Cameroon: Àṣírí èèyàn kan tó dìbò ní ìgbà 89 tú, Ọlọ́pàá gbé e jàǹtò!

Oludibo Cameroon

Bi iroyin ṣe jade tan pe idibo ti pari lawọn ibido idibo kaakiri orilẹede Cameroon lati yan awọn aṣofin atawọn kansilọ ni iroyin mii jade pe ọwọ Ọlọpaa tẹ oludibo kan.

Bi wọn ṣe pari kika ibo lawọn ibudo idibo ti wọn si ti ilẹkun gbọngan ibudo pa to jẹ wi pe awọn oluwoye nikan lo wọle, ṣe lawọn alatilẹyin ẹgbẹ duro sita ti wọn n wo lojuu ferese.

Ka to ni ka maa sinmi lori eto idibo ti ko ni kọnu nkọhọ ninu la gbọ pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ọkunrin kan to dibo nigba mọkandinlaadọrun ni Kumba to wa ni ẹkun Guusu Iwọ Oorun Cameroon.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ ọ, nigba ti wọn de ibudo idibo, eeyan mọkandinlaadọrun ni wọn ba to ti dibo ṣugbọn wọn ko tilẹ ri arakunrin kan nibẹ bẹẹ si ni ko buwọ̀ rẹ luwe idibo.

Àkọlé fídíò, BBC Africa Eye: Akọroyin fẹ ìdí àwọn oníṣẹ́ ibi ọmọ ogun síta

Oṣiṣẹ ajọ eleto idibo Cameroon kan lo fi aridaju iroyin yii han fun BBC.

Olugbe agbegbe Kumba ọhun kan sọ fun akọroyin BBc pe alaga ibudo idibo naa ti dibo C naa ti wa lọwọ awọn agbofinro.

Iroyin wa sọ pe alaga ẹgbẹ alatako, Social democratic pary ni Kumba 3 Um Rufus gba afurasi naa mu pẹlu apoti idibo to kun fun iwe itẹka lati igba ti eto idibo ko tilẹ tii gberasọ.

Awọn olugbe adugbo naa sọ fun BBC pe awọn n gbọ iro ibọn latọdọ awọn ologun to wa ni agbegbe naa ti wọn si ni ki gbogbo eeyan doju bo ilẹ.

Ni Kumba nibudo idibo kan, ẹgbẹrun lọna mẹtadinlogun eeyan lo fẹ dibo ṣugbọn bi wọn ṣe bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn, wọn o tilẹ ri to eeyan igba rara lati dibo.

Latari eyi, Ọna Kumba ọhun lewu lti gba ti wọn si n ṣe ikọlu si awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo Cameroon.