin ọjọ́ kan péré - Omoyele Sowore
- Bí nǹkan bá ṣe mí àtàwọn ọmọ mi, Aláàfin ni kẹ mú o - Olorì Anu figbe ta
- Ọ̀pọ̀ òkú fọ́nkálẹ̀ nílé ìwòsàn ìjọba ní Ore, ìpayà àjàkálẹ̀ àrùn gbàlú kan
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
Ginimbi Genius Kadungure sọ fun awọn ẹbi rẹ wi pe aṣọ funfun ni ki gbogbo eniyan to ba fẹ wa si ibi isinku oun wo.
Eyi ko ṣẹyin bi gbajumọ naa ṣe ma n wọ aṣọ funfun nigba to wa laye.

Oríṣun àwòrán, Ginimbi Genius Kadungure
Awọn ẹbi rẹ ni ile nla rẹ ni wọn yoo sin Ginimbi Genius Kadungure si ni Ọjọ Satide , ọsẹ yii
Bakan naa ni ẹgbọn rẹ obinrin, Abilẹkọ Juliet fi lede pe, aburo oun ti ma n sọ wi pe ohun fẹ ki aye gbọ ki ọrun mọ nigba ti o ba kuro laye, ti wọn ba fẹ sin oku oun.
O ni ki wọn ma fi waduwadu sin oku oun, ki wọn ṣe e ni ṣiṣẹ n tẹle.
Bakan naa lo ni Ginimbi Genius Kadungure fi oun silẹ pe, awọn ọrẹ oun to wani oke okun gbọdọ peju pesẹ si ibi isinku oun.

Oríṣun àwòrán, Ginimbi Genius Kadungure
'O ni gbogbo eniyan gbọdọ wọ aṣọ funfun naa ni ọjọ gan an ti wọn ba fẹ sin oku oun, ki wọn si fun awọn eniyan laaye lati peju pese sibẹ.'
Nibayii, Juliet ni awọn ti ta atibaba nla meji si iwaju ita ile baba awọn nibi ti isinku naa yoo ti waye, ki wọn to lọ si itẹ rẹ ninu ile nla rẹ ni Ọjọ Satide.
Bakan naa lo fikun wi pe awọn elere lorisirisi lo ti wa ni kalẹ , lati fi orin aladun tẹ awọn ololufẹ Ginimbi Genius Kadungure lọrun, lati ṣe idaro ẹni ire to lọ.
Ti ẹ ko bamọ, Ginimbi Genius Kadungure to doloogbe naa, dabi olowo Hushpuppi ni Naijiria.
Ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa Ginimbi Genius Kadungure to doloogbe:
- Ọjọ Isinmi ni Ginimbi Genius Kadungure jade laye ni agbegbe Borrowdale, Harare, Zimbabwe
- Ọmọ ọdun mẹrindinlogoji ni Ginibi ko to jade laye
- Ọjọ kẹwaa, Oṣu Kẹwaa, ọdun 1984 ni wọn bi
- Ginibi lo ni ileeṣẹ Piko Trading Holdings, Genius Foundation, Club Sankayi (AKA Dreams Nightlife Club)
- O kawe gboye imọ eto ọrọ aje lati ileewe giga Great Zimbabwe University, lorilẹede Zimbabwe
- Harare, lorileede Zimbabwe ni wọn ti bi Ginibi, amọ Govan Mbeki, Mpumalanga, lorilẹede South Africa ni oun gbe ko to papoda
- Lati ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni Giniba Kadungare ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ oniṣowo, to si ma n lọ pin afẹfẹ gaasi fun awọn eniyan ninu ile wọn
- Ti o tilẹ jepe, awọn eniyan ko le sọ pato bi o ṣe lọwọ si, amọ dukia rẹ to USD $10 milliọnu si USD $100 milliọnu
- Ni ọdun 2009, 2014, 2016 ati 2018 ni wọn fi ẹsun iwa jẹdugujẹra kan Giniba pẹlu aisan owo ori bo se yẹ, amọ o ni oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.

















