Ilé ẹjọ́ tó ga jù ní kí gómìnà tẹ́lẹ̀, Jolly Nyame lọ fẹ̀wọ̀n ọdún 12 ṣara rindin

Jolly Tavoro Nyame

Oríṣun àwòrán, EFCC

Àkọlé àwòrán, Jolly Nyame jẹ gomina ipinlẹ Taraba laarin ọjọ kọkandinlọgbọ̀n, oṣu karun, ọdun 1999 si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun, dun 2007.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ to gajulọ ni Naijiria ti dajọ lọjọ Ẹti pe ki gomina nigba kan, Jolly Nyame o lọ si ẹwọn ọdun mejila.

Ile ẹjọ naa dajọ ẹwọn fun nitori ẹsun iwa ibajẹ, ati mago-mago to ṣe pẹlu owo ilu nigba to fi jẹ gomina. Owo naa to o biliọnu kan aabọ Naira (1.6bn).

Ile ẹjọ ko tẹ mi lọrun ti kọkọ ni ko san owo itanran dipo ẹwọn, ṣugbọn igbimọ ẹni maarun to da ẹjọ naa, ti Onidajọ Mary Odili jẹ olori fun, wọgi le e.

Ile ẹjọ giga nilu Abuja sọ pe ki Nyame, to ti jẹ gomina ipinlẹ Taraba ri jẹbi ẹsun debi pe ko lọ ṣe ẹwọn ọdun mẹrinla fun jija awọn eniyan ipinlẹ rẹ to ni igbagbọ ninu rẹ kulẹ.

Yoo tun ṣe ọdun meji miran fun fun lilo owo ilu nilokulo; ọdun meje miran fun lilo owo ilu fun ifẹkufẹ ara a rẹ; ati ọdun meji miran fun jibiti lilu.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, lo gbe Nyame lọ sile ẹjọ lori awọn ẹsun naa.

Ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2007, si ni igbẹjọ bẹrẹ lori ẹsun naa nile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni Guru. Ẹsun mọkanlelogoji si ni wọn fi kan an.

Ninu oṣu Karun, ọdun 2018, ile ẹjọ giga ti Onidajọ Adebukola Banjoko to dajọ naa sọ pe gomina nigba kan ri naa jẹbi ẹsun mọkandinlọgbọn.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Onidajọ Banjoko dajọ pe Nyame, to tun jẹ pasitọ, ja awọn eniyan to fi ẹmi igbagbọ sinu rẹ kulẹ lasiko to fi jẹ gomina ipinlẹ Taraba, lasiko to na ọtalerugba din mẹwa miliọnu Naira (250m) ni inakuna.

Ajọ EFCC tun sọ loju opo ayelujara Twitter rẹ pe Onidajọ Banjoko tun sọ pe Nyame jẹbi ẹsun pe o lu jibiti miliọnu marundinlaadọsan Naira (165m).

Bi nkan ṣe ri yii, o ṣeeṣe ki Nyame to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgọta bayii o pe ẹni ọdun mọkanlelssdọrun ko to ṣẹwọn tan.