Yoruba Film: Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́fà tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe láti kékéré

O ti ṣe oníruuru àwọpn eré títà, bíi ìgè àdùbí, Oshodi Oke, Narrow Path, ìjà ọmọde.

Bí eré bí àwàdà, gbogbo àwọn ọmọ kekere aná ninu isẹ tiata lede Yoruba ti wá dàgbà bayìí, àgbà bọ̀ wọ́n ni, ibi ti àgbà bá wà, ibẹ̀ náà ni ọmọde yoo ti dàgbà báa níbẹ̀.

Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ kéékèké tó ti di gbájúgbajà ìlúmọ̀ọ̀ká, òṣèré Nollywood báyìí ri, ti wọn bẹrẹ ere sise ni majesin amọ ti wọn ti di agba ọjẹ bayii.

Ní àsìkò kan tàbí òmíràn, àwọn ọmọdé òṣèré yìí ló kúrò lójú ìwòràn tí wọ́n sì lọ gbájúmọ́ ètò ẹ̀kọ́ wọn ki wọ́n tó tún padà wa sinu ere.

Ki a ba le ni yin niran nipa wọn, ni BBC Yoruba fi ṣe àgbéyẹ̀wò mẹfa nínú àwọn òṣèré tí wọn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àṣejẹ wọ́n yìí láti ọmọde piniṣin.

1. Funke Akindele Bello (Jenifa):

Nollywood: Àwọn òṣèré Yorùbá méje tó wọ inú òṣèré láti kékéré

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún 1998 ni Funke Akindele ti bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣe eré orí ìtàgé, síbẹ̀, ọdún 2002 ni ó tó di ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré lásìkò tó kópa nínú síníma tí àjọ ìsọ̀kan àgbáyé lórí ìkàniyan sagbátéru rẹ̀ (UNPF) ti wọn pe àkọ́lé rẹ ni ‘I Need to Know’.

Ní àsìkò yìí tó kópa nínú eré "I need to Know", Funke Akindele ti kawe gboye imọ ijinlẹ nínú òfin lọ́dún 1998.

Láti ọdún 2002 ní orúkọ rẹ ti di pàtàkì igun ilé nínú eré orí ìtàgé.

Funke Akindele Bello ti ṣe ọpọlọpọ eré tiata, lára rẹ ni orúkọ ti ọ̀pọ̀ ènìyàn ń pè é, eyiun Jẹnifa kẹn, Aiyetoro kén.

Amọ nibayii, ere Jenifa (Jenifa Diary) ti di ere agbelewo lori tẹlifisan, eyi to n waye lati igbadegba.

Ní báyìí, Funke Akindele ti di Òǹkọ̀tàn, òṣèré ati olùdarí eré, to si ti tun gbe ọ̀pọ̀ sinima jade pẹlu.

2. Opemipo Bamigbopa:

Nollywood: Àwọn òṣèré Yorùbá méje tó wọ inú òṣèré láti kékéré

Opemipo ti gbogbo ènìyàn mọ si Maradona, bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe sinima láti igba to ti wa ni ọmọ ọdún mẹfa.

Sùgbọ́n nígbà tó ṣe díẹ̀, ó kúrò láti lọ mójú tó ẹkọ́ rẹ̀, sùgbọ́n ní báyìí, ó ti pada sí idí sinimá.

O lọ si Fasiti ilú Eko nibi to ti kẹkọọ gboye imọ nípa ètò ìrìnà

O ti kópa nínú eré agbéléwò "One Love", Opa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Opemipo, nínu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe, lo ti salaye pe, nítori pe oun maa n tẹ̀lẹ́ ìyá òun lọ si ibi àyéwò lati kópa fun eré ni wọ̀n ti fa òun sínú eré tíátà.

Ní báyìí ó ti pada sí idí sínimá lẹ́yìn to pari ètò ẹkọ rẹ̀.

3.Kabirat Kafidipe:

Nollywood: Àwọn òṣèré Yorùbá méje tó wọ inú òṣèré láti kékéré

Ọdun 1999, ni Kabirat bẹ̀rẹ̀ si ni ṣeré tíátà, èyí ti àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ " The Handkerchief‘ ti Bayo Adebowale ṣe, ti Tunde Kelani si dari rẹ̀.

