Michael Okhide: Àwọn ọmọ àwọn olóògbé méjèjì kọ̀wé sí aráàlú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé àwọn ọmọ àwọn olóògbé, agbẹjọ́rò Clement Okhide àti ìyàwó rẹ̀, Oluwatoyin Okhide tí ìròyìn ń tàn káàkiri pé ọmọ wọn ọkùnrin gún wọn pa.
Arabinrin "A" to jẹ ọ̀kan lara awọn ọmọ awọn oloogbe ti ko fẹ ki a darukọ rẹ fi omije ba akọroyin BBC sọrọ pe bi awọn ṣe n gbọ iroyin naa kaakiri n ba awọn lọkan jẹ tori awọn ọlọdani oniroyin(Bloggers) ko mọ ohun to ṣẹlẹ gan, wọn kan n kọ gbọ yii sọ yii ni.

O ni itan naa ko fara pamọ mọ pe gigun ati kukuru iroyin naa ni wi pe ọmọ kan gun iya ati baba rẹ pa. Wọn si ti jọ n gbe pẹlu awọn ọmọ wọn ninu ile kan naa fun ọdun mẹtadinlogun bayii lati ọdun 2002 tori ile yii gangan ni ile baba wọn gangan niyẹn ṣugbọn wọn ṣi ni ile mii ti wọn n gbe tẹlẹ.
Ohun to wa lori awọn iwe iroyin kaakiri eyi ti arabinrin "A" naa ni ko si irọ ninu eyi ti awọn iwe iroyin Naijiria tootọ kọ ni wi pe Michael Okhide fi ẹsẹ fẹẹ lẹyin to gun baba ati iya rẹ pa ninu ile wọn to wa ni agbegbe Ejigbo ni ipinlẹ Eko, Naijiria.
Ọmọ ọdun mẹtalelogun naa tun doju kọ arabinrin rẹ to jẹ agunbanirọ nigba to dele ni nkan bii ago marun abọ irọlẹ ṣugbọn arabinrin rẹ ni nigba ti oun wle toun si ti ri ti ẹjẹ fọn kaakiri ile ni ẹru ti n ba oun ati pe o gbọ ohun iya rẹ to n kigbe pe oruk oun lati sọ fun oun pe ko sa lọ.
O kọ lati wọ inu ile gẹgẹ bi Michael arakunrin rẹ ṣe n pe e nitori naa wọn jọ wọya ija ti Michael si ri i gun ni ikun ati ọwọ ṣugbọn ko fi bẹẹ wọ ọ lara tori naa o ri bi sa asala fun ẹmi rẹ.
- Yàtọ̀ f'àwọn mẹ́fà tó m bọ̀ láti ìpàgọ̀ àdúrà tó kú, àjọ FRSC Osun sọ ipò táwọn tó fara pa wà báyìí
- Èèyàn mẹ́fá tó m bọ̀ láti ìpàgọ́ àdúrà kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó l'Osun
- Àrá sán pa aboyún ìnàkí àtàwọn mẹ́ta míì tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ láyé
- Àwọn fíìmù Nollywood ń mú kí òògùn owó àti ìjínigbé gbilẹ̀ síi - Fashola
- Àwọn ológun ṣíná ìbọn pa Sọjà tó pa èèyàn 26 ní Thailand
- Lẹ́yìn tó fi ọ̀bẹ halẹ̀ mọ́ ọ, ọkọ Magarita fi àáké gé e lọ́wọ́, kí ló ṣe tó bẹ́ẹ̀?
- Ẹ má ṣe fàsẹ́yìn rára o lórí ikọ̀ àmọ̀tẹ́kùn - Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin rọ àwọn gomina
Ifọrọwanilẹnu wo pẹlu BBC Yoruba
Arabinrin "A" sọ pe ọrọ naa ti di ọrọ to wa lọwọ Ọlọpaa bayii.
"Fun ọpọlọpọ ọdun laye mi la fi jọ gbe inu ile baba wa papọ gẹgẹ bii idile. Ile wa ni lati nkan bii ọdun mẹtadinlogun ki n to rinrinajo kuro ni agbegbe naa tori naa ṣe ẹ ri i pe ti a lee kọ itan nipa rẹ".
