Ìdí rèé tí Man U ṣe já Odion Ighalo sílẹ̀ nínú ìgbáradì rẹ̀ tí yóò wáyé ni Spain

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Odion Ighalo ko ni ba awọn akẹgbẹ ni Manchester United kopa ninu igabradi wọn ti yoo waye lorilẹ-ede Spain nitori ibẹru aisan Coronavirus.
Ẹlẹsẹ ayo ọhun darapọ Manchester United lati ẹgbẹ agbabọọlu Shanghai Shenhua lorilẹ-ede China, nibi ti aisan naa ti kọkọ bẹrẹ.
Wọn ni ti Ighalo ba tẹlẹ awọn akẹgbẹ rẹ lo si Spain, o ṣeṣe ki ileeṣẹ aṣọbode ilẹ Gẹẹsi ma gba a laaye lati pada si orilẹ-ede naa nitori ibẹru aisan ọhun.
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn "Occupy Lagos" ń fẹ́ kí ìjọba Eko dá Okada àti Maruwa padà
- 'Ẹ jọ̀ọ́, a ò fẹ́ gbọ́ òfófó ìròyìn mọ́ pé àbúrò mi gún bàbá àti ìyá mi pa, ó ti tó gẹ́!'
- 'Kìí ṣe 'ibà Lassa' ló padà wọ ìpínlẹ̀ Benue', mọ̀ nípa ààrùn tó ti pa èèyàn 15 ní Benue
- Àdó olóró tí wọ́n fi ń pa iná àdó olóró míì ló gbiná l'Ekiti - Ọlọ́pàá Ekiti
Akọnimọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer sọ fun awọn oniroyin pe yoo jẹ didun inu Ighalo lati darapọ mọ awọn akẹgbẹ rẹ.
O ni "Nitori bi ọrọ ṣe ri lọwọ yii ni China, ko da wa loju pe wọn yoo gba Igahlo laye lati pada wọ ilẹ Gẹẹsi to ba lee jade."
Solskjaer tẹsiwaju pe, nitori naa, Ighalo yoo ṣi wa ni ilẹ Gẹẹsi fun akoko yii.
Akọnimọgba naa ni igbesẹ ọhun jẹ fun igba diẹ lati le mọ ibi ti ọrọ aisan Coronavirus naa yoo yọri si.
Aisan coronavirus ọhun to bẹrẹ lorilẹ-ede China ti mu ọpọlọpọ ẹmi lọ, ti awọn onimọ ijinlẹ si ti n wa ojutu sii.
- Mí ò bẹ̀bẹ̀ fún oyè igbákejì alága APC kí wọ́n tó ó fún mi - Abiola Ajimobi
- Ilé ẹjọ́ tó ga jù ní kí gómìnà tẹ́lẹ̀, Jolly Nyame lọ fẹ̀wọ̀n ọdún 12 ṣara rindin
- Ìjọba Eko sọ pé ká má tọrọ bárà mọ́, wọ́n tún fòfin de kẹ̀ẹ̀kẹ́ tá a fi n ṣiṣẹ́ - Àwọn àkàndá ẹ̀dá
- Wo ọ̀nà to le gbà tọ́jú arúgbó rẹ lásìkò tí ọpọlọ wọn bá kù díẹ̀ lọ́jọ́ ogbó












