Ọwọ́ ọlọ́pàá Eko tẹ ọmọ ọdún 22 tó jẹ́ olórí 'bambam' f'ẹ́gbẹ́ òkùnkùn Berry Boys

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ ọmọkunrin, ẹni ọdun mejilelogun kan, ati awọn miran to jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Ọwọ awọn ọlọpaa lati ẹka agbegbe Itire tẹ Maliki Bello to jẹ olori ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Berry Boys.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ ninu atẹjade kan lati ọwọ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Bala Elkana , pe ọjọ ti pẹ ti wọn ti n wa Maliki fun awọn ẹsun jagidijagan ati ija awọn ẹgbẹ okunkun.
Ọwọ tẹ Maliki to jẹ ọmọ ipinlẹ Kwara, ni ọjọ kẹrin, oṣu Keji ọdun 2020.
O jẹwọ pe lootọ, oun ni oun wa nidi awọn ija igboro, ipaniyan, ati idigunjale kan to waye ni adugbo bi i Idi-araba, Dosunmu, Ashimowo, Omo Bola, Mushin, ati Itire.
O sọ fun awọn ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa pe ọmọ ọdun mejila ni oun wa nigba ti wọn mu u darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Lasiko yii, o wa ni kilaasi akọkọ nileewe girama kekere (JSS1). Ko to o di pe o de ipo olori 'bambam' ninu ẹgbẹ naa.
- Àrá sán pa aboyún ìnàkí àtàwọn mẹ́ta míì tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ láyé
- Àwọn fíìmù Nollywood ń mú kí òògùn owó àti ìjínigbé gbilẹ̀ síi - Fashola
- 'Ẹ jọ̀ọ́, a ò fẹ́ gbọ́ òfófó ìròyìn mọ́ pé àbúrò mi gún bàbá àti ìyá mi pa, ó ti tó gẹ́!'
- 'Street Gospel' tí mò ń kọ, Ọlọ́run ń fi tún ayé àwọn 'Boys' ṣe gan - Testimony Jaga
Bakan naa ni Maliki tun jẹwọ pe oju opo ayelujara Facebook ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Bbl Baloteli'ati awọn oju opo ayelujara miran ni awọn ti maa n gba ọmọ ẹgbẹ wọle.
Oju opo ayelujara yii kan naa ni wọn ti maa n ṣe eto bi wọn yoo ṣe ṣe ikọlu.
Lẹyin ti ọwọ tẹ Maliki ni iwadii tun mu ki ọwọ tẹ awọn afurasi mọkanla miran.












