Occupy Lagos: A fẹ́ kí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko dá Okada àti Maruwa padà - Olùfẹ̀hónúhàn

Occupy Lagos

Oríṣun àwòrán, @ifbnw

Awọn olugbe ipinlẹ Eko kan ti ya bo ojuko ti ere eje-gigun ipinlẹ Eko pari si ni Eko Atlantic lati ṣe iwọde lodi si bi ijọba ipinlẹ ọhun ṣe gbẹsẹ le Okada ati kẹkẹ Maruwa.

Nibi iwọde naa ti wọn pe ni "Occupy Lagos" ni wọn ti sọ fun ijọba ipinlẹ ọhun pe ko tu ero rẹ pa lori bo ṣe fofin de ọkada ati Maruwa naa.

Ọkan gboogi lara awọn to ṣiwaju iwọde naa, Kunle Wiseman Ajayi sọ fun BBC pe iwọde miran ṣi n bọ lọjọ iwaju ti ijọba ba kọ lati yi ipinu rẹ pada lori igbeṣẹ ọhun.

O ni ko yẹ ki ijọba dede gba iṣẹ lọwọ awọn to n fi ọkada ati keke Maruwa jẹun lai ba wọn ṣe ipade ko to fofin de iṣe wọn.

Ajafẹtọ ẹni naa sọ pe "Ti ijọba ba fẹ gba iṣẹ lọwọ awọn eeyan, o yẹ ko pe wọn si ijoko lati lee jiroro papọ pẹlu wọn ni."

Ajayi sọ pe ijọba ipinlẹ Eko ko pese iṣẹ fun awọn eeyan ṣugbọn o n gba iṣẹ lọwọ awọn to pese iṣẹ funra wọn.

Occupy Lagos

Oríṣun àwòrán, @ifbnw

O tẹsiwaju pe ọpọlọpọ awọn ti wọn n wu iwa jagidijagan tẹlẹ ṣugbọn ti wọn n ṣe ọkada ti pada sinu iwa ibajẹ wọn.

O ni oun to yẹ ki ijọba ṣe bayii ni pe ko kọkọ yi ipinlẹ rẹ pada, lẹyin naa ni ko pe ipade pẹlu ẹgbẹ awọn ọlọkada ati kẹkẹ Maruwa lori ohun to kan.

Kunle pari ọrọ rẹ pe ileri ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ṣe fun awọn ọlọkada nigba idibo kọ ni pe yoo gba iṣẹ lọwọ wọn.