Kò kàn mí, mi ò ní dá sí aáwọ̀ láàrin Gómìnà Kano àti Emir Kano - Buhari

Gomina Ganduje ati Emir Sanusi

Oríṣun àwòrán, OTHER

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ni ayafi tọrọ naa ba fẹ la ẹmi lọ lo ku, loun to le da si aawọ to n waye laarin Gomina Abdullahi Ganduje ati Muhammadu Sanusi keji tii ṣe Emir ilu Kano.

Ọpọlọpọ ipe lo ti n lọ sọdọ aarẹ lati wa ọna bu omi pa'na aawọ hun. Laipẹ yii lọjọbọ ọsẹ ni Emir ilu Ningi bẹ aarẹ Buhari lati gba iṣelu ibilẹ ẹkun ariwa Naijiria kalẹ nipa pe ko tete da si ohun to n ṣẹlẹ laarin Emir ati Gomina.

O ti fi Allah bẹ Buhari tori ki iṣelu ibilẹ ma baa gba itiju lawujọ.

Si ọ̀rọ̀ yii ni oluranlọwọ pataki si aarẹ, Garba Shehu lori iroyin ati r to kan ara ilu fesi wi pe aarẹ Buhari ni"Mo m ipo mi gẹgẹ bi aarẹ".

Aarẹ tẹsiwaju pe nipa ti ofin orilẹede Naijiria, Gomina ipinl Kano naa ni iṣẹ tirẹ tori pe bi ọr ba ti wa ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ (bi eyi to wa ni Kano lọwọlọwọ yii), aarẹ ko lagbara labẹ ofin lati da si i.

Nitori naa, aarẹ ni "nipa ofin ni mo fi wa nibi, ofin ni mo fi ṣe ibura bẹẹ si ni n o duro ti i digbi digbi.

Ẹwẹ, aarẹ fi aridaju han pe nitori alafia ati aabo ọmọ Naijiria ṣe pataki bi o ba si ri ibi ti wọn ti n tẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ ni oun yoo lo agbara oun gẹgẹ bi ofin.