Nollywood ń mú kí òògùn owó àti ìjínigbé gbilẹ̀ síi- Fashola

FASHOLA

Oríṣun àwòrán, Google

Minisita to n ri si ọrọ iṣẹ ode ati ileegbe to tun ti jẹ gomina ipinlẹ eko tẹlẹ ri, Babatunde Fashola ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn oṣere Naijiria ṣe maa n ṣafihan awọn ere bii oogun owo.

Fashola ni ki wọn dẹkun ki wọn maa sọ iru itan bẹẹ tori pe o ni oogun owo kii ṣe nkan to yẹ keeyan maa tẹ pẹpẹ.

Bo tilẹ jẹ wi pe awọn ere itage ati agbelewo ti awọn oṣere nollywood maa n gbe sita maa n da ni lara ya pẹlu oniruuru nkan to wa ninu ẹ ti ọrọ ogun owo si maa n wọpọ nibẹ, Fashola ni ko tọ.

Ọgbẹni Fashola fi ọrọ yii lede nibi eto idanilẹkọ kan ti ẹgbẹ to n jẹ "United Action for Change" ṣe agbekalẹ rẹ nibi eyi ti wọn ti sọrọ nipa abo ara ilu nipasẹ awọn ere Nollywood.

Wọn ni o lee maa ru ina ijinigbe soke, wọn ṣe apẹrẹ awọn eeyan ti Ọlọpaa ti gbamu pẹlu ori ọmọ eniyan atawọn ẹya ara mii pẹlu erongba ati fi ṣe ogun owo.

Fashola nibi to ti n sọrọ ni asiko ti to wayi ki awọn oṣere atawọn atawọn to wa nidi ofin ṣiṣe yi itan wọn pada lati le gba ẹmi alaiṣẹ la lọwọ iparun.

Fashola ni "awọn kan gbagbọ pe bi o ba ri ori eeyan tabi ẹya ara obinrin, wọn lee yi wọn pada si owo. Eyi kii ṣe ootọ o. Bi ẹ ba si ri ẹni to ni oun gbagbọ ninu rẹ ti wọn ti ri i ko ṣẹlẹ, wọn ni wọn pe ni gbogbo ẹ.

Àkọlé fídíò, Nollywood: Bẹbẹ ń lọ ní ibùdó yíya sinimá Àgbésọrísùn

Ẹwẹ, awọn ere idanilaraya ti jẹ ki awọn eeyan nigbagbọ ninu rẹ koda titi dori ayelujara.

Fashola ni "bawo ni ori eeyan ṣe le mu owo jade? Iwe ti eeyan ṣe lo n di owo, wọn a ko iwe sinu mọṣíìǹì lati tẹ̀ ẹ́ jade gẹgẹ bi ohun ta n ri bii owo, ọna yẹn nikan dẹ ni owo ti n wa".

Ibi ti iṣoro wa ni ohun ti awn eeyan n yan lati gbagbọ ninu rẹ. Fashola ni bi a ba wo iye awọn to ti nu nipasẹ ijinigbe tori awọn kan ṣa gbagbọ pe o n ṣiṣẹ.

O ni awọn Ọlọpaa gan le sọ iye awọn eeyan ti wọn ti ka ori gbigbẹ ati tutu mọ lọwọ to fi mọ ẹya ara eniyan. "Ilana igbagbọ yii gbudọ kuro nilẹ!".

Nitorinaa Fashola ni "gbogbo wa atawọn to n ṣe fiimu gbudọ yi itan pada ki a si bẹrẹ si ni ta itan tuntun pe iwe beba ni wọn fi n tẹ owo ninu mọṣiini kii ṣe nipa na miiran bii ogun owo ṣiṣe.

Bakan naa o tabuku ba ibẹru to gbode kan lọdun to kọja nigba ti iroyin n tan pe awọn ọdaran ori ayelujara tun n ji awọtẹlẹ awọn obinrin lati fi ṣe owo.

Fashola ni irọ ni ko le ri bẹ́ẹ̀, bawo ni iyẹn ṣe fẹ ṣẹlẹ̀? Ki ni ibaṣepọ to wa laarin owo beba ati pata olowu abi nikẹni ti ri owo ti wn fi owu ṣe ri?

O tẹnu mọ ọ pe "gbogbo awa taa ni ọna ati ṣe ayipada atawọn alaṣẹ gbudọ fẹsẹ wọn mulẹ lati rii pe ayipada de ba iru igbagbọ yii lọkan awọn eeyan".