Bola Tinubu 2023: Babachir Lawal sọ pé APC gbọdọ̀ fààye gba Tinubu láti díje fún ipò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọwe ijọba Naijiria nigba kan, Babachir Lawal, ti sọ pe dandan ni fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lati fi aye gba ẹnikẹni to ba fẹ dije fun ipo aarẹ l'ọdun 2023.
Oṣu Kẹwaa, ọdun 2017, ni wọn yọ Lawal kuro nipo lẹyin ti wọn fi ẹsun kan pe o na N544m ni inakuna lati fi ge koriko.
Lasiko to n ba iwe iroyin abẹle The Punch sọrọ, Lawal sọ pe lootọ ni aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa, Bola Tinubu, ko ipa pataki ninu bi aarẹ Muhammadu Buhari ṣe wọle ibo si ipo aarẹ l'ọdun 2015.
O ni kii ṣe nkan to pamọ pe igun Tinubu wa ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
O fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti Tinubu kede atilẹyin rẹ fun Buhari lọdun naa, lo to o fojuhan pe oun ni yoo gba tikẹẹti ẹgbẹ lati dije.
"Ti kii ba ṣe pe Tinubu jọwọ ara rẹ nigba naa, mo lero pe Kwakwanso ni ko ba gba tikẹẹti ẹgbẹ APC. Nitori idi eyi nikan, o fihan pe Tinubu ni onilu to lu fun iromi Buhari , ati idagbasoke ẹgbẹ APC.

Oríṣun àwòrán, The Guardian
Bakan naa ni Lawal sọ pe Tinubu lo ko owo jọ fun ipolongo, nigba ti Buhari ko ni owo lọwọ lati gbọ bukata eto idibo. Oun kan naa lo gba ileeṣẹ ilẹ okeere kan lati ilẹ America, fun atunṣe si oju ti awọn eeyan fi n wo Buhari ṣaaju eto idibo.
"Oju ti ọpọ eeyan fi n wo Buhari nigba naa ko dara rara, eyi to ṣeeṣe ko ṣe idiwọ fun jijawe olubori rẹ"
"Nitori naa, ti a ko ba fẹ pe ibinu Ọlọrun si ori wa, eyi ti a ko fẹ, a gbọdọ fi aaye gba ẹnikẹni to ba fẹ dije, to fi mọ Tinubu."
Ọrọ ti Lawal sọ yii ti n fa ariyanjiyan laarin awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan lori ayelujara.
Igba akọkọ kọ niyi ti iroyin ati awuyewuye ti n waye lori pe boya Tinubu fẹ ẹ dije du ipo aarẹ Naijiria ni ọdun 2023. Oun naa si ti sọ laimọye igba pe, oun ko dije.
Ẹ ṣọ́ra fún ayédèrú ìròyìn, mi ò pe Buhari ní alákatakítí ẹ̀sìn láéláé- Tinubu ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Twitter/Muhammadu Buhari
Ẹ ṣọra fun iroyin ofege, emi o pe aarẹ Muhammadu Buhari ni alakatakiti ẹsin, eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu lo sọ bẹẹ.
Atẹjade kan lo lu ayelujara pa ninu eyi to fẹsun kan Tinubu pe o ṣapejuwe Buhari bi alakati ẹsun, ẹlẹyemẹta ati daaru daapọ lọdun 2013.
Atẹjade naa tun sọ pe Tinubu ni ti wọn ba gba Buhari laaye pẹrẹ, afaimọ ko maa pin orilẹede Naijiria, ati pe iwa ẹlẹmyamẹya Buhari le ṣakoba fun iṣọkan fun Naijiria.
- BBC tún gbé e dé! Wọ́n tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun àti SARS káàkiri Nàìjíríà
- Bàbá fìdí ọmọ ọdún márùn ún jó sítóòfù gbígbònà, ó di aláàbọ̀ara nítorí ó jí ẹja
- Ìgbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ ní ọ̀rọ̀ àwọn àgbààgbà ẹkùn àríwá pé ìjọba Buhari ti kùnà- Femi Adesina
- Buhari ń fowó aráàlú gbàtọ́jú nílùú òyìnbó nígbà táwọn ilé ìwòsàn wa ti di mọ́ṣúárì - Falana
- Àṣírí èèyàn kan tó dìbò ní ìgbà 89 tú, Ọlọ́pàá gbé e jàǹtò!
Bi ẹ ko ba gbagbe Buhari dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ANPP ninu idibo gbogbogbo ọdun 2003 ṣugbọn o fidi rẹmi, nigba ti Olusegun Obasanjo ẹgbẹ oṣelu PDP wọle ibo naa.
Tinubu naa dupo gomina ipinlẹ Eko fun saa keji lọdun naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AD ninu eyi to ti jawe olubori.
Amọ, oludamọran fun Tinubu lori eto iroyin, Tunde Rahman sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti pe ayederu iroyin lawọn kan n gbe kiri.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Muhammadu Buhari
O ni awọn eeyan kan ti wọn koriira Tinubu lo wa nibi iroyin ofege naa, bakan naa lo beere pe ki ẹnikẹni to ba mọ ibi ti Tinubu ti sọrọ naa wi pe ko wa sọ.
''Asiwaju ko le sọ iru ọrọ bayii nipa Buhari laelae! Ati pe ko si ohun to le mu ki Tinubu sọ iru ọrọ yii nitori oun ati Buhari ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa, bẹẹ ni wọn o si nija ara wọn ninu,'' Ọgbẹni Rahman lo woye bẹẹ.
O ṣalaye siwaju sii pe ko ba tiẹ wu Tinubu gan an ki Buhari wọle ibo aarẹ ọdun 2003 nitori oun ti Obasanjo ṣe fun ipinlẹ Eko nigba to gbẹsẹ le owo to n wolẹ lati apo ijọba apapọ.
- Tinubu kò ṣékú, kò ṣé ẹyẹ, o n dibọn ní lórí ọ̀rọ̀ ikọ̀ Amotekun - Fani Kayode
- Ohun tó ti yá kan kìí pẹ́ mọ́, fọ́ọ̀mù ìgbaniṣíṣẹ́ fún Àmọ̀tẹ́kùn dé!
- Ìsọkúsọ ni Olúbàdàn ń sọ, àwa la lè yọ́ lóyè. òun kò le è yọ́ wá - Lekan Balogun
- Iléẹjọ́ gíga Akure kọ̀ láti gba onídùróó olórí ìjọ Sotitobire
- Ìjọba Eko sọ pé ká má tọrọ bárà mọ́, wọ́n tún fòfin de kẹ̀ẹ̀kẹ́ tá a fi n ṣiṣẹ́ - Àwọn àkàndá ẹ̀dá
- Mí ò bẹ̀bẹ̀ fún oyè igbákejì alága APC kí wọ́n tó ó fún mi - Abiola Ajimobi
- Saheed àti Fathia Balogun dìjọ ń ṣe ọjọ́ ìbí lónìí, ẹ wo àjọṣepọ̀ tó wà láàrin wọn














