Amotekun: Àwọn adájọ́ àgbà ilẹ̀ Yoruba dá àba kí ìkọ̀ Amotẹkun lo ìbọn

Oríṣun àwòrán, @DAWNCommission
Awọn adajọ agba ni ẹkun iwọ oorun Naijiria ti da a laba ki awọn kọọkan ni ikọ Amọtẹkun ma a gbe ibọn.
Arakunrin Seye Oyeleye to jẹ alakoso ikọ Dawn Commission lo fi eyi han fun BBC Yoruba.
O ni awọn adajọ agba da aba yii lasiko ti wọn ṣe ijiroro lori bi ikọ Amọtẹkun yoo ṣe ri ati ọna ti wọn yoo gbe e gba lati ri i pe ikọ naa ri iṣẹ wọn ṣe bi iṣẹ.
- BBC tún gbé e dé! Wọ́n tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun àti SARS káàkiri Nàìjíríà
- Èèyàn mẹ́wàá tó m bọ̀ láti ìpàgọ́ àdúrà kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó l'Osun
- Àrá sán pa aboyún ìnàkí àtàwọn mẹ́ta míì tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ láyé
- Àwọn fíìmù Nollywood ń mú kí òògùn owó àti ìjínigbé gbilẹ̀ síi - Fashola
- Àwọn ológun ṣíná ìbọn pa Sọjà tó pa èèyàn 26 ní Thailand
- Lẹ́yìn tó fi ọ̀bẹ halẹ̀ mọ́ ọ, ọkọ Magarita fi àáké gé e lọ́wọ́, kí ló ṣe tó bẹ́ẹ̀?
Arakunrin Oyeleye ni aba ọhun yoo fun awọn ọga ati awọn kọọkan ninu ikọ amọtẹkun ni anfaani lati le lo ibọn lati koju iwa ọdaran lawujọ.
Amọ, o fi kun un wi pe aba yii ko lee dofin, aya fi ti ile igbimọ asofin ipinlẹ mẹfẹẹfa ba buwọlu, ti ijọba apapọ si fun wọn ni aṣẹ license lati le gbe ibọn dani.
Alakoso ikọ Dawn Commission fi kun un wi pe ko si ẹni ti ko le gbe ibọn ti ijọba ba ti fun wọn ni aṣẹ lati gbe e.
Ẹ má ṣe fàsẹ́yìn rára o lórí ikọ̀ àmọ̀tẹ́kùn - Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin rọ àwọn gomina
Ile igbimọ Asofin ni iwọ-oorun Naijiria ti ti ṣeleri lati rii wi pe awọn ṣe kanmọ kanmọ ki ikọ amọtẹkun tete bẹrẹ iṣẹ.
Wọn sọ eyi lati fi ran awọn gomina leti ki wọn tete gbe igbesẹ lori eto abadofin naa.

Oríṣun àwòrán, @toluogunlesi
Ọjọ Kẹsan, Osu Kini, ọdun 2020 ni awọn gomina ẹkun iwọ oorun Naijiria parapọ lati ṣe igbekalẹ ikọ ti yoo gbogun ti eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.
Amọ ni ọjọ diẹ sẹyin ti wọn ṣe ifilọlẹ ikọ amọtẹkun ni olotu eto idajọ ijọba ati minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami kede wi pe ikọ amọtẹkun ko ba ofin mu.
Lati igba naa, ko fibẹẹ tii si ohun pato ti a lee ri gbamu lati sọ pe eto ikọ Amọtẹkun naa ti fẹ gberasọ lẹkun Iwọ Oorun.
Abẹnugan ile igbimọ asofin ipinlẹ Osun, Timothy Owoeye sọ wi pe awọn ti ṣe tan lati ge isinmi awọn kuro ki awọn baa le pada si ẹnu iṣẹ, ki wọn le tete ṣiṣẹ lori abadofin naa.
Bakan naa ni ipinlẹ Oyo sọ wi pe awọn n ṣiṣẹ le abadofin Amọtẹkun lọwọ ki wọn ba le pari rẹ laarin ọsẹ meji.

Oríṣun àwòrán, @toluogunlesi
Ninu ọrọ tirẹ, Abẹnugan ile igbimọ asofin ni ipinlẹ Ogun sọ wi pe awọn naa n sa ipa awọn lati ri wi pe gbogbo rẹ waye ni akoko ti wọn fi si.
Ẹwẹ, ipinlẹ Eko ko le e sọ igba ti awọn yoo le ṣe abadofin naa tan, amọ awọn ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ.













