Ẹ̀ṣùn àjẹbánu: Alamieyeseigha ni gómìnà àkọ́kọ́ tó lọ sẹ́wọ̀n láti ọdún 1999

Foyose, Ibori ati Dariye

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Ayodele Fayose

Lati igba ti orilẹede wa Naijiria ti bẹrẹ isejọbna alagbada pada lọdun 1999, ọpọ ojo lo ti rọ, ti ilẹ ti fi mu taa ba n sọrọ awọn gomina to ti kawọ pọnyin rojọ nidi ẹsun iwa ajẹbanu.

Ta ba si ni ka maa ka ni eni, eji, ẹta, a ka to ori aadọta tabi ju bẹ lọ, ka to dawọ duro.

Ko si si agbegbe kankan ti ọrọ yii yọ silẹ, bawọn eeyan to ti jẹ gomina ri lapa oke ọya se n kawọ pọnyin, naa ni awọn ti ẹkun guusu Naijiria n se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Wọn ko ni nkan ṣe fún ipinlẹ Ọyọ ni' #BBCGovDebate

Alaye si ree nipa awọn eeyan to ti jẹ gomina ri, ti wọn ti jẹjọ̀ nile ẹjọ lori ẹsun ajẹbanu.

Lati igba ti orilẹede wa Naijiria ti bẹrẹ isejọbna alagbada pada lọdun 1999, ọpọ ojo lo ti rọ, ti ilẹ ti fi mu taa ba n sọrọ awọn gomina to ti kawọ pọnyin rojọ nidi ẹsun iwa ajẹbanu.

Jolly Nyame:

Gomina ipinlẹ Taraba nigba kan, ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja ju si ẹwọn ọdun mẹrinla fun ẹsun pe o da owo ipinlẹ naa, eyi to to biliọnu kan le diẹ́ (1.64billion) sapo ara rẹ.

Bakan naa ni ile ẹjọ sọ pe, ko tun da owo to ji ko ọhun pada si apo ijọba. Oṣu Karun, ọdun 2007 ni ajọ EFCC fi ẹsun kan an.

Wọn fi ẹsun kan Nyame pe, o dari owo naa lati inu apo asunwọn ipinlẹ rẹ si apo ile isẹ kan, Saman Global lati ra awọn irinṣẹ ati eroja ikọwe lọọfisi, amọ alọ owo ni wọn ri, wọ̀n ko ri aabọ.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan an pe, o fi ọna eeru ko ọrọ jọ fun ara rẹ, to si ja ireti awọn araalu kulẹ.

Amin iyasọtọ kan

Joshua Dariye:

Joshua Dariye

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwọn ọdun mẹrinla ni ile ẹjọ ju Joshua Dariye si, ẹni to ti fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ Plateau.

Ẹsun ti wọn fi kan ni pe, o dari biliọnu kan o le diẹ (1.16 billion) owo idagbasoke ayika si apo ileeṣẹ to jẹ tiẹ, Ebenezer Ratnen ventures, lasiko to fi jẹ gomina lọdun 1999 si 2007.

Ẹsun mẹtalelogun ni ajọ EFCC fi kan an, ti adajọ to gbọ ẹjọ rẹ si sọ pe o jẹbi mẹẹdogun ninu rẹ.

Lẹyin ọdun mẹwa ni wọn to o da ẹjọ rẹ. Ọdun 2007 ni ajọ EFCC fi ẹsun kiko owo ipinlẹ Plateau pamọ kan Dariye. Ọdun 1999 si 2007 ni Dariye fi jẹ gomina nipinlẹ naa.

Amọ ṣaa, Dariye pe ẹjọ kotẹmilọrun, ile ẹjọ si din ẹwọn rẹ si ọdun mẹwa.

Amin iyasọtọ kan

James Bala Ngilari:

Gomina ipinlẹ Adamawa, James Bala Ngilari, naa lọ si ẹwọn ọdun maarun lai san owo itanran lori ẹsun pe o lu ipinlẹ rẹ ni jibiti miliọnu mẹtadinlaadọsan naira.

Amin iyasọtọ kan

Lucky Igbinedion:

Gomina ipinlẹ Edo nigba kan, Lucky Igbinedion ni wọn dajọ ẹwọn oṣu mẹfa fun, fun pe o ji miliọnu mẹẹdọgbọn naira owo ipinlẹ rẹ, sugbọn o pada duna-dura lati san miliọnu mẹta aabọ Naira owo itanran.

Ile ẹjọ si fi silẹ.

Amin iyasọtọ kan

James Ibori:

Ẹwọn ọdun mẹtala ni ile ẹjọ kan ni London ju James Ibori si, ẹni to ti fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ Delta si.

James Ibori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ naa sọ pe, o jẹbi ẹsun kiko ọtalerugba miliọnu Naira owo ipinlẹ rẹ.

Oun si ni oloṣelu akọkọ lati Naijiria to gba idajọ ẹwọn nilẹ okeere fun ẹsun jiji owo ilu.

Igba naa si ni igba kẹta ti Ibori gba idajọ ẹwọn fun ole jija.

Amin iyasọtọ kan

Diepreye Alamieyesegha:

Bakan naa ni Oloogbe Diepreye Alamieyesegha to jẹ gomina ni ipinlẹ Bayelsa gba idajọ ẹwọn ọdun meji, lẹyin ti wọn fi ẹsun kan an pe, o ji owo to din diẹ ni biliọnu mẹrin Naira lasiko to fi jẹ gomina.

Ati pe o parọ ninu kikede dukia rẹ.

Ile ẹjọ gbẹsẹ le ile rẹ mẹrin, miliọnu mọkandinlọgbọn Pọun, ipin idokowo towo rẹ jẹ biliọnu kan Naira nile ifowopamọ ati awọn owo mi i.

Alamieyeseigha ni gomina akọkọ to lọ sẹwọn fun iwa ibajẹ lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada si iṣejọba awaarawa lọdun 1999.

Amin iyasọtọ kan

Ayọdele Fayoṣe:

Gomina nigba kan fun ipinlẹ̀ Ekiti n jẹjọ lọwọ fun ẹsun kiko owo ipinlẹ Ekiti si apo ara rẹ, ati pe o gba owo ti ko tọ ọ lati ṣe ipolongo ibo gomina to gbe wọle lọdun 2014 lọwọ Sẹnetọ Musiliu Ọbanikoro.

Ni kete ti Fayose kuro ni iṣakoso gẹgẹ bi gomina lọdun 2018 ni ajọ EFCC ti gbe awọn ẹsun naa sita

Oríṣun àwòrán, @Ayodele Fayose

Àkọlé àwòrán, Ni kete ti Fayose kuro ni iṣakoso gẹgẹ bi gomina lọdun 2018 ni ajọ EFCC ti gbe awọn ẹsun naa sita

Ni kete ti Fayose kuro ni iṣakoso gẹgẹ bi gomina lọdun 2018, ni ajọ EFCC ti gbe awọn ẹsun naa sita, ti wọn si gbe ọrọ rẹ lọ sile ẹjọ. Igbẹjọ ṣi n lọ lori ẹsun mọkanla ti wọn fi kan an.