O ni to fi mọ ọmọkunrin naa to gun baba awọn pa lawọn jọ dagba ninu ile ti baba awọn ra yii ti awọn obi awọn si tọ daadaa bi Ọlọrun ṣe ran wọn lọwọ.
Arabinrin "A" ni wọn mọ wa ninu ile ọhun. Ile naa ni a ti lọ ile iwe alakọbẹrẹ, girama, fasiti, ibẹ naa ni mo n gba lọ ibi iṣẹ nigba ti mo bẹrẹ iṣẹ. Ohun gbogbo nipa igbe aye wa, inu ile yii lo ti waye".
(O bu sẹkun) "mi o le maa sọ ita n gbogbo ohun to ṣẹlẹ, a maa da bi ofofo iroyin fun un yin nipa idile mii. A maa dabi iṣẹ ẹyin oniroyin".
Arabinrin "A" ni "ohun ti mo fẹ ni ki gbogbo titan kalẹ yii dawọ duro, mo fẹ ko duro! Ki awn eeyan jọ ọ. Iwe iroyin tibi ti sọ ọ, t'ọhun ti sọ ọ, awọn ọlọdani oniroyin naa tun wa n gbe e kaakiri. O ti to gẹ!"
"Eeyan ti wọn bọwọ fun lawujọ ni baba mi to jẹ agbẹjọro ati iya mi to jẹ nọọsi. Nitori naa mo fẹ ki eyi daw duro ki awọn eeyan si tẹsiwaju ninu nkan mii. Mi o fẹ maa ri aworan awn obi mi kaakiri".
Nigba ti akọroyin BBC bere nipa arakunrin rẹ to ṣe iṣẹ ibi yii, Arabinrin "A" dahun pe oun ko fẹ sọ nkankan nipa rẹ tabi ibi ti o wa lọwọlọwọ tori oun ko fẹ ki wọn ṣi oun gbọ ati pe a ṣi n ṣ'ọ̀fọ̀.
Arabinrin "A" pada sọ fun akọroyin BBC pe awọn ọrẹ oun gan mọ pe mo maa n sọrọ fun wọn pe mo ni aburo kan to ni iru iwa ipa kan lọwọ ṣugbn a o mọ pe o le ṣe nkan to to eyi. O ti lọ si ile iwosan, a ti gbe e l si ile ti wọn ti n tun iwa ṣe fun oṣu mẹfa ni Abeokuta, wọn si ti da a silẹ pe ara rẹ ti ya; o ti lọ oriṣi fasiti mẹta ọtọtọ...
Mi o sọ eleyi lati ṣe ẹlẹya ọmọkunrin naa o tori pe... (o bu sẹkun) awọn obi wa gbiyanju, wn kọ wa wọn si fi ifẹ han si gbogbo awa ọmọ wọn tori naa ko tọ si wọn ki awn eeyan maa wa ọrọ si wọn lara. O ti to gẹ!
Arabinrin "A" ni ohun to ṣẹlẹ ti ṣẹlẹ mo ṣi n gbiyanju lati bori rẹ kii ṣe ki n gbe foonu mi ki n tun maa wa ka oniruuru ọrọ ti awọn eeyan n sọ lodi si wa bi awọn kan ti wn a ni "ko ba san keeyan ma ni ọmọ kankan". O ti to gẹ!
O tẹnu mọ ọ pe ọna ati mu iru iwa yii kuro nilẹ lo yẹ ki awn eeyan maa wa kii ṣe ohun ti wọn n san. O ni ijọban gba awọn ọdọ laye lati maa korajọ kaakiri ti wọn si n mu igbo, wọn maa n korajọ ni agbegbe NNPC Junction ni Ejigbo, o yẹ ki ijba lọ ko wọn, dipo rẹ awọn ọmọ Yahoo nikan ni wọn n wa kiri bẹẹ si ni awọn ọdọ n ku kaakiri ti ẹmi wọn si n ṣ'ofo.