Sùgbọ́n inú fiimu Saworo Ide gan ní ogo rẹ̀ ti jáde lọ́dún 1999.

Fasiti Olabisi Onabanjo ni Kabirat ti kawe gboye ninu ìmọ̀ ìròyìn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Laipẹ yìí ló ṣe ọjọ́ ìbí ogójì ọdún, fún ọ̀pọ̀ ọdún ló fi kúro lójú iworan síníma, sùgban ó ṣe eé agbélewo kan to pe akọle rẹ̀ ni Bintu.

Ó ti kópa nínú onírúurú àwọn eré míràn pàápàá jùlọ èyí ti Tunde Kelani ba ṣe.

Samuel Olasehinde

Nollywood: Àwọn òṣèré Yorùbá méje tó wọ inú òṣèré láti kékéré

Samuel Olasehinde ti gbogbo ènìyàn mọ si ọmọ Ajirebi, bẹ̀rẹ̀e ré tíátà lásìkò to wà ni ọmọ ọdún márùn.

Arowolo ni fíìmù àkọ́kọ́ ti Samuel ṣe, èyí si lo mu gba àmi ẹyẹ.

O ti ṣe oníruuru àwọn eré títà, bíi ìgè àdùbí, Oshodi Oke, Narrow Path, ìjà ọmọde.

Nínú ọdún 2018, Samuel lọ sìnrú ilú gẹ́gẹ́ bi agunbanirọ, tí ó sì n pinnu láti pada sínú eré.

Ọmọ òṣèré ni, baba rẹ̀ si ni gbogbo ènìyàn mọ si Pa Ajirebi.

Azeez Ijaduade:

Nollywood: Àwọn òṣèré Yorùbá méje tó wọ inú òṣèré láti kékéré

Ọmọ òṣèré tíátà Yoruba ni Azeez jẹ́, Waheed Ijaduade, tawọn eeyan mọ si Dimeji si ni baba rẹ, ti ó si ti bẹ̀rẹ̀ eré tíátà láti ìgbà tí ó ti wà ni ọmọ ọdún méje.

Oun ló ṣe ere Iru Ẹsín, Jensinmi, Ọmọ Nla eyi tí òkíkí rẹ̀ gbà ilú kan, ní bi ọgbọ̀n ọdún sẹyin.

Títí di àsìkò yìí, ó sí wà nínú eré tíátà tí ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀ eré, bakan náà lo n dari ere, tó sì tún ń kọ itan pẹlu.

Gabriel Afolayan:

Nollywood: Àwọn òṣèré Yorùbá méje tó wọ inú òṣèré láti kékéré

Gabriel Afolayan jẹ ọmọ gbajúgbaja òṣèré, Adeyemi Afolayan ti gbogbo ènìyàn mọ sí Ade Love.

Gabriel Afolayan bẹ̀rẹ̀ eré tíátà kí ó tó pé ọmọ ọdún mẹ́wàá sùgbọ́n òkíkí rẹ kò kan títí ìgbà tó fi fàrahàn nínú eré agbéléwò ‘Madam Dearest’, ti Tade Ogidan ṣe lọdun 2006.

Ó ti farahan nínú eré agbeléwò Wale Adenuga, (Super Story).

O ṣe Fopawọn ni ọdún 1990 ati àwọn eré yìí:

Glitterati - 2013

The Antique - 2014

Ojujo - 2014

7 Inch Curve - 2015

Okafor's Law - 2016

A Love Like This - 2016

King Invincible - 2017

Tatu - 2017

Something Wicked - 2017

Alakada Reloaded - 2017

Hanatu - 2017

Kasala - 2018

Power of 1 - 2018

Philander - 2018

Gold Statue - 2019

Lugard, The Movie - 2019

For Maria - 2019

Oracles Online - 2019

Coming from Insanity - 2019

Alubarika - 2019

Codewilo - 2019

Latana 1 and 2 - 2019

Sharo - 2019

Say Mama - 2019

Ilú Eko ni wọn bi Gariel Afolayan sí, sùgbọ́n ọmọ ilú Agbamu ní ìpínlẹ̀ Kwara ni.