Domestic Violence: Wo ìlú tí wọ́n ti gbàgbọ́ pé bí ọkọ bá nà ẹ, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ gan ni

Àkọlé fídíò, 'Lẹ́yìn tó fi ọ̀bẹ halẹ̀, òfin kò gbà kí n sọ̀rọ̀, àfìgbà tí ọkọ mi fi àáké gé mi lọ́wọ́'

Magarita sọ nkan toju rẹ n ri ninu ile fun BBC.

O ni lasdiko ti oun wa yii, o tẹ oun lọrun ki oun ṣi ni ọwọ oun ṣugbọ́n ko lee ri bẹẹ fun un mọ.

Òfin Russia sọ pé àwọn ọ̀daràn fún ìgbà àkọ́kọ́ tí kò dá ọ̀gbẹ́ púpọ̀ sí ẹnìkejì lára kò leè dédé lọ sẹ́wọ̀n.

Eyi lo fa a to fi n ni ifarada gbogbo iwa ti ọkọ rẹ kọkọ n wu si i titi to fi wa di pe o ṣe manigbagbe yii.

Bi o tilẹ jẹ wi pe kii ṣe gbogbo eniyan lo fara mọ iru ofin bayii. Iṣẹlẹ yii ti wa sọ Magarita di gbajugbaja lọdọ awọn oniroyin. Koda o ti ṣe iwe jade lori iriri rẹ