Àrá sán pa aboyún ìnàkí àtàwọn mẹ́ta míì tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Inaki mẹrin to fi mọ àwọn abo inaki kan to n gbe lori apata ti ku ni Uganda lẹyin ti mọnamọna ara san pa wọn.
Wọn ri abo agba inaki mẹta ọhun ati akọ ọmọkunrin ni ọgba ti wọn nko ẹranko si, Mgahinga National Park ni Uganda pẹlu ọpọlọpọ ifarapa lara wọn eyi to si tumọ si pe ina gbe wọn.
Apapọ awọn onimọ nipa ranko, Virunga Transboundary Collaboration (GVTC) ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi adanu nla fun ẹya inaki.
- BBC tún gbé e dé! Wọ́n tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun àti SARS káàkiri Nàìjíríà
- Bàbá fìdí ọmọ ọdún márùn ún jó sítóòfù gbígbònà, ó di aláàbọ̀ara nítorí ó jí ẹja
- Buhari ń fowó aráàlú gbàtọ́jú nílùú òyìnbó nígbà táwọn ilé ìwòsàn wa ti di mọ́ṣúárì - Falana
- Ìgbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ ní ọ̀rọ̀ àwọn àgbààgbà ẹkùn àríwá pé ìjọba Buhari ti kùnà- Femi Adesina
Ẹgbẹrun kan pere iru inaki ori apata (Mountain Gorilla) yii nikan lo wa laye.
Awọn ibi ti wọn jẹ ki awọn inaki yii wa ni awọn agbegbe ti abo wa fun ni Democratic Republic of Congo, Rwanda ati Uganda.
Awọn mẹrin to ku yii wa lara ẹgbẹ ẹlẹni mẹtadinlogun ti wọn n pe wọn ni idile "Hirwa".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Idile awọn inaki Hirwa yii ti wa rekọja ibode lati Rwanda si Uganda lọdun to kọja ti wọn si ti n gbe ọgba ẹranko igbo Mgahinga ni Uganda.
Mgahinga jẹ ọkan lara awọn oke Virunga nla eyi to n pa ala pọ pẹlu awọn ibode Uganda, Rwanda ati DR Congo.
Andrew Seguya to jẹ akọwe agba GVTC sọ fun BBC pe iṣẹlẹ iku awọn inaki yii ba ni lọkan jẹ pupọ.
O ni "ipa ti awọn abo inaki mẹta yẹn yoo ko ninu ibisii ko kere rara".
Ẹwẹ, o fi kun un pe awọn mọlẹbi inaki naa mẹtala to ye iṣẹlẹ ara naa ni wọn ti ri ti wọn si n jẹun daadaa.


Ayẹwo ti n lọ lọwọ lori oku wọn ni ibudo ayẹwo ti wọn si n reti ohun to ṣokunfa iku wọn laarin ọsẹ mẹta si isinsiyii.












