Muhammadu Buhari: Falana ní ilé ìwòsàn ti di mọ́ṣúárì ní Nàìjíríà nígbà tí Buhari ń gbàtọ́jú nílẹ̀ òkèrè

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Falana
Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹtọ yin lati beere fun eto ilera to peye lọwọ ijọba aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari.
Agbẹjọro ati ajafẹtọ, Femi Falana lo sọrọ yii idanilẹkọ ọdọọdun fun iranti Dokita Beko Ransome-Kuti ẹlẹẹkẹrinla rẹ.
Agbẹjọro Falana sọ pe ijọba ologun Buhari lo ju Dokita Beko si ọgba ẹwọn Kirikiri fun oṣu mẹfa lọdun 1984 nitori o jijagbara lati beere fun eto ilera to peye lọwọ ijọba.
Falana sọ pe ohun to kudiẹ kaato ni pe aarẹ Buhari n rinrin ajo lọ si oke okun fun itọju ara rẹ, nigba ti awọn ọmọ Naijiria n lọ si awọn ile iwosan to ti di mọṣuari bayii.
O ni Buhari fun ra rẹ lo nigba to gori aleefa gẹgẹ bi ọgagun olori orilẹede Naijiria lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 1983 pe awọn ile iwosan ni Naijiria ti di ibi ti awọn eeyan ti n ri awọn dokita lasan an.
Falana ṣalaye pe Buhari kan naa to sọrọ lọdun 1984 pe awọn ile iwosan to wa ni Naijiria ko ju ibi tawọn eeyan kan ti n ri awọn dokita lasan lọ, oun naa si ni aarẹ Naijiria lonii ti awọn iwosan ti di mọṣuari.
Gbajugbaja agbẹjọro ni Buhari ko lọ si awọn ile iwosan yii, ilu oyinbo lo n lọ fun itọju ara rẹ, owo ilu lo si n na.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Falana
''Ẹjọ ti mo pe ijọba wa ni ileẹjọ kotẹmilọrun bayii ninu eyi ti mo ti sọ pe ki ijọba ṣe eto iwosan to peye fun gbogbo eeyan nitori ori ko ju ori,'' Falana lo sọ bẹẹ.
''Ti ẹyin ba n gba ilu oyinbo lọ fun itọju, ẹ gbọdọ ba wa ṣe awọn ile iwosan ti awa naa n lo nile ko dara, ka wa naa le lanfaani si eto ilera to peye,'' Falana lo woye bẹẹ.
Falana tun fi kun ọrọ rẹ pe Buhari naa ni o fa iya to n jẹ ọpọ ara ilu Eko bayii lẹyin ti ijọba f'ofin de ọkada ati kẹkẹ Maruwa nitori o wọgile aba lati ṣe eto igbokegbodo ọkọ ti igbalode oni igba nmiliọnu dọla($200m) eyi ti Gomina Lateef Jakande ṣe agbekalẹ rẹ lasiko to wa lori alefa.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Eko tẹ ọmọ ọdún 22 tó jẹ́ olórí 'bambam' f'ẹ́gbẹ́ òkùnkùn Berry Boys
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn "Occupy Lagos" ń fẹ́ kí ìjọba Eko dá Okada àti Maruwa padà
- Ìjọba Eko sọ pé ká má tọrọ bárà mọ́, wọ́n tún fòfin de kẹ̀ẹ̀kẹ́ tá a fi n ṣiṣẹ́ - Àwọn àkàndá ẹ̀dá
- Ìsọkúsọ ni Olúbàdàn ń sọ, àwa la lè yọ́ lóyè. òun kò le è yọ́ wá - Lekan Balogun